Ọwọ́ EFCC tẹ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè 158 tó ń kọ́ àwọn ọmọ Naijiria ní 'Yahoo-yahoo'

Oríṣun àwòrán, EFCC
Ẹgbẹrin din mẹjọ eeyan (792) ni ajọ Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ti kede bayii, pe awọn mu nipinlẹ Eko, lori ẹsun kikọ awọn ọmọ Naijiria nipa bi wọn ṣe le maa lu jibiti lori ayelujara.
Gẹgẹ bi EFCC ṣe wi, ọna kan gboogi ti wọn n gba kọ wọn ni nipa lilo ifẹ, ṣiṣe ileri ifẹ fun eeyan lori ofo. Ẹni ti wọn n parọ fun ko ni i mọ, yoo maa fi owo ranṣẹ si wọn.
Wilson Uwujaren, agbẹnusọ EFCC lo sọ eyi di mimọ lorukọ Ola Olukoyede, Alaga EFCC.
Nigba to n ṣalaye iṣẹlẹ naa lọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kejila ọdun 2024, Olukoyede sọ pe ile nla kan to wa lojule keje, opopona Oyin Jolayemi, Victoria Island nipinlẹ Eko, ni wọn ti n kẹkọọ nipa jibiti lilu lori ayelujara.
O ṣalaye pe ọmọ orilẹ-ede China mejidinlaaadọjọ (148), Philippines ogoji (40), ọmọ ilẹ Kharzar meji ati Pakistan kan lọwọ ba, to fi mọ awọn ọmọ Naijiria naa.
Akojọpọ iye awọn ajeji tọwọ ba jẹ mejidinlọgọjọ (158), nigba ti awọn yooku jẹ ọmọ orilẹede Naijiria, ti iye wọn si jẹ 634.
Ninu ile alája meje kan ni wọn ti mu wọn.
"Ni àjà karun-un ile naa, oju opo foonu ẹẹdẹgbẹta (500 lines) ni awọn ọtẹlẹmuyẹ ri, pẹlu oriṣiiriṣii ẹrọ ibaraẹnisọrọ ti wọn fi n ṣe iṣẹ jibiti.
"Wọn n lo awọn ọmọ Naijriia lati lu awọn ọmọ ilẹ okeere ni jibiti, awọn to wa lati America, Canada, Mexico atawọn apa ilẹ Europe mi-in."
EFCC sọ pe ọjọ kẹwaa, oṣu Kejila ọdun 2024 ni aṣiri awọn eeyan naa tu.

Oríṣun àwòrán, EFCC/X
''Bí wọ́n ṣe ń lu jìbìtì ìfẹ́ ni wọ́n ń gba owó ńlá lọ́wọ́ àwọn èèyàn''
EFCC fi kun un pe ilana okowo igbalode ti wọn n pe ni Crytocurrency, ni awọn onijibiti yii tun maa n lo, bi wọn ko ba purọ ifẹ.
Wọn fi kun un pe ko si ẹni ti yoo ri ile ti wọn ti n kẹkọọ jibiti ọhun ti ko ni i ro pe ọfiisi awọn eeyan ojulowo iṣẹ ni.
"Wọn n kọ awọn ọmọ Naijiria lati maa lo ayederu idanimọ loju opo WhatsApp, instagram ati Telgaram.
"Wọn ti kọ wọn bi wọn ṣe le ṣide ọrọ sisọ pẹlu ẹni ti wọn fẹẹ lu ni jibiti, oju opo www.yooto.com, ni wọn n lo, eeyan yoo si san $35 to kere ju ki idunaa-dura too bẹrẹ.
"Bi ẹni ti wọn fẹẹ ṣe gbajuẹ fun ba ti ko si wọn lọwọ, awọn ajeji to n kọ wọn lẹkọọ ni yoo maa ṣeto yooku lọ. Wọn yoo yọwọ awọn ọmọ Naijiria kuro nibẹ"
Bẹẹ ni Alaga EFCC ṣalaye.
O ni bi awọn tọwọ ba yii ba fẹẹ sanwo fawọn ọmọ Naiiria, wọn ki i lo akanti kankan, niṣe ni wọn maa n ko owo naa le wọn lọwọ.
"O fi kun un pe awọn ajeji naa n lo Naijiria bii ibudo iwa jibiti, lati fi bo aṣiri iṣẹ ibi ti wọn n ṣe.
Olukoyede ni bi ọwọ ṣe ba wọn yii fi han pe, ki i ṣe gbogbo jibiti to n ṣẹlẹ ni Naijiria ni awọn ọmọ orilẹede yii n lọwọ si.
EFCC ko ṣai gba ọpọ nnkan bii kọmputa, foonu, ẹrọ agbeletan ati mọto lọwọ awọn afurasi naa.
Wọn ti gba ọrọ ẹnu wọn silẹ, wọn fi wọn si ahamọ, iwadii si ti n lọ lọwọ bi EFCC ṣe sọ.

Oríṣun àwòrán, efcc/X












