Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin tó gé orí ọ̀rẹ́ rẹ̀ fún oògùn owó

Paulinus Okon

Oríṣun àwòrán, Israel Joe

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọlopaa ipinlẹ Delta ti fi ṣikun ofin mu ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan to ji ọrẹ rẹ gbe, to si gbẹmi rẹ lọna ti fi ṣoogun owo.

Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ naa, Olufemi Abaniwonda sọ pe lati inu oṣu Kẹsan an ọdun yii ni ẹgbọn oloogbe naa ti sọ pe awọn n wa amọ ọrẹ rẹ gan lo gbẹmi rẹ.

Nigba ti iṣẹlẹ ọhun milẹ titi lori ayelujara pe wọn n wa oloogbe naa, Paulinus Okon, ni ọlọpaa bẹrẹ iṣẹ takuntakun lati ṣe ọfintoto ibi to wa.

Afurasi gba ₦N20m lọwọ mọlẹbi oloogbe naa

Abaniwonda sọ pe afurasi naa kọkọ ni oun ko mọ ohun to ṣẹlẹ si Paulinus amọ ọlọpaa ran leti pe niṣe lawọn mejeji jọ jade lọjọ to di awati.

O ni "Lẹyin akoko naa ni afurasi wa bere ₦500,000 lọwọ ẹgbọn oloogbe ọhun pe oun fẹ fi owo naa be babalawo kan lọwẹ lati ṣawari ibi ti aburo rẹ wa.

Lẹyin naa lo tun pada lọ ba mọlẹbi rẹ lati gba owo ti iye rẹ jẹ ₦20,715,000 lẹyin to sọ fun wọn pe akata awọn ajinigba lo wa, awọn ajinigbe naa si ti kan si oun.

Eyii lo mu ki awọn mọlẹbi rẹ funra si pe ejo lọwọ ninu.

Ọlọpaa ṣe iwadii finifini, ti esi iwadii wọn si fi han pe ọdọ ọkunrin ẹni ọdun mejidinlaadọta kan ni afurasi gbe oloogbe naa lọ.

Ọkunrin afurasi keji ọhun lo jẹwọ pe lootọ ni ọrẹ Paulinus gbe e wa ka oun mọle leti odo Orere to wa ni Otokutu pe ki awọn gbẹmi rẹ.

O fi kun pe oru ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹsan an, ọdun 2024 lawọn lọ ge ori rẹ nidi odo ti awọn si ju oku rẹ sinu odo ọhun.

Lẹyin ti wọn ge ori rẹ tan ni wọn sin ori ọhun si ojubọ kan.

CP Abaniwonda ṣalaye siwaju si pe afuriasi naa sọ fun ọlọpaa pe oun ri ile kan ti wọn n ta ni N30m ti oun si polongo ile naa fun Paulinus.

Paulinus san 30m naa fun afurasi lati ra ile ọhun amọ niṣe ni afurasi lo owo naa fun ara rẹ to si gbẹmi oloogbe naa ki akara ma baa tu sepo gẹgẹ bii ohun to sọ.