Ọlọ́pàá ló jẹ̀bi ìṣẹ̀lẹ̀ ìtẹra-ẹnipa tó wáyé, ìjọba gbọdọ̀ fún ẹ̀bí àwọn èèyàn tó kú lówó - Falana

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat/Facebook
Ilumọọka agbẹjọro ati ajafẹtọọ, Femi Falana, ti sọ pe awọn ọlọpaa lo lẹbi lori iṣẹlẹ itẹra-ẹnipa to waye nibi ti wọn ti n pin ounjẹ ọfẹ niluu Ibadan, Okija nipinlẹ Anambra ati niluu Abuja.
Eeyan marundinlọgọfa lapapọ lo padanu ẹmi wọn nibi iṣẹlẹ yii niluu mẹtẹẹta.
Agbẹjọro agba Falana fidi ọrọ yii mulẹ nigba to n sọrọ apilẹkọ rẹ nibi eto iranti ọdun kan ti Gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹ Rotimi Akeredolu doloogbe niluu Akure.
Falana ni aiṣedeede awọn ọlọpaa lo ṣokunfa iṣẹlẹ to mu ẹmi awọn eeyan lọ yii.
Falana ni ''iku eeyan marundinlọgọfa ni Ibadan, Okija ati Abuja jẹ iṣẹlẹ to buru jai.
Ọlọpaa ko ṣiṣẹ wọn lati daabo bawọn eeyan, awọn lo lẹbi iṣẹlẹ yii.''
Ijọba gbọdọ fawọn ẹbi eeyan to ku lowo gba mabinu tori ijọba lo kuna
Ilumọọka agbẹjọro naa ni ijọba gbọdọ sanwo gba mabinu fun ẹbi awọn eeyan to padanu ẹmi wọn nibi iṣẹlẹ itẹra-ẹnipa to waye n'Ibadan, Okija ati l'Abuja.
Falana wa kepe ijọba Naijiria lati wa ojutuu si oṣi ati iṣẹ to n ba ọpọ ọmọ Naijiria finra.
O ni iṣẹlẹ itẹra-ẹnipa yii ti fihan pe oṣi, airiṣẹṣe, ebi ati aimọọkọ-mọọka pọ niluu.
Falana ni ti ijọba ko ba daabo bo araalu nipa ipese iṣẹ ati ounjẹ, eto aabo ko le kẹsẹjari ni Naijiria.
Gbajugbaja agbẹjọro naa ni ọpọ eeyan lo ti n dẹbi iṣẹlẹ naa ru awọn to ṣagbekalẹ eto ounjẹ pinpin lọfẹẹ yii.
Amọ, o ni awọn eeyan yii fẹ ṣe iranwọ fawọn ti ko rọwọ họri ni.
Falana no awọn ọlọpaa ni ko ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ ti ọpọ eeyan fi ku nibi iṣẹlẹ itẹra-ẹnipa to waye.















