Adeleke tú Olowookere Segun, ẹlẹ́wọ̀n 52 míì sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

Adeleke

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/Remi Tunde

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti dariji Olookere Segun to gba idajọ iku lẹyin to digunjale nipinlẹ naa, to si ji adiye lọdun mẹrinla sẹyin.

Yatọ si ọdọkunrin ọhun, Adeleke tun foriji awọn ẹlẹwọn mii ti iye wọn to mejilelaadọta.

Agbẹnusọ gomina ọhun, Olawale Rasheed lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan.

Adeleke ni oun gbe igbesẹ naa gẹgẹ bii agbara ti ofin orilẹede Naijiria ti wọn kọ lọdun 1999 fun oun.

Awọn ẹlẹwọn ti Adeleke dariji lori ẹsun kekeke

1. Olabomiji Nurudeen

2. Mustapha Isah

3. Olalekan Abdullahi

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

4. Ayomide Olojede

5. Akeem Raphael

6. Adeyemi Abiodun

7. Oladipupo Segun

8. Omisakin Sunday

9. Ademola Adio

10. Tunde Olapade

11. Late Chief Wole Ola Rufus Ojo

12. Omoloye Olajide Olayemi

Awọn Ẹlẹwọn ti Adeleke ni ki wọn tu silẹ lẹsẹkẹsẹ

1. Olubo Sunday

2. Isah Umar Biodun

3. Fawas Kareem

4. Omirin Temitayo

5. Olarenwaju Ayomide

6. Dare Sunday

7. Oladapo Tunde

8. Ganiyu Saheed

9. Adewumi Sodiq

10. Adebayo Adeoye

Kehinde

11. Lasis Kazeem

12. Dauda Ojo

13. Ismaila Raji

14. Oseni Micheal

15. Ajayi Korede

16. Abiona Nurudeen

17. Oshi Samuel

18. Sheu Yusuf Olatunji

19. Ojo Aanu

20. Mustapha Kehinde

21. Lasis Abeeb

22. Alexandra Iorlaha

23. Ojo Taiwo

24. Azeez Mujeeb

25. Akinyemi David

26. Adeosun Adekunle

27. Olaobaju Samuel

28. Adura Adefemi

29. Paul Basil

30. Kunle David

Awọn ẹlẹwọn ti yoo gba itusilẹ nitori wọn ti yipada

1. Sunday Morakinyo

2. Segun Olowookere

3. Tunde Olapade

4. Demola Odeyemi

Awọn ẹlẹwọn ti wọn yoo gba itusilẹ nitori ilera wọn

1 Oluwafemi Fagbemi

2 Bewaji Sunday

3. Amehin George

4. Ayomide Arulogun

5. Taiwo Oluwatobi Stephen

6. Abubakar Abdulazeez

Ẹlẹwọn ti wọn yi idajọ iku rẹ si ọdun mẹẹdogun lẹyin to ti ṣẹwọn ọdun mẹwaa

Ijekunle Timothy

"Adájọ́ tó ní kí wọ́n yẹgi fún Olowookere Segun kò ṣìṣe, àlàkalẹ̀ òfin ló tẹ̀lé"

Segun Olowokere

Oríṣun àwòrán, Remi Tunde

Awọn alaṣẹ ẹka eto idajọ ipinlẹ Osun ti sọrọ lori idajọ iku ti ile ẹjọ kan nibẹ ṣe fun Segun Olowookere lẹyin to ji adiyẹ pẹlu ohun ija oloro lọwọ rẹ.

Ṣaaju ni iroyin idajọ naa ti kọkọ milẹ titi lẹyin ti mọlẹbi rẹ ke gbajare si gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, pe ko boju aanu wo ọdaran naa, ko si tu silẹ.

Lẹyin ti ọrọ naa jade ni Adeleke sọ pe ijoba oun yoo darijin ọmọ ọhun.

Amọ ọpọ Naiijiria lo bu ẹnu atẹ lu ile ẹjọ to ṣedajọ naa lati nnkan bii ọdun mẹrinla ṣeyin, ti pupọ wọn si n sọ pe ko tọ lati ṣedajọ iku fun ẹni to ji adiyẹ nigba ti awọn oloṣelu to n ji obitibiti miliọnu naira n yan fanda laarin ilu.

Eyii lo jẹ ki ileeṣẹ ẹka eto idajọ ipinlẹ naa sọrọ soke ninu atẹjade kan nibi ti wọn ti sọ pe awọn eeyan n yi idajọ naa pada lọna ati bu ẹnu atẹ ẹka eto idajọ ipinlẹ naa, ati pe wọn n ba orukọ adajọ to gbe ẹjọ naa kalẹ, Olajide Falola to ti fẹyinti jẹ.

Ki ni ohun ti wọn sọ?

Ninu atẹjade kan ti akọwe ileeṣẹ eto idajọ naa, F. I. Omisade, fi lede, o ni idajọ ọhun waye gẹgẹ bii alakalẹ ofin to rọ mọ idigunjale pẹlu ohun ija oloro.

Akọwe naa ṣalaye pe ẹni ọdun mọkandinlogun ni Segun lasiko ti idajọ rẹ waye, nigba ti ẹni ti wọn jọ daran jẹ ọmọọdun mejidinlogun, eyii to lodi si iroyin ti awọn eeyan n gbe kiri igboro.

O tẹsiwaju pe "Awọn eeyan ti yi bi idajọ naa ṣe waye pada fun araalu. Ohun ti wọn n sọ fun awọn eeyan ni pe ile ẹjọ ṣedajọ iku fun ọdọkunrin ọhun latari pe o ji adiyẹ kan.

"Awọn to n gbe iroyin irọ yii ti ṣafihan ibi ti wọn le ronu mọ, ẹni to ba kawe ko nilo agbẹjọro ko to mọ pe ko ṣeeṣe ki wọn dajọ iku fun eeyan latari pe o ji adiyẹ, ko da bo tilẹ jẹ biliọnu kan naira gan, lai ṣe pe irufẹ ẹni bẹẹ di ihamọra lasiko to jale naa.

"Ofin sọ pe ijiya ẹni to ba jẹbi ẹsun idigunjale ni idajọ iku niwọn igba ti ẹri ba le fi han pe adigunjale naa di ihamọra ogun lasiko to n jale naa.

Atẹjade naa sọ siwaju si pe o ti pẹ ti ọdaran naa tawọn ẹmẹwa rẹ ti maa n ja awọn eeyan lole pẹlu ibọn lọwọ wọn ki akara wọn to tu sepo lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun 2010.

Omisade pari atẹjade naa pe ko tọ ki awọn eeyan kan lawujọ maa mọọmọ tabuku ẹka eto idajọ ipinlẹ Osun atawọn adajọ latari idajọ ọhun, nitori adajọ to da ẹjọ naa ko ṣe aṣiṣe ninu idajọ rẹ.