Ìdí tí owó àlùbọ́sà fi wọ́n lọ́dún 2024 ju àwọn ọdún yòókù lọ

Alubosa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Alubọsa jẹ ọkan pataki lara awọn eroja ti awọn eeyan fi n se ounjẹ ni gbogbo igba - awọn ounjẹ bii ẹfọ riro, ọbẹ sise, ata dindin ati bẹẹbẹẹlọ ni wọn n lo alubọsa si.

Yatọ si pe wọn n fi alubọsa kun eroja ounjẹ, o tun jẹ ọkan pataki lara eroja to n mu ki ounjẹ tasansan.

Ainiye ni igba ti owo alubọsa ti lọ soke, to si tun ti wa silẹ laarin ọja kaakiri orileede Naijiria lọdun 2024 ti a wa yii.

Owo alubọsa si ti lọ soke lọdun 2024 ju bo ṣe maa n lọ soke lawọn ọdun to kọja lọ.

Eyi si n jẹ ki awọn eeyan maa kọminu, to si tun jẹ iyalẹnu lori ohun to fa bi owo alubọsa ṣe n lọ soke ni gbogbo igba, ati igba ti owo rẹ yoo pada si bo ṣe wa tẹlẹ.

Iwadii BBC fihan pe ẹgbẹrun lọna igba si ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira ni wọn n ta apo alubọsa kan bayii.

Ẹgbẹrun lọna ọgbọn si ẹgbẹrun lọna ogoji naira ni wọn n ta apo alubọsa naa tẹlẹ lawọn oṣu diẹ sẹyin.

Ki lo fa bi owo alubọsa ṣe lọ soke lọdun yii?

Iwadii BBC jẹ ko di mimọ pe ko sohun meji to fa bi owo alubọsa ṣe fo soke lọdun 2024 , to kọja ojo to fa omiyale lasiko ojo lọdun yii.

Ọkan lara awọn agbẹ ni Naijiria to ba BBC sọrọ, ṣalaye pe omiyale ba awọn alubọsa jẹ pupọ lọdun yii.

Saadu Gata, ontaja kan to n alubọsa jẹ ko di mimọ pe omiyale ṣọṣẹ buruku, to si da wahala tawọn eeyan n koju lasiko yii silẹ.

"Lọdun yii, ọpọ ojo lo rọ, to si ba awọn alubọsa ti a gbin sinu oko jẹ gidi gan-an".

O fi kun ọrọ rẹ pe "Keresimesi to wọle de tun jẹ ọkan lara awọn ohun to ṣokunfa wahala bowo alubọsa ṣe lọ soke. Idi niyi ti a fi n ra alubọsa ni ẹgbẹrun lọna okoolenigba si ẹgbẹrun lọna ọgbọnlenigba naira ni Kano, o tun nii ṣe pẹlu bi awọn alubọsa ọhun ba ṣe tobi si."

Lawọn ilu kan lẹkun Gusu, bii Port Harcourt owo ti ko din ni ẹgbẹrun lọna aadọrinlenigba ni wọn n ta apo nla, nigba ti wọn n ta apo kekere laarin ẹgbẹrun lọna ọgọjọ si aadọsan naira.