Ilé ẹjọ́ sọ ọmọ lórúkọ lẹ́yìn ọdún mẹ́ta tí àwọn òbí rẹ̀ kò fẹnukò lórí orúkọ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Mọlẹbi kan lagbegbe Karnataka, lorilẹede India ti ko ara wọn lọ sile ẹjọ fun odidi ọdun mẹta gbako latari ariyanjiyan lori orukọ to yẹ ki wọn sọ ọmọ wọn.
Ọrọ naa le to bẹẹ ti tọkọtaya ọhun fi n mura lati ja iwe mi oṣe mọ fun ara wọn bayii.
Ọdun 2021 ni ọrọ naa kọkọ bẹrẹ lẹyin ti iyawo pada si ile awọn obi rẹ lẹyin to bi ọmọ tan.
Ni India, obinrin gbọdọ lọ sile lati lọ wẹ lẹyin to ba bi ọmọ tan.
Gẹgẹg bii aṣa wọn, ọkọ rẹ gbọdọ lọ mu iyawo rẹ ọhun lẹyin to ba wẹ tan ki wọn si pada sile wọn.
Amọ lẹyin ti iyawo sọ pe oun ko faramọ orukọ ti ọkọ oun fun ọmọ wọn, ọkunrin naa kọ lati lọ mu obinrin naa pada sinu ile ti awọn mejeji n gbe.
Ọkan lara awọn agbẹjọro to da si ọrọ naa ni "Adi" ni orukọ ti obinrin naa fun ọmọ ti wọn bi, to jẹ lara orukọ rẹ ati orukọ ọkọ rẹ.
Amọ ṣa, lẹyin ọpọ ọdun ti ọkọ rẹ kọ lati lọ mu nile awọn obi rẹ, obirin ọhun gba ile ẹjọ lọ ki ile ẹjọ le kan an nipa fun ọkọ rẹ lati maa fi owo itọju ọmọ wọn ranṣẹ si.
Agbẹjọro obinrin naa, MR Harish, sọ fun BBC pe o ti ke si ile ẹjọ pe ko tu igbeyawo wọn ka.
Bo tilẹ jẹ ile ẹjọ gbiyanju lati pa aawọ laarin mejeji, ni ṣe ni wọn fariga, lẹyinorẹyin, ile lo fun ọmọ ọhun lorukọ.
Orukọ ti ile ẹjọ fun ọmọ naa ni "Aryavardhana" to n tumọ si ohun iyebiye.
Wayi o, kii ṣe igba akọkọ ree ti ile ẹjọ yoo da si ọrọ tọkọtaya latari ariyanjioyan nipa orukọ to yẹ ki wọn sọ ọmọ wọn ni India.















