Àwọn ọmọ Nàìjíríà márùn ún tó ti gbàmì ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tó pegedé jùlọ l'Afirika ṣaájú Lookman

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹlẹsẹ ayo ikọ Super Eagles Naijiria ati ẹgbẹ agbabọọlu Atalanta, Ademola Lookman, ni agbabọọlu ọkunrin kẹfa lati Naijiria ti yoo gbami ẹyẹ agbabọọlu to pegede julọ nilẹ Afirika.
Lalẹ ọjọ Aje nibi ayẹyẹ kan to waye niluu Marrakech lorilẹede Morocco ni ajọ CAF to n ri si ere bọọlu afẹsẹgba l'Afirika ti kede Lookman gẹgẹ ọba awọn agbabọọlu nilẹ Afirika lọwọ yii.
Ni bayii, igba meje ọtọtọ ni orilẹede Naijiria ti gba ami ẹyẹ ere bọọlu yii lati igba to ti bẹrẹ.
Igba akọkọ ree ti orilẹede Naijiria yoo gbami ẹyẹ ere bọọlu yii lera lera lati ọdun 1997 ti Victor Ikpeba gba ami ẹyẹ naa lẹyin ti Nwakwo Kanu ti kọkọ gba a lọdun 1996.
Awọn agbabọọlu Naijiria to ti gbami ẹyẹ agbabọọlu to pegede julọ l'Afirika ṣaaju Lookman
Rashidi Yekini - 1993

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbaọjẹ agbabọọlu ikọ Super Eagles tẹlẹ ri to ti doloogbe bayii, Rashidi Yekini, ni agbabọọlu Naijiria akọkọ to gba ami ẹyẹ agbabọọlu to pegede julọ nilẹ Afirika lọdun 1993.
Gbogbo ololofẹ ere bọọlu lo mọ Rasidi fun donbo to n maa n gbọ sawọn nigba aye rẹ.
Koda, oun ni ẹlẹsẹ ayo lo gba bọọlu sawọn julọ ninu idije AFCON ọdun 1992 ninu eyi ti Super Eagles ti gba ipo kẹta.
Iyẹn nikan kọ o, Rashidi tun fakọyọ fun ikọ agbabọọlu Vitoria Setubal ni saa bọọlu 1992/1993 nibi to ti gba ọgbọn goolu sawọn ninu ninu ere bọọlu ọgbọn to gba.
Eyi gan an jẹ ọkọn lara idi ti ajọ CAF sẹ fi ami ẹyẹ agbabọọlu to dantọ julọ nilẹ Afirika da a lọla.
Emmanuel Amuneke – 1994

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin ti Rashidi Yekini ṣide ami ẹyẹ yii fun Naijiria tan lọdun 1993 ni Emmanuel Amuneke fọba le e lọdun 1994 nigba toun naa gbami ẹyẹ yii fun Naijiria.
Amuneke gba goolu meji wọle ninu ere bọọlu aṣekagba idije AFCON 1994 ninu eyi ti Naijiria ti la Zambia mọlẹ gba ife ẹyẹ idije naa lorilẹede Tunisia.
Amuneke tun wa lara awọn agbabọọlu Super Eagles to fakọyọ fun Naijiria ninu idije ife ẹyẹ agbaye ọdun 1994 to waye lorilẹede Amẹrika.
Eyi gan an lo jẹ la George Weah ati Yekini mọlẹ gba ami ẹyẹ agbabọọlu ilẹ Afirika to dantọ julọ lọdun 1994.
Nwankwo Kanu - 1996, 1999

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nwankwo Kanu ti ọpọ mọ si Papilo ni agbabọọlu Naijiria kan ṣoṣo to gbami ẹyẹ agbabọọlu ilẹ Afirika to dantọ julọ lẹẹmeji.
Ọdun 1996 ni Kanu kọkọ gba ami yii lẹyin to fakọyọ ninu idije Atlanta '96 to waye lorilẹede Amẹrika.
Manigbagbe ni goolu meji ti Kanu gba wọle fun Naijiria ni ipele to kangun si aṣekagba nibi ti Naijiria ti koju orilẹede Brazil.
Kanu gba ami ẹyẹ yii fun igba keji lọdun 1999 nigba to n ṣoju ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal.
Lẹyin to gbadun iṣẹ abẹ ọkan to ṣe tan lo darapọ mọ Arsenal ti o si bẹrẹ si ni fakọyọ fun ẹgbẹ agbabọọlu naa.
Victor Ikpeba - 1997

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹlẹsẹ ayo Victor Ikpeba ni agbabọọlu Naijiria kẹrin ti yoo gba ami ẹyẹ agbabọọlu to pegede julọ nilẹ Afirika.
Ọdun 1997 ni Ikpeba gbami ẹyẹ naa lẹyin ti Kanu ti kọkọ gba a lọdun 1996.
Ikpeba to n gba bọọlu fun ikọ AS Monaco nigba naa fakọyọ debi pe awọn ololufẹ ere bọọlu bẹrẹ sii pe e ni Ọmọba Monaco.
Goolu mẹrindinlọgbọn lo gba sawọn fun Monaco lọdun naa eyi to ṣe iranwọ fun Monaco gba ife ẹyẹ liigi.
Victor Osimhen - 2023

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lati ọdun 1999 ti Nwankwo Kanu ti gami ẹyẹ naa kẹyin, ko si ọmọ Naijiria to tun ri ami ẹyẹ naa gba mọ titi di ọdun 2023.
Ẹlẹsẹ ayo, Victor Osimhen, ni agbabọọlu Naijiria to tun gbami ẹyẹ naa lọdun 2023.
Osimhen fakọyọ fun ẹgbẹ agbabọọlu rẹ, Napoli lọdun 2023 debi wi pe o gba goolu mẹrindinlogun sawọn eyi to ṣeranwọ fun Napoli lati gba idije liigi Seria A ni Italy.
Igba akọkọ si niyẹn ti Napoli yoo gba ife ẹyẹ naa fun ọdun mẹtalelọgbọn.
Osimhen tun fakọyọ fun ikọ Super Eagles bakan naa lọdun 2023.















