Ecowas fẹ́ la ọ̀nà láti Ivory Coast sí Naijiria

Oríṣun àwòrán, AFP
Awọn aarẹ ni Iwọ oorun Afrika ti n gbaradi lati bẹrẹ si ni la oju ọna kan ti yoo so oril-ede Iwvory Coast pọ mọ Ghana, lọ si Togo titi de Benin Republic, ti yoo si pari si ilu Eko ni Naijiria.
Oju ọna naa yoo jẹ 1,028km, ni awọn onigbọwọ ati oludokowo ti jẹjẹ $15.6bn fun ṣiṣe rẹ.
Ọdun 2026 ni ireti wa pe iṣẹ yoo bẹrẹ lori rẹ.
Ọdun mẹjọ sẹyin ni wọn ti buwọlu oju ọna ọhun ti yoo lọ kaakiri Iwọ oorun Africa.
Afojusun fun opopona ni pe yoo wa ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu eyi ti awọn orilẹ-ede ilẹ Yuroopu ṣe fun idagbasoke okoowo ati ilọsiwaju.
Oju ọna ọhun, ti wọn ba pari rẹ ṣe e ṣe ko pese iṣẹ to to 70,000 , ti ireti si wa pe yoo pari lọdun 2032.
Lara nnkan ti yoo wa ninu oju ọna ọhun ni kọ oju'rin ti yoo gba eti okun kọja.
Pupọ ni awọn ilu ti ọna naa yoo gba, lo jẹ abawọle si ibudokọ oju omi.
Awọn ilu to tobi ju ni Ila oorun Africa ni oju ọna naa yoo so papọ - Abidjan, Accra, Lomé, Cotonou ati Eko.
Igbagbọ wa pe iṣẹ oju ọna naa yoo mu ki kara-kata o rọrun si i ti yoo si tun maa ya daadaa laarin awọn orilẹ-ede naa bi ti EU.
Ajọ Ecowas buwọlu u pe Mali, Niger ati Burkina Faso le da duro
Awọn alaṣẹ ajọ Economic Community of West African States, ECOWAS, ti buwọlu u pe ki awọn orilẹ-ede mẹta to fẹ kuro laarin wọn, Niger, Mali ati burkina Faso , maa lọ.
Eyi tumọ si pe lati ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kini, ọdun 2025, awọn orilẹ-ede mẹtẹta ko nii jẹ ọmọ ẹgbẹ ECOWAS mọ.
Igbesẹ ti awọn olori ECOWAS gbe yii, jẹ ọkan lara awọn adehun ti wọn fi ọwọ si nibi ipade ijiroro wọn to pari niluu Abuja lọjọ Aiku, pe ki wọn jẹ ki awọn orilẹ-ede mẹtẹẹta to wa labẹ iṣakoso ologun lọwọlọwọ, o da duro.
Ninu atẹjade to fi sita, akọwe ajọ naa, Omar Touray, sọ pe awọn adari ECOWAS bọ̀wọ̀ fun erongba awọn orilẹ-ede ọhun lati ya kuro ninu ajọ naa.
Amọ ṣa, wọn ni lootọ ni awọn ti yọnda wọn lati maa lọ, ṣugbọn ilẹkun ṣi silẹ fun wọn fun oṣu mẹfa – ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kini si ọjọ kọkandinlọgbn, oṣu Keje ọdun 2025, lati fi ronu si boya wọn fẹ ẹ lọ tabi duro.
Awọn adari ECOWAS sọ pe igbesẹ ti awọn gbe wa ni ibamu pẹlu abala 91 to wa ninu atunṣe ofin ajọ naa to faaye gba awọn orilẹ-ede lati da duro.
Awọn orilẹ-ede mẹtẹẹta ti ọrọ kan sọ pe awọn gbe igbesẹ lati le mu ki ibaṣepọ to wa laarin awọn l'agbara si ni.
Bakan naa ni wọn ti da ẹgbẹ alajumọṣe ti wọn, ti wọn pe ni AES, silẹ.












