Ṣé lóòótọ́ làjọ NAFDAC fòntẹ̀ lu àgbo Lungitox tí kò ní jẹ́ kí sìgá mímu ṣàkóbá fún ara?

Aworan agbo inu igo

Oríṣun àwòrán, AFP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ NAFDAC to n ri si ọrọ ounjẹ ati oogun lilo ni Naijiria ti sọ pe irọ ni iroyin to sọ pe ajọ naa fontẹ lu agbo kan tawọn to n fa siga le maa lo fun ilera wọn.

Ọga agba ajọ NAFDAC, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye, sọ ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi sita loju opo X rẹ pe ajọ naa ti ṣakiyesi fidio kan to lu ori ayelujara pa eyi to sọ pe NAFDAC ti buwọlu oogun kan ti orukọ rẹ n jẹ Lungitox eyi ti ko ni jẹ kawọn to ba n fa siga ni iyọnu niwọn igba ti wọn ba ti lo agbo naa.

Ajọ NAFDAC ti sọ pe irọ nla to jina si ootọ ni iroyin naa, ajọ naa sọ ninu atẹjade to fi sita pe ileeṣẹ to ṣe agbo yii ko forukọ rẹ silẹ pẹlu ajọ NAFDAC.

NAFDAC ni ẹni to ṣe agbo ọhun kan si ajọ naa lati forukọ oogun ọhun silẹ ki NAFDAC si buwọ lu u, amọ, lẹsẹ kẹsẹ naa lawọn ti sọ fun un pe ko sọrọ nibẹ.

''NAFDAC kọ lati fontẹ lu agbo naa nitori nnkan ti ẹni to ṣe e sọ pe siga mimu ko le ṣakoba fun ilera ẹni to n mu niwọn igba to ba ti mu agbo Lungitox.

Ajọ NAFDAC ko ni beṣu bẹgba lati maa daabo bo ilera araalu nipa fifi ontẹ lu ounjẹ ati oogun to koju oṣunwọn.

A kẹyin si awọn eeyan to n gbe iroyin ofege kiri lati le ṣe araalu ni ijamba.

A n fi asikọ yii rọ awọn araalu lati kọ eti ikun si fidio to ti lu ori ayelujara pa yii ati iroyin tawọn kan le maa gbe kiri lori agbo Lungitox,'' NACDAF lo sọ bẹẹ ninu atẹjade to fi sita.

Ajọ naa tun rọ araalu lati kan si NAFDAC lori nọmba ẹrọ ibanisọrọ - 08001623322 tabi lori ikanni www.nafdac.gov.ng lati ta wọn lolobo ti ẹnikẹni ba kẹfin nnkan ti wọn fẹ fi to NAFDAC leti.

NACDAC ni oun ko ni kaarẹ nipa gbigbogun ti ẹnikẹni to ba fẹ ṣakoba fun eto ilera araalu.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post