'Àsàsí ló mú mi pa ọmọ mi lọ́mọ́ oṣù kan ààbọ̀, kìí ṣe pé mo fẹ́ fi ṣe ètùtù ọlà'

Oríṣun àwòrán, Oloburo Afopina/Facebook/
Ọmọọṣẹ babalawo kan, Michael Ifagbenga Taiwo , ni ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti mu bayii, fun ẹsun pe o dunbu ọmọ rẹ, ọmọ ọjọ mọkanlelogoji, ni agbegbe Adatan, niluu Abeokuta.
Iroyin sọ pe Ifagbenga, ẹni ọdun mẹtalelogun, pa ọmọ rẹ ọkunrin ni ọjọ Aje, ọj kẹsan-an, oṣu Kejila, nibi ti ọmọ tuntun naa sun si lori ibusun ti iya gbe si.
Iya ọmọ naa, Raimat Wasilat, tẹ ọmọ ọhun si inu yaara, to si n fọ aṣọ niwaju ile wọn to wa ni adugbo Keesi, Adatan.
Nigba ti Wasilat pada sinu yara, lo ba ọmọ rẹ ti wọn ti fi ọbẹ ge ọrun rẹ, to si pariwo sita.
Ninu ọrọ to ba awọn akọroyin sọ ni agọ ọlọpaa, afurasi naa, Ifagbenga Taiwo to jẹ baba ọmọ, sọ pe asasi tabi eedi lo mu ki oun pa ọmọ naa.
Gẹgẹ bi Taiwo ṣe sọ, o ni oun fun iyawo oun ni owo ounjẹ lasiko ti oun n jade lọ sibi to ti n kọ iṣẹ babalawo.
"Bi mo ṣe de ibi'ṣẹ lọjọ naa, mo kiyesi pe mo gbagbe awọn oogun kan ti mo fi n ṣọra, eyi to mu ki n pada sile lati mu wọn."
Taiwo sọ pe nigba ti yoo fi to wakati kan ti oun pada si ibi'ṣẹ, afẹfẹ kan fẹ lu oun, ti ara oun ko si balẹ mọ.
"Niṣe lo dabi i pe nnkankan n rin kaakiri ara mi, o si n ṣe mi bii ki n daran."
Arakunrin naa sọ pe bi oun ṣe de ile pada, oun ko ba iyawo oun nibi to ti n fọ aṣọ, to si wọle lọ ọ ba ọmọ tuntun nibi to sun si, nibi to ti fi ọbẹ dunbu rẹ bi adiyẹ.
Ile ti Taiwo n gbe pẹlu iyawo ati ọmọ ni iya rẹ naa n gbe.
O ni bi oun ṣe wọle ni o n ṣe oun bi ki oun daran
"Mo wọ yaara iya mi lọ, mo si mu ọbẹ ti a ra lọja Kuto lati fi pa ẹran ikom ọmọ naa. ọbẹ hun ni mo si fi pa ọmọ mi."
Ọgbẹni Taiwo sọ pe nigba ti oun pa ọmọ naa tan, ni iye oun ṣẹṣẹ pada, ti oun si ri pe ọmọ oun ti ku, "mo bẹrẹ si n wo o pe ki lo sẹlẹ, nitori pe ọbẹ ti mo lọ ọ mu ni mo ranti kẹhin".
Afurasi naa sọ pe bi iye oun ṣe pada, ni oun sa gba ọna ẹyinkule ile naa jade, nitori pe ẹru ba oun.
Ninu fidio naa, o kọ jalẹ pe oun ko ni erongba lati fi ọmọ naa ṣe ohunkohun, ju pe asasi ni bi oun ṣe pa akọbi ọmọ oun, tako igbagbọ awọn eeyan kan pe, oun fẹ fi ọmọ naa ṣe oogun ni.
Ṣaaju ni fidio kan ti jade si ori ayelujara, nibi ti awọn ara ile naa ti sọ pe oju ferese ni awọn afurasi to gba ẹmi ọmọ tuntun naa, gba wọle ṣe iṣẹ ibi wọn.
Ọjọ naa gan-an ni awọn ọlọpaa ti kọkọ mu baba ati iya ọmọ lọ si agọ wọn, ki iwadii wọn to fidirẹ mulẹ pe, baba ọmọ, Ifagbenga Taiwo, lo pa ọmọ.












