Olorì Naomi ń kọ oúnjẹ sílẹ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Agodi tó wà ni báyìí, Ìyá rẹ̀ ṣàlàyé

Olori tẹlẹ, Naomi Silekunola

Oríṣun àwòrán, Queen Naomi Silekunola/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Bo ṣe n pe ọsẹ kan lọ ti olori tẹlẹ laafin Ọọni Ile Ifẹ, Naomi Silekunola ti wa lọgba ẹwọn Agodi niluu Ibadan, iroyin to n ti ibẹ wa ni pe iyawo Ọọni Ifẹ tẹlẹ naa kọ lati jẹun.

Iya Naomi, Funmilayo Ogunseyi, lo sọ eyi di mimọ ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu iwe iroyin Punch.

Iya olori tẹlẹ naa ṣalaye pe Naomi ti ru pupọ ninu ọgba ẹwọn ti wọn fi i si, bẹẹ ni inu rẹ ko dun, yatọ si pe o kọ ounjẹ silẹ lai jẹ.

''Nigba ti mo debẹ l'Ọjọbọ, ara rẹ ko ya daadaa. Irora ṣi wa fun un pẹlu iṣẹlẹ to ṣẹlẹ yii, o ti ru ninu ẹwọn.

''O kọ lati jẹun, mo rọ ọ titi pe ko jẹun, ko dahun. Ibanujẹ gba ọkan rẹ nitori awọn ọmọ ti wọn ku, ibi ti wọn si fi i pamọ si yẹn ko rọ ọ lọrun rara.''

Bayii ni Iya Naomi ṣalaye.

Ńjẹ́ àwọn èèyàn ń dìde sí ọ̀rọ̀ yìí kí Naomi lè gba òmìnira?

Nigba to n fesi lori igbesẹ to le mu Naomi Silekunola gba ominira kuro lẹwọn, iya rẹ sọ pe ẹbẹ naa loun ṣi n bẹ awọn alẹnulọrọ lati dide iranlọwọ.

'' A kan n bẹ gbogbo eeyan naa ni o, a n bẹ gbogbo ọmọ Naijiria lati ran wa lọwọ. Ki wọn ba wa bẹ Gomina Seyi Makinde lati da si ọrọ yii.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

''A n rọ awọn ọmọ Naijiria, ki wọn ba wa bẹ awọn obi to padanu ọmọ ninu iṣẹlẹ yii. Ẹ ma binu, ki i ṣe ohun ti a mọ-ọn-mọ ṣe, a ko lero lati pa ẹnikẹni.''

Nipa ipa ti Ọọni Adeyeye Ogunwusi n ko lori ọrọ yii, Iya Naomi sọ pe ana ṣi ni oun ati Ọọni Adeyeye.

Iya naa sọ pe oun mọ pe Kabiyesi naa yoo ti maa gbiyanju laaye ara rẹ nipa bi ọrọ naa yoo ṣe yanju.

O loun mọ pe Ọọni ko ni i fẹ idaamu fun obinrin to bimọ fun un.

Latigba ti olori Naomi ti wa lahaamọ pẹlu Oriyomi Hamzat ati Abdullahi Fasasi; oga ileewe Islamic High School ti ayẹyẹ to fa iku ọmọde marundinlogoji n'Ibadan ti waye, ni iyapa ẹnu ti n ṣẹlẹ laaarin awọn eeyan lori rẹ.

B'awọn kan ṣe n sọ pe awọn to ṣeto naa ni ko ṣe ohun to yẹ, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe ìfà lo fa awọn to padanu ẹmi wọn lapo ya, nitori eto ko ti i bẹrẹ ti wọn ti n lọọ tẹ ara wọn pa.

Nigba ti Iya Naomi si bọ sori afẹfẹ pẹlu omije loju, to n bẹbẹ fun ọmọ rẹ, aanu ṣe awọn mi-in, bẹẹ lawọn kan sọ pe ki ni yoo jẹ ipin awọn ti ọmọ wọn ku bi wọn ba yọnda Naomi to tẹ pẹpẹ ayẹyẹ.

Ṣaa, adajọ ti ni ki awọn eeyan mẹta to wa lahaamọ naa ṣi wa nibẹ, titi di ọjọ kẹrinla oṣu Kin-in-ni ọdun 2025.

Bẹẹ ni awọn eeyan kọọkan ti n dide ẹbẹ si awọn alaṣẹ, lara wọn ni iya oniwaasi ilu Ibadan, Kafila Kaola ati Femi Branch ti oun jẹ oṣere tiata.

Ìyá Olorì Naomi sunkún kíkorò: 'Ẹ má jẹ́ kí wọ́n pa Naomi, olúọmọ ló jẹ́ fún mi'

Iya Naomi, Pasitọ Olufunmilayo Ogunseyi ati ọmọ rẹ;Naomi Ogunseyi.

Oríṣun àwòrán, Queen Naomi@ Instagram

Àkọlé àwòrán, Iya Naomi, Pasitọ Olufunmilayo Ogunseyi ati ọmọ rẹ;Naomi Ogunseyi.

Pasitọ Olufunmilayo Ogunseyi, iyẹn mama to bi Olori tẹlẹ fun Ọọni ifẹ, Naomi Silekunola, ti fi omije bẹbẹ nipa ọmọ rẹ, o ni ki gbogbo abiamọ aye ma jẹ ki wọn pa Naomi mọ oun lọwọ.

Ninu fidio kan to wa loju opo Instagram Naomi ni mama rẹ ti n sunkun kikoro, to si n ṣalaye nipa apeje to ran ọmọde marundinlogoji lọ sọrun lọjọ kejidinlogun, oṣu kejila ọdun 2024 yii.

Tẹ o ba gbagbe, Olori Naomi lo ṣagbatẹru apeje to ti ni oun yoo ran ẹgbẹrun marun-un awọn ọmọde lọwọ, ti Oriyomi Hamzat si ba a kede rẹ lori redio.

Iṣẹlẹ naa lo gbe Naomi de teṣan ọlọpaa, kootu ati ọgba ẹwọn, nibi ti adajọ ni ki wọn fi i si titi di oṣu kin-in-ni ọdun 2025 ti igbẹjọ yoo tun waye.

'' Ẹ ṣaanu mi, ẹ ma jẹ ki wọn ba aye mi jẹ, ọmọ mi o mọ nnkan kan, aago mẹwaa la fi eto si, aago mẹrin aabọ idaji ni wọn ti n tẹra wọn pa nigba ti eto o ti i bẹrẹ.

''Ẹ jọọ, ẹ ma jẹ ki wọn pa Naomi, oluọmọ lo jẹ fun mi. Ọdun kẹwaa to ti n ṣeto yii ree, fun awọn ọmọde, arugbo ati awọn alaboyun. O tun wa s'Ibadan lati ṣe e ni.

'' Naomi o mọwọ-mẹsẹ, emi gan-an ṣi n sun lọwọ nigba ti wọn ti n tẹra wọn pa ni. Wọn ṣaa bẹrẹ si i mi pe lorii foonu, nọmba mi lo wa lara posta apeje yẹn.

Ẹ ṣaanu mi, gbogbo abiamọ aye o''

Bẹẹ ni Iya Olori Naomi fi omije bẹbẹ.

'Funra Naomi lo lọọ sọ ohun to ṣẹlẹ f'ọlọpaa ti wọn fi ti i mọle'

Naomi ati iya rẹ

Oríṣun àwòrán, Olufunke Akinsete/ Facebook

Àkọlé àwòrán, Naomi ati iya rẹ

Nigba to n tẹsiwaju ninu alaye rẹ,Pasitọ Ogunseyi sọ pe funra Naomi lo lọọ fi iṣẹlẹ naa to wọn leti ni teṣan ọlọpaa Iyaganku, n'Ibadan.

''A jọ lọ si teṣan naa ni, wọn dẹ da a duro latigba yẹn, wọn fi i si sẹẹli. Wọn bẹrẹ si i fọrọ wa a lẹnu wo titi to fi daku gbọrangandan.

''Ojiji ni wọn gbe e lọ si kootu, ti awọn ọlọpaa kunbẹ. Wọn ju ọmọ mi s'ẹwọn, wọn ju Naomi sẹwọn. Haa, mi o rẹni sọ fun mi pe bo ṣe maa ri fun mi ni Disẹmba 2024 ree o.

''Mi o mọ eeyan kankan o, ẹ saanu mi. Ẹyin tẹ ẹ padanu ọmọ ninu iṣẹlẹ yii, mo ba yin kẹdun, ko ni i ṣẹlẹ si yin mọ ẹ ṣaanu fun mi.

''Ẹ ba mi pe prẹsidẹnti Naijiria, mi o mọ ọn, ẹ ba mi pe gbogbo alagbara. Ti mo ba debi kan, wọn aa ni lati oke wa ni, mi o mọ eeyan kankan loke o, wọn o jẹ ki n ri ọmọ mi, ẹ ṣaanu mi o''

Iya Naomi lo fi omije bẹbẹ bẹẹ.

Wọ́n fi ẹ́sùn ìpànìyàn kan Naomi Silekunola

Lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kejila ọdun 2024 ni wọn gbe Naomi Silekunola lọ sile ẹjọ Majisireeti to wa ni Iyaganku, n'Ibadan.

Nibẹ ni Adajọ Olabisi Ogunkanmi ti paṣẹ pe ki wọn fi olori tẹlẹ naa pẹlu Oriyomi Hamzat to ni ileeṣẹ redio ti wọn ti kede eto naa si ahamọ ọgba ẹwọn.

Bakan naa ni adajọ paṣẹ pe ki wọn fi olori ile ẹkọ Islamic High School, Bashorun, Ibadan, ti eto naa ti waye si ẹwọn pẹlu, iyẹn Ọgbẹni Fasasi Abdulhahi Babatunde.

Ọgba ẹwọn Agodi ni Adajọ Ogunkanmi sọ pe ki wọn fi wọn pamọ si titi di igba ti igbẹjọ yoo tun waye lọjọ kẹrinla, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025.

Apa kan iwe ẹsun naa ka bayii pe:

''Iwọ Naomi Silekunola, Alh Oriyomi Hamzat, Fasasi Abdullahi Babatunde ati awon yooku ti wọn ti sa lọ bayii, gbimọ pọ lati huwa to le fa iku kiakia, lọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila ọdun 2024. Laaarin aago marun-un idaji si aago mẹjọ aarọ, ni ile ẹkọ Islamic High School, lagbegbe Bashorun. Fun idi eyi, e huwa tako abala 324 ofin iwa ọdaran ipinlẹ Oyo, ti wọn se lọdun 2000.