"Oṣù Kíní, ọdún 2025 ló yẹ kí ọmọ mi rìnrìnàjò lọ sí òkè òkun, àmọ́ FMC Owo paá"

Àkọlé fídíò,
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Agbabọọlu ni Oluwadunsin Ayomide Fasuyi, bakan naa si lo tun ma n ta jita fun awọn olorin nigba aye rẹ.

Amọ, gbogbo ala ati iran rere to ni wa sopin lẹyin to ni ijamba ọkọ kan lọdun 2024.

Ijamba ọkọ naa lo gbe oloogbe Fasuyi de ileewosan ijọba to wa ni ilu Owo, FMC, nipinlẹ Ondo, nibi to ti dagbere faye.

Ẹsun ti mọlẹbi oloogbe fi kan ileewosan naa lori iku ọmọ wọn ni pe, aibikita ati ailamojuto lati ọwọ awọn olutọju alaisan lo pa a.

Baba oloogbe, Ọgbẹni Akindele Fasuyi sọ pe, ọmọ naa to jẹ abigbẹyin oun, ni afojusun lati lọ si ilẹ okeere lati maa ṣiṣẹ gẹgẹ bi agbabọọlu.

O ni, inu oṣu Kinni, ọdun 2025, lo yẹ ko gbera lọ si ilẹ okeere, nitori oloore kan ti gba lati gbọ gbogbo bukaata rẹ.

Bo sẹ sọ, o ni awọn deedee gba ipe pe o ni ijamba, eyi to mu wọn gbe e lọ si ileewosan nla naa.

"Amọ ko si iyatọ si bi a ṣe gbe e debẹ."

Dunsin Fasuyi

Oríṣun àwòrán, Dunsin Fasuyi

Lara awọn ẹsun ti ẹbi oloogbe Ayomide fi kan ileewosan naa ni pe, wn ni ko si epo Didu ninu ẹrọ amunawa wọn lati ṣe ayẹwo inu ara, ti a mọ si X-ray.

"Kia ni awọn ọrẹ rẹ fa ara wọn kalẹ lati ra disu, ko to o di pe wọn gbe lọ ṣe x-ray.

"Aago mẹrin aabọ ni wọn to ṣe ayẹwo ọhun to yẹ ki wọn o ti ṣe lati aago mẹsan an."

Baba oloogbe tun fi ẹsun kan pe, awọn olutọju alaisan naa ko fun ni aporo, tabi itọju pajawiri kankan fun ẹsẹ to fi pa nigba ti mọto kọ luu.

Yatọ si eyi, ẹgbọn rẹ, Ayo Fasuyi, kun ọrọ baba wọn lẹyin pe, awọn alaṣẹ ileewosan FMC Owo, tun sọ pe ẹrọ aṣayẹwo CT Scan awọn naa tun ti bajẹ.

"Wọn sọ eyi lẹyin ti a ti san owo ayẹwo."

O ni ẹnikan lara awọn ti awọn mọ ni orilẹ-ede Canada, lo ba awọn pe ẹni to jẹ kọmisanna fun eto ilera nipinlẹ Ondo.

"Ko ju bii ogun iṣẹju ti kọmisanna de si ileewosan naa, ni wọn tan ẹrọ amunawa ti wọn ni ko dara.

Iya oloogbe, Arabinrin Fasuyi, sọ pe awọn oṣiṣẹ FMC pa ọmọ oun ti sinu inira, lai tọju rẹ.

"Awọn nọọsi tun le wa jade kuro nibi ti a ti n ṣe aajo rẹ ko ma ba a jabọ lori ibusun nitori inira."

Ẹgbọn oloogbe sọ pe nibi ti oun ti n sunkun, daro aburo oun lẹyin to pada gbẹmi mi, ni oun ati dokita kan ti tahun sira wọn, "nitori awọn ọrọ kan ti dokita naa ati nọọsi kan sọ".

Yoruba kan si awọn alaṣẹ ileewosan FMC, amọ wọn kọ lati fesi si awọn ibeere akọroyin wa.

Wọn ni awọn n ṣiṣẹ iwadii lọwọ lori iṣẹlẹ ọhun.