Kí ló kan iléeṣẹ́ rédíò Agidigbo nípa ìṣẹ̀lẹ̀ tó mú ẹ̀mí àwọn ọmọdé lọ níbi àpèjẹ Olori Naomi?

Oriyomi Hamzat àti Naomi Ogunwusi

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Igbimọ alaṣẹ ileeṣẹ redio Agidigbo FM niluu Ibadan ti sọ pe ileeṣẹ redio naa kọ lo ṣagbekalẹ eto apejẹ to waye lọgba ile-ẹkọ Islamic High School, to wa ni agbegbe Bashorun, nibi ti ọpọ oku awọn ọmọde ti sun.

Ọjọru, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kejila ọdun 2024 ni eyi waye.

Olori Ooni nigba kan, Naomi Silekunola Ogunwusi, lo ṣagbatẹru eto naa lati fi mu inu awọn ọmọde dun lasiko ọdun.

Ọdọọdun ni Olori Naomi ma n ṣe ariya naa, paapaa niluu Akure to n gbe. Amọ, ilu Ibadan lo ti ṣe eleyi to di wahala bayii.

Iroyin sọ pe eero to pọ ju ninu ọgba ile-ẹkọ Islamic High School, Bashorun, lo mu ki wọn o tẹ ara wọn pa, ti awọn miran si daku nitori ooru to mu wọn.

Lati ọsan ọjọ naa ti iroyin ti jade si ni awọn eeyan kan ti n pariwo oludasilẹ ileeṣẹ redio Agidigbo FM, Oriyomi Hamzat.

Eyi ko ṣẹyin bi wọn ṣe polongo apejẹ ọhun nibẹ. Koda, wọn ṣe akanṣe eto ifọrọwerọ pẹlu Olori Naomi lori redio naa lọjọ Iṣẹgun.

Ọga agba ẹka igbohun safẹfẹ ileeṣẹ redio naa, Ọgbẹni Olayinka AbdulWahab, lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita nirọlẹ Ọjọru.

Ọgbẹni AbdulWahab ni, o ṣe pataki lati jẹ kawọn araalu mọ pe ileeṣẹ redio naa kan jẹ ọkan lara awọn ileeṣẹ iroyin ti ajọ WINGS Foundation to ṣagbekalẹ eto naa lo lati polongo apejẹ ọhun ni.

Aworan ipolongo apejẹ
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọga agba ẹka igbohun safẹfẹ nileeṣẹ redio Agidigbo ni irọ nla ni iroyin tawọn eeyan kan n gbe kiri wi pe Agidigbo lo ṣagbekalẹ eto naa.

Ọgbẹni AbdulWahab sọ ninu atẹjade to fi sita pe ''lati aago marun-un idaji Ọjọru ti a ti ri pe ọpọ eeyan lo n lọ sibi eto naa ni a ti bẹrẹ si ni ṣe ilanilọyẹ wi pe kawọn eeyan ma lọ mọ nitori pe eero to ti wa nibẹ ti pọju.

Awọn to ṣagbekalẹ eto naa gbiyanju agbara wọn lati ri pe eero ko pọju nipa lilo awọn agbofinro atawọn oṣiṣẹ eleto ilera, amọ nnkan ti bọ sori.

"Ọjọ ibanujẹ ni ọjọ ti iṣẹlẹ yii waye jẹ fun wa ni Agidigbo, amọ, a rọ awọn eeyan wi pe ki wọn ye gbe irọ kiri pe ileeṣẹ redio Agidigbo lo ṣagbekalẹ eto apejẹ naa.

A fẹ ki ẹni ti ọrọ naa ba ru loju kan si wa nileeṣẹ wa fun alaye kikun lori ohun to ṣẹlẹ.''

Ọgbẹni AbdulWahab ni asiko yii kii ṣe akoko lati maa gbe irọ kiri.

O ni igbimọ alaṣẹ Agidigbo FM kẹdun pẹlu awọn ẹbi awọn ọmọde to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Bakan naa lo tun gbadura fawọn to wa nile iwosan wi pe ki Eledua fun wọn ni ilera pipe.

Atẹjade

Oríṣun àwòrán, Agidigbo FM