Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn mọ́kálíìkì tó fẹ́ dìtẹ̀ mọ́ Makinde lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ Oyo

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ile ẹjọ kan niluu Ibadan ti fi okunrin mejila ti wọn n tun ọkọ ṣe si ahamọ ọgba ẹwọn lẹyin ti wọn fẹsun iditẹgbajọba, ibanilorukọ jẹ, ati idunkoko mọ gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde kan wọn.

Ile ẹjo majistreeti to wa ni Iyaganku, ni adajọ Olabisi Ogunkanmi ti pasẹ ki awọn mejila naa wa ni ahamo ijọba titi ti ilẹ ẹjo yoo forikori pẹlu ajọ to n ri si eto idajọ, DPP, ipinlẹ Oyo.

Awọn afurasi mejila naa ni: Abdullahi Alajiga (38), Olaniyi Dauda (71), Alfa Olafisoye (69), Daudu Babalola (52), Akande Musbau (58), Olatinwo Wale (42), Saheed Tijani (41) ati Sunday Awosope (38).

Awọn tom ku ni Idris Olujimi (32), Ayobami Idowu (37), Olajire Sodiq (24) ati Adeniyi Alimi (51).

Ẹsun mẹjọ ọtọtọ ni wọn ka si wọn lẹṣe.

Lara awọn ẹsun naa ni iditẹgbajọba, iditẹ lati gbẹmi eeyan, kikọ atejade to le da wahala sẹlẹ, kikọ iroyin ofege, ipejọ lọna aito ati gbigbe igbesẹ lati da alaafia ilu ru.

Agbẹjọro ọlọpaa, Sikiru Opaleye ṣalaye fun ile ẹjọ pe niṣe ni awọn afurasi naa leri lati rọ Gomina Seyi Makinde loye tipatipa.

O ni awọ afurasi ọhun sọ pe awọn yoo le gomina kuro ni ọọfisi rẹ tí wọn si tun fi ọrọ naa si ori ẹrọ ayelujara.

Adajọ Olabisi Ogunkanmi sun igbejọ lori ẹsun naa siwaju di ọjọ kejilelogun, oṣu Kini, ọdun 2025.

Awọn ẹṣẹ ti wọn ka si awọn afurasi ohun lọ lodi si ofin to risi iwa ọdaran Ipinlẹ Oyo ti abala 41(b),59,70,86,(1)249(d),323,375 ati 516 ti ofin iwa odaran ọdun 2000 ti ipinlẹ Oyo.