Àwọn alákatakítí ẹ̀sìn jí mi gbé fún ọ̀sẹ̀ méjì, wọ́n ní dandan ni kí n darapọ̀ mọ́ àwọn

Ghana

Oríṣun àwòrán, Michael Mvondo / BBC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọkunrin ọmọ orilẹede Ghana kan ti ṣalaye fun BBC bi awọn alakatakiti ẹsin ṣe ji gbe loju ibọn ni Burkina Faso, ti wọn si ru u lọ sinu igbo kojikiji nibi to ti ni iriri bi wọn ṣe n gbe igbeaye wọn.

Pẹlu nnkan ti oju rẹ ri ni agọ wọn, o ni oun gbagbọ pe lati kekere ni wọn ti n kọ wọn bi wọn ṣe n wu iwa igbesunmọ ti wọn si n kọ wọn bi wọn yoo ṣe so ado oloro mọ ara wọn.

Ọkunrin ọhun, ti a pe orukọ rẹ ni James, lati daabo bo o, sọ pe inu ibẹru bojo loun wa lọjọ akọkọ ti oun de inu agọ wọn.

James sọ pe ṣe ni awọn alakakiti ẹsin Islam naa n yinbọn soke ninu agọ ọhun latari pe wọn ṣẹṣẹ de lati ode ti wọn ti lọ ji eeyan gbe ni.

O ni "Ni ṣe ni mo n laagun, mo ro pe opin ti de lọjọ naa ni."

Lọjọ naa lọhun, James tọ si ṣokoto nigba to ro pe ọjọ naa gan ni oun yoo jade laye lẹyin ti awọn kan lara wọn la idi ibọn mọ ti wọn si bẹrẹ si n rẹrin.

Ọkunrin ọhun to jẹ oniṣẹṣe sọ pe awọn agbesunmọmi naa gbiyanju lati mu ki oun darapọ mọ wọn, koda, wọn ṣeleri pe oun le di ọga ninu ẹgbẹ wọn lọjọ iwaju, amọ o kọ jalẹ.

James ṣalaye pe "Olori wọn gbe apo kan jade ti oniruru ibọn bii Ak-47, M16 ati G3 wa ninu rẹ, o wa bere lọwọ mi eyii ti mo le lo ninu rẹ, mọ sọ fun pe mi o yin ibọn ri."

Ọkunrin naa sọ pe ori lo ko oun yọ ti wọn tu oun silẹ laarin ọsẹ meji pere lẹyin ti oun bẹbẹ pe oun ni ọmọ kekere to n ṣaisan nile, ti oun si tun ṣeleri fun olori wọn pe oun yoo ba wọn wa awọn ti yoo darapọ mọ ẹgbẹ wọn bo tilẹ jẹ pe ileri ori ahọn lasan ni.

Ajọ to n ṣe idanilẹkọọ fun awọn ọdọ ki wọn ma baa darapọ mọ ẹgbẹ agbesumọmi ni Ghana, National Commission on Civic Education, sọ pe awọn mọ nipa iriri James.

Ẹgbẹ Jama'at Nusrat al-Islam wal-Muslimin (JNIM), to ni ibaṣepọ pẹlu ẹgbẹ al-Qaeda lo ji ọkunrin naa gbe.

Ẹgbẹ naa gbilẹ gidi ni Burkina Faso to bẹẹ ti nnkan bii ẹgbẹrun marundinlogun eeyan sa kuro ni orilẹede naa lati maa gbe ni Ghana.

Yatọ si Burkina Faso, awọn agbesunmọmi naa tun ti gbilẹ ni Mali ati Niger, bẹẹ ni wọn tun n ṣọṣẹ ni Ivory Coast, Benin ati Togo.