Gómínà Adeleke pàṣẹ ìtúsílẹ̀ ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n dájọ́ ikú fún nítorí pé ó jí adìyẹ̀

Gomina Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Gov Ademola Adeleke/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti kede sita pe oun ti bẹrẹ igbesẹ lati ṣe iwadii kikun nipa ọmọkunrin kan, Segun Olowookere ti wọn dajọ iku fun lọdun mẹwaa sẹyin.

Adeleke ni oun yoo rii daju pe idajọ ododo waye lori ẹjọ naa, ati pe ẹsun ti wọn fi kan ọmọdekunrin ọhun ko to idajọ to gba.

Olowookere ni Onidajọ Jide Faola ti ile-ẹjọ giga to wa niluu Ikirun, ipinlẹ Osun paṣẹ pe ki wọn lọ yẹgi fun lori ẹsun wi pe o ji adiyẹ ati ẹyin gbe ninu oko adiyẹ lọdun mẹwaa sẹyin.

Ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni Olowookere wa nigba ti Onidajọ Falola paṣẹ pe ki wọn lọ yegi fun oun pẹlu ẹnikẹji rẹ, Morakinyo Sunday.

Ki ni Gomina Adeleke sọ?

Ninu atẹjade ti Gomina Adeleke gbe jade lati ọwọ agbẹnusọ rẹ, Olawale Rasheed lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kejila, o ni ki adajọ agba ipinlẹ naa tete dide iwadii.

Gomina Adeleke ni bi adajọ ba ṣewadii naa tan, ko rii daju pe orukọ ọmọkunrin naa wa ninu orukọ awọn ti wọn yoo fi oju aanu wo ki ọdun too pari.

"Ninu ẹjọ yii, mo ti paṣẹ fun Kọmiṣanna feto idajọ lati bẹrẹ igbesẹ lati foju aanu wo ọmọkunrin naa.

"Ipinlẹ Ọṣun jẹ ipinlẹ ti kii ṣe ojusaaju ninu ofin. A ni lati rii daju pe a n daabo bo awọn eeyan nipa ilana.

"Mo ni lati sọ fawọn araalu wi pe ẹjọ naa n kọ mi lominu. Ti a si gbọdọ gbe igbesẹ pajawiri lati rii pe a ṣe ojuṣe wa gẹgẹ bi ijọba araalu."

Bawo ni Gomina Adeleke ṣe gbọ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ajọ kan ti wọn pe ni World Institute of Peace ni wọn lo dide idirẹbẹ fun Segun Olowookere.

Alakoso ajọ naa, Lamina Kamiludeen Omotoyosi ṣalaye pe ọdun mẹwaa ṣeyin ni wọn dajọ iku fun Olowookere nigba to wa lọmọ ọdun mẹtadinlogun lori ẹsun wi pe o ji adiyẹ gbe.

Omotoyosi jẹ ko di mimọ pe "idajọ ti wọn fun Segun lo nii ṣe pẹlu ẹsun jiji adiyẹ kan ati awọn ẹyin gbe ninu oko nnkan ọsin to wa ni Oyan, ipinlẹ Osun lọdun mẹwaa sẹyin.

"Idajọ iku ti wọn fun iru ẹṣẹ yii lo n beere oniruuru ibeere ni ilana ofin, paapaa nigba ti a ba n ṣagbeyẹwo ọjọ ori ti Segun wa, ti wọn fi dajọ naa, ati iru ohun ti wọn lo ji.

"Ṣugbọn ṣa, ko si awawi fun eyikeyi iwa ọdaran. ṣugbọn Segun sọ pe oun ko jẹbi lori ẹsun ti wọn fi kan oun yii.

"Awọn obi Segun, Folashade ati Olanrewaju Olowookere ni wọn ti n sọrọ sita, ti wọn si n bẹbẹ kaakiri pẹlu omije loju, lori bi ọmọ ọkunrin kan ṣoṣo ti wọn ni ṣe wa lẹwọn lati ọdun mẹwaa sẹyin.

"Gẹgẹ bi ẹ ti mọ, ilana idajọ ati oju aanu jẹ eyi to ṣe pataki ninu agbegbe to n ni idagbasoke.

"Awọn obi yii ti bẹbẹ pẹlu ẹdun ọkan, ti wọn si n tẹnu mọ-ọn pe Segun jafafa, ati pe ọlọpọlọ pipe to ni afojusun ọjọ ọla rere ni ọmọ wọn.

"Wọn ti n farada ijiya ọjọ pipẹ, ti wọn si ti ta gbogbo dukia ti wọn ni lojuna lati gba ọmọ wọn jade, pẹlu bi wọn ṣe n ni ireti igbakeji fun ọmọ wọn.

"Idajọ nla naa kọja iru ẹsun ti wọn fi kan an, to si foju han gbangba wi pe ẹjọ Segun yẹ lati boju aanu wo. Gomina, ẹ dakun," Omotoyosi sọ ninu atẹjade to fi sita.

Ki lo ṣẹlẹ gangan?

Segun ati Morakinyo Sunday ni iroyin sọ pe o fipa lọ ja ilẹkun ile ọlọpaa kan ti wọn pe ni Balogun Tope, ẹni to n ṣiṣẹ nileeṣẹ ọlọpaa ẹkun Okuku.

Ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun 2010 ni wọn lawọn mejeeji yii wọle Ọgbẹni Tope, ti wọn si ji awọn dukia rẹ ko lọ.

Lẹyin o rẹyin ni wọn sọ pe ọwọ tẹ Segun ati Sunday, ti wọn si fẹsun igbimọ papọ, idigunjale, ati ole jija kan wọn, ni ibamu pẹlu abala kẹfa, ipin keji ati abala kinni, ipin keji ninu iwa ofin iwa idigunjale ati ohun ija oloro lorileede Naijiria ti ọdun 2004, ati abala aadọrunlelọọdunrun, ipin kinni (Section 390(1)) ninu iwa ofin ọdaran tipinlẹ Osun lọdun 2002.

Igbimọ to fẹsun kan awọn mejeeji naa, ti Arabinrin Abiola Adewemimo lewaju wọn, ni wọn lo pe ẹlẹrii mẹfa ọtọọtọ to tako wọn, pẹlu oniruuru ẹri ti wọn ko silẹ.

Ki lo ṣẹlẹ nile ẹjọ

Awọn olufẹsunkan naa sọ fun ile-ẹjọ wi pe lọjọ kẹtala, oṣu Kọkanla, ọdun 2010, wọn kofiri awọn ọkunrin naa layika ile Balogun pẹlu ada ati ibọn, ati pe nigba tọwọ tẹ awọn meji, awọn yooku na papa bora.

Wọn lawọn ti wọn fẹsun kan yii gba pe lotitọ lawọn jẹbi wi pe lotitọ lawọn ji adiẹ gbe, ati pe awọn ti figba kan ri jale nile ọkunrin naa ri.

Adewemimo fi kun ọrọ rẹ pe "awọn mejeeji tun sọ pe ṣaaju asiko naa, awọn ti lọ jale nile Alaaja Umani Oyewo, ti awọn si ji awọn adiẹ, ẹyin adiẹ ati ọpọlọpọ ike ororo gbe."

Lẹyin awijare lati ọdọ awọn eeyan naa, Onidajọ Jide Falola ṣe idajọ lori ẹsun mẹta pere to nii ṣe pẹlu: idajọ iku lori igbimọ papọ; ẹwọn gbere lori ẹsun idigunjale, ati ẹwọn ọdun mẹta lori ole jija.

Onidajọ Falola ninu idajọ rẹ jẹ ko di mimọ pe gomina le tun ero rẹ pa lati yi idajọ iku naa si ẹwọn ọdun mẹwaa, to ba n ṣagbeyẹwọ ọjọ ori wọn.

Awọn obi Segun sọ ohun ti oju wọn ri

Baba Segun, Ọgbẹni Olanrewaju Olowookere, nigba to n bẹbẹ fun oju aanu laipẹ yii, jẹ ko di mimọ pe ko sigba kan ti Segun fi lọwọ si iwa ọdaran tabi idigunjale.

Ọkunrin naa sọ pe inu ṣọọbu loun pẹlu Segun wa, ati pe ọmọ oun pẹlu awọn ọrẹ rẹ ni wọn jọ n ṣere lọwọ lọjọ ti wọn wa mu, to si ni awọn kan lo ditẹ.

O ni "Nibi tọrọ de duro bayii, a ko nilo ohunkohun ju iranlọwọ Gomina Ademola Adeleke lọ lati foju aanu wo ọmọ wa. Inu ibanujẹ ọkan la wa latigba ti wọn ti dajọ fun un.

"A ko tii figba kan ri ni imọriri idunnu ati ayọ latigba naa. Ko si ẹni ti inu rẹ yoo dun, nigba to ba n ri ọmọ rẹ lọgba ẹwọn."

Bakan naa, mama Segun, Arabinrin Folashade Olowookere, nigba toun naa n rawọ ẹbẹ fun ọmọ rẹ, sọ pe Segun ti kẹkọọgboye ni fasiti kan lẹyin to kẹkọọ nipa iṣẹ iṣegun oyinbo lẹwọn.

"Mo fẹẹ rawọ ẹbẹ si gomina wa, Sẹnetọ Ademola Adeleke lati lo ipo rẹ fi da ọmọ wa silẹ. A ti ta awọn dukia wa lati le rii pe a gba Segun silẹ latigba ti wọn ti dajọ fun un lọdun 2014.

"Ọmọ to jafafa to si ni ọjọ iwaju rere niwaju rẹ ni. A ko gbọdọ faaye silẹ lati jẹ ki aye rẹ bajẹ sinu ọgba ẹwọn," Arabinrin Olowookere ṣalaye.