Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn tó fi èpè ránṣẹ́ sí Ààrẹ Tinubu àti ọ̀gá àgbà ọlọpàá dèrò àtìmọ́lé

Oríṣun àwòrán, Olamide Thomas
Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti fi ṣikun ofin mu obinrin ajafẹtọọ ọmọniyan kan, Olamide Thomas, lori ẹsun pe o ṣẹ epe fun Aarẹ Bola Tinubu ati olori ileeṣẹ ọlọpaa, Kayode Egbetokun.
Yatọ si pe o jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan, a gbọ pe iṣẹ eto ilera, nọọsi ni obinrin naa n ṣe.
Iroyin sọ pe agbegbe Bariga, niluu Eko ni wọn ti mu obinrin naa lọ si atimọle ọlọpaa ni Panti.
Lẹyin naa ni iroyin ni, wọn gbe e kuro ni Panti lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Abuja.
Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ
Ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024 ni wahala naa bẹrẹ fun Olamide lasiko iwọde iranti EndSARS.
Asiko iwọde naa ni ọlọpaa ti kọkọ da seria fun, gẹgẹ bii fidio ti a foju ri.
Nibi iwọde naa lo ti bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ lu Aarẹ Bola Tinubu, to si n fi epe ṣọwọ si oun ati ọmọ rẹ, to fi mọ ọga ileeṣẹ ọlọpaa.
Ẹsun ti arabinrin naa fi kan ọlọpaa nipe wọn yin gassi tajutaju si oun lasiko iwọde iwọde, wọn tẹ ẹtọ oun gẹgẹ bii ọmọ Naijiria loju mọle, wọn si fi iya jẹ oun lọna aitọ.
Ọkan lara awọn eeyan rẹ to wa nibi iwọde naa, Tomide Netufo, ti oun naa jẹ ajafẹtọ ọmọniyan ṣalaye fun BBC pe, ṣe ni obinrin ọhun kọkọ ro pe ibọn lo ba oun lọjọ naa lọhun.

Oríṣun àwòrán, Tomide Netufo
O ni "inu ile rẹ ni wọn wa mu, iro lasan lo ro mọ aya nigba ti wọn mu lọjọ mẹta sẹyin.
"Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin ni awọn ọlọpaa tu mu, wọn ko wu iwa ọmọluabi si rara, wọn ni oju wọn gan ko ti maa mura, eyii ti ko yẹ ko ri bẹẹ.
"Ẹgbọn rẹ ọkunrin ni wọn kọkọ mu nigba ti wọn n wa, ọrọ ẹgbọn rẹ naa ni wọn fi tọpinpin ile to n gbe."
Tomide ṣalaye pe lẹyin ọjọ keji ti wọn mu obinrin naa tan ni wọn wa fi ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Venza kan to ni nọmba idanimọ KTU 582HX gbe lọ sinuu baalu ti wọn fi gbe lọ siluu Abuja.
NIbo ni obinrin naa wa bayii?
Gẹgẹ bii ohun ti Tomide sọ fun BBC, olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Abuja ni obinrin naa wa bayii ninu atimọle.
O ni wọn kọkọ gbe lọ si ẹka ti wọn ti n ṣe iwadii iwa ọdaran, FCID, ki wọn to tun tare rẹ lọ ẹka ti wọn ti n ṣe iwadii iwa ọdaran ori ayelujara, Cybercrime.
Tomide fi kun pe ohun ti obrinin naa sọ ko tii to ohun to yẹ ki ijọba fi baalu gbe lati ilu Eko lọ Abuja lori.
O pari ọrọ rẹ pe awọn agbẹjọro awọn ajafẹtọ ọmọniyan ti wa ni ileeṣẹ ọlọpaa naa lati da si ọrọ ọhun.
Ẹwẹ, gbogbo akitiyan BBC Yoruba lati ba alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Ọmọba Olumuyiwa Adejobi sọrọ lori ọrọ naa lo ja si pabo.















