Wo orílẹ̀ èdè Áfíríkà márùn-ún tó ti lé ní àádọ́rin ọdún tí wọ́n gba òmìnira

Àwọn tó ń ṣe ayẹyẹ lásìkò àjọdún òmìnira ní Liberia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ilẹ̀ Áfíríkà jẹ́ ilẹ̀ tó ní ìtàn tó sodo sínú púpọ̀ gan, tó sì ní àwọn orílẹ̀ èdè tó ti pẹ́ gan ní ilẹ̀ ayé.

Láti ìlú kéréje, títí di ìpínlẹ̀ ńlá, ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè yìí ní ìtàn wọn ṣe àfihàn ìfarajìn, okun pati àyípdà ńlá.

Lára àwọn orílẹ̀ èdè tí ọjọ́ orí wọn pọ̀ ní Áfíríkà nìyí:

Liberia

Liberia jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀ èdè tí ọjọ́ orí rẹ̀ pọ̀ jùlọ ní ilẹ̀ Áfíríkà.

Ní ọdún 1822 ni ìtàn sọ pé wọ́n dá orílẹ̀ èdè náà sílẹ̀ láti fi ṣe ìdúnáàdúrá lórí títú àwọn ẹrú sílẹ̀, tí wọ́n sì gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ àwọn amúnisìn ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Keje, ọdún 1847.

Liberia ni orílẹ̀ èdè àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ Áfíríkà tí yóò gba òmìnira lọ́wọ́ àwọn amúnisìn, tí wọ́n sì fi orúkọ olú ìlú rẹ̀, Monrovia sọ ààrẹ ìgbà kan rí nílẹ̀ Amẹ́ríkà, James Monroe.

Òwò ṣíṣe àti kíkò rọ́bà lọ sí ilẹ̀ òkèrè ló gbajúmọ̀ jùlọ ní Liberia.

South Africa

Ní ọdún 1910 ni South Africa gba òmìnira gẹ́gẹ́ bíi Union of South Africa.

Olú ìlú mẹ́ta ni orílẹ̀ èdè South Africa ní: Pretoria, Cape Town àti Bloemfontein.

South Africa kojú ìwà ẹlẹ́yàmẹ̀yà láàárín àwọn aláwọ̀ dúdú àti aláwọ̀ funfun títí di ọdún 1914 lẹ́yìn ìjà n gbara Nelson Mandela.

Onírúurú àṣà àtàwọn ohun àlùmọ́nì lọ́kan-ò-jọ̀kan ni South Africa gbajúmọ̀ fún lóde òní.

Egypt

Ní ọdún 1922 ni Egypt gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gba òmìnira, ètò ìjọba lọ́balọ́ba ni orílẹ̀ èdè ṣàmúlò títí di ọdún 1956.

Egypt, lóòótọ́ wà lára ẹkùn ilẹ̀ Áfíríkà ní ìbáṣepọ̀ tó pọ̀ gidi pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ Áráàbù pàápàá lábẹ́ ìṣèjọba ààrẹ Gamal Abdel Naseer.

Ethiopia

Ethiopia, tí olú ìlú rẹ̀ jẹ́ Addis Ababa jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀ èdè nílẹ̀ Áfíríkà tí àwọn òyìnbó kò músin.

Àmọ́ Italy wọ ilẹ̀ náà láàárín ọdún 1936 sí ọdún 1941 tí wọ́n sì gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ Italy lọ́dún 1941.

Àṣà àti ìṣẹ̀ṣe jẹ́ ohun tó gbilẹ̀ ní Ethiopia.

Libya

Ọdún 1951 ni Libya gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ United Kingdom.

Olú ìlú Libya, Tripoli jẹ́ oríkò ètò ọrọ̀ ajé ní ẹkùn àríwá ilẹ̀ Áfíríkà.

Epo rọ̀bì ni wọ́n mọ Libya sí jùlọ.