Ìjọba Eko bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ọkọ DJ Kulet tí ìyàwó rẹ̀ fi ẹ̀sùn kàn pé ó ń bá ọmọdé lòpọ̀

DJ Kulet

Oríṣun àwòrán, DJ Kulet/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹka ijọba ipinlẹ Eko to n risi ẹsun ifipabaọmọde lopọ ti kede sita pe awọn ti gbọ nipa iroyin kan to lu si ori ayelujara nipa ifipa ba ọmọ lopọ.

Saaju ni ọdọmọbinrin kan to jẹ amuludun kede pe oun ti fopin si igbeyawo rẹ, to si fẹsun kan ọkọ rẹ pe o fipa ba ọmọ ọdun mẹtala kan lopọ ni ile ti wọn jọ n gbe papọ.

Kudirat Gbemisola ẹni ti ọpọ mọ si Dj Kulet ni oun ko si ninu igbeyawo pẹlu Ohis Emmanuel, ẹni ti wọn jọ se igbeyawo alarinrin nibi oṣu mẹjọ sẹyin.

Ninu ọrọ to gbe sori ayelujara o ni; "Lẹyin ti mo ri ọpọ ẹri bi fọnran, aworan to si tun kuna lati yi iwa rẹ pada.

"Eyi to se gbẹyin yii jẹ ohun iyalẹnu pe o n ba ọmọ ọdun mẹtala lopọ labẹ orule wa fun oṣu mẹfa..

"Mo ti kọkọ darijin ṣugbọn lẹyin ọpọ iwadi mo ri pe o tun ba eeyan mọlẹbi rẹ, to jẹ ẹni ogun ọdun ati ọrẹ rẹ lopo, to si fun wọn ni aarun ibalopọ.

"Mo ri pe o fẹran lati ma ba ọmọde lopọ. Oṣu mẹjọ ni mo fi jẹ iyawo rẹ, ti mo si ti se itọju aarun ibalopọ ni igba mẹta ọtọọtọ."

Kudirat ni oun n pe akiyesi awọn obinrin bi tiẹ lati yago fun iru eeyan bi ti ọkọ rẹ tẹlẹ.

Nigba ti ijọba ipinlẹ Eko sọrọ lori ayelujara, wọn ni awọn ti kan si Kudirat lati wa wi tẹnu rẹ lori iṣẹlẹ naa.

Eyi waye" lẹyin ti a ri fidio kan to n lọ kaakiri ori ayelujara, nibi ti ọkùnrin naa ti jẹwọ pe, o n ba ọmọde lopọ."

"A ti kan si DJ Kulet, a n rọ ẹnikẹni to ba mọ bi a tun se le ri DJ Kulet, ko fi to wa leti.

"A ni lati daabo bo awọn ọmọ laibikita iru eeyan ti wọn o ba jẹ tabi ibi ti wọn ti wa."

Aworan

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Taa ni DJ Kulet?

Kudirat Gbemisola lo pa orukọ da di DJ Kulet to n fi iṣẹ DJ dara, ara gidi lawujọ.

Lootọ ko jẹ tuntun mọ ki obinrin maa ṣe iṣẹ DJ amọ ti Kudi yatọ.

Kulet gẹgẹ bi inagijẹ rẹ, kan dede yan lati maa ṣa awọn orin Fuji atawọn to fara pẹ ẹ nikan safẹfẹ.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC Yoruba lọdun 2020, Arabinrin Kudirat sọ pe ọdun 2018 ni oun bẹrẹ iṣẹ amuludun, DJ.

Ṣaaju akoko yii, ijo lo ni oun maa n jo kiri inawo oni inawo koda bi wọn o pe e, yoo lọ tori ijo lati da inu ara rẹ dun.

"Baba mi o fọwọ sii, iya mi o fọwọ sii, awọn ọrẹ mi naa o fọwọ sii, gbogbo wọn ṣaa da mi nu".

O ni ọpọlọpọ igba lawọn onibara naa maa n kọkọ wo oun pe ṣe o lee ṣe iṣẹ ti wọn fẹ gbe fun un yii ti wọn a si gbe e fun ọkunrin tori wọn gbagbọ pe iṣẹ ọkunrin ni.

Amọ aye ọpẹ pada yọ ninu nnkan ti Kudirat DJ Kulet yan laayo.