Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Njẹ o mọ pe awọn orilẹede kan ti wọ ọdun 2025 lonii ti 2024 pari
Ṣe lori eepẹ ta a wa yii naa?
Bẹẹ ni,aago mọkanla aarọ oni ni orileede Kiribati ti wọ 2025 tiwọn
Lo ba tan
Ko i tan o, awọn orilẹede mi-in tun ti wọ 2025 bayii yatọ si Kribati
Kan si oju opo BBC .COM / Yoruba, lati ka nipa akojọpọ awọn orilẹ-ede naa
......................................................................................................................
Wọn n binu o, wọn lawọn yoo daṣẹ duro lọdun tuntun
Awọn wo niyẹn?
Awọn ileeṣẹ ẹlẹrọ ibaraẹnisọrọ ni Naijiria ni
Wọn lawọn yoo daṣẹ duro lawọn agbegbe kan ti ajọ to n ri si ibaraenisọrọ ko ba ṣe atunṣe lori owo tawọn eeyan n san lori ipe.
Ki ni yoo waa ṣẹlẹ bayii
Ọrọ di hun!
.....................................................................................................
Ṣe o ti gbọ pe ibudo ifọpo rọbi to wa ni Warri ti bẹrẹ iṣẹ?
Haa, iyẹn daa o
Ọjọ Aje ana ni NNPC ṣiṣọ loju ibudo naa, pẹlu alaye pe iṣẹ ti bẹrẹ ni ida ọgọta (60%)
Koda, wọn ni ti Kaduna paapaa yoo dide laipẹ
Ṣe owo epo yoo walẹ saa?
Inu iroyin lẹkunrẹrẹ wa
