Wo ìdí tí àwọn tó ń kọ́ṣẹ́ dókítà ṣe ń pa ara wọn nílùú yìí

Oríṣun àwòrán, AFP
Ẹmi o laarọ, to ba ti bọ, o pari niyẹn. Ṣugbọn ilu kan ree ti awọn ọdọ to n kọṣẹ iṣegun oyinbo lati di dokita ti n gba ẹmi ara wọn.
Lọsẹ to kọja yii, ibanujẹ, ipayinkeke ati ibanujẹ gbalẹ lorilẹede Kenya, lẹyin ti ọmọkunrin kan toun naa n kọ nipa oogun oyinbo pa ara rẹ.
Ọmọkunrin naa, Francis Njuki, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29) ni ẹni karun-un to pa ara rẹ ninu awọn akẹkọọ to gba ẹmi ara wọn naa.
Lati nnkan bii oṣu meji sẹyin ni iku awọn ọdọ to yẹ ko di dokita ati apoogun ni Kenya ti n gogo si i.
Kí ló fà á tí wọ́n fi ń pa ara wọn?
Gẹgẹ bi awọn ẹbi Oloogbe Francis Njuki ṣe ṣalaye fun BBC, wọn ni awọn ijọba ni ko sanwo oṣu to yẹ fun un.
Wọn ni wọn n lo oun ati awọn akẹgbẹ rẹ bii omi ojo nileewosan ijọba ti wọn ti n kọ ẹkọ mọ ẹkọ ni.
Ileewosan ijọba kan to wa ni ilu Thika, ti ko jinna si Nairobi ti i ṣe olu ilu Kenya ni Njika ti n kọṣẹ iṣegun mọ eyi to ti kọ nileewe giga.
Afikun imọ ti awọn akẹkọọ to fẹẹ di dokita maa n ṣe lọsibitu f'ọdun kan, ti a mọ si 'Intenship', lo lọọ ṣe nileewosan naa.
Gẹgẹ bi awọn ẹbi rẹ ṣe wi, oṣu kẹjọ ọdun yii lo bẹrẹ si i ṣiṣẹ lọsibitu naa, o si yẹ ki wọn maa san owo oṣu fun un.
Bakan naa lo yẹ ko lẹtọọ si awọn eto aabo bii ma-dan-dofo ( Insurance), ṣugbọn ko si eyi to tẹ awọn dokita to n kọṣẹ-mọṣẹ naa lọwọ.
Pẹlu ai ri owo gba yii naa, iṣẹ to le ju ni ileewosan naa ni wọn fi n awọn dokita naa ṣe.
Nigba ti wọn fẹhonu han nibi isinku Njuki, ẹni ti ko ri owo oṣu mẹrin gba titi to fi pa ara rẹ yii, awọn ọmọdẹ dokita naa sọ pe aṣeku iṣẹ lawọn n ṣe lọsibitu.
Wọn ni ọpọ iṣẹ lawọn n ṣe fun awọn agba dokita, eyi to maa n mu awọn ni irẹwẹsi ọkan.
Wọn ni awọn ko ri aaye sun to, ko si alaafia ara ati ọkan, ijọba ko si tun sanwo iṣẹ f'awọn.
Eyi ni wọn lo fa a ti awọn to yẹ ko pada di dokita ni Kenya ṣe n pa ara wọn danu, lati ti han pe ijọba ko ṣe ẹtọ rẹ laye awọn.
'Èèyàn márùn-ún ló tún ti gbé ìgbésẹ̀ áti pa ara wọn'
Dokita Davji Atellah, Akọwe fun Kenya Medical Practitioners and Dentists Union (KMPDU), sọ pe ọmọ ẹgbẹ naa marun-un lo tun ti gbe igbesẹ lati gba ẹmi ara wọn ninu ọdun yii.
O ni yatọ si awọn to ti pa ara wọn tẹlẹ.
Dokita Atellah ni awọn ko ri iru nnkan bayii ri.
O ni awọn ko ti i mọ onka awọn ọmọ ẹkọṣẹ iṣegun oyinbo to ti pa ara wọn lọdun yii.
'Dókítà tó pa ara rẹ̀ gbẹ̀yìn kò lè dá owó ilé rẹ̀ san, àtijẹun di ìjàngbọ̀n'

Oríṣun àwòrán, Kiambu County's Department Of Health Services.
''Francis Njuki to pa ara rẹ gbẹyin ninu awọn dokita to n kọṣẹ lọwọ yii ni akọbi awọn obi rẹ.
''O ni awọn ẹtọ to yẹ ko ṣe fun awọn obi naa pẹlu awọn aburo rẹ ati ara rẹ pẹlu, eyi to ni ireti lati ṣe nipasẹ iṣẹ ifimọ-kun-imọ ọlọdun kan to lọọ ṣe lọsibitu naa.
''Ṣugbọn aṣeku iṣẹ, ai le sun, airowo gba ati ibanujẹ to n ri nibi iṣẹ naa ko jẹ ko le ṣe ohunkohun fun awọn eeyan rẹ.
''Oun paapaa ko le da owo ile rẹ san, atijẹun pẹlu di ijangbọn.
''O ti figba kan sọ fun wa pe irẹwẹsi ọkan n da oun laamu, o sọ fun wa pe oun maa n da sọrọ, ohun to si jẹ ko pada gba ẹmi ara rẹ ree, nigab ti ilera ọkan, ọpọlọ rẹ ko pe mọ.''
Tirus Njuki, ẹni to jẹ ẹgbọn fun Oloogbe Francis Njuki lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.
Kí ni àlàyé ìjọba lórí àìsanwó fún àwọn dókítà tó ń fìmọ̀-kún-ìmọ̀ náà?
Ida ọgbọn (30%) ni awọn dokita to n fi imọ-kun-imọ ni awọn ọsibitu ijọba to wa ni Kenya.
Nigba mi-in, wọn le fi wakati mẹrindinlọgbọn(36 hours) ṣiṣẹ, bo tilẹ jẹ pe awọn akọṣẹmọṣẹ dokita maa n wo ohun ti wọn n ṣe.
Ọpọ igba ni ijọba Kenya ati awọn ajọ oṣiṣẹ maa n ja lori ìyà ti wọn fi n jẹ awọn ọmọde dokita yii.
Ohun ti ijọba maa n wi ṣaa ni pe ko si owo ti awọn yoo san fun wọn.
Ijọba ti dabaa lati ge owo oṣu awọn dokita kekere yii si $540 (£430).
Awọn ajọ oṣiṣẹ fẹ ko wa ni $1,600 ti ijọba fi ẹnu ko si ni 2017.
Ṣugbọn Aarẹ William Ruto ti sọ pe ijọba ko le san iru owo bẹẹ, o ni ohun ti awọn ba ni loun yoo fi ṣejọba.
" A ko le maa na owo ti a ko ni,"
Ruto lo sọ bẹẹ ninu oṣu kẹrin ọdun yii.
Ṣugbọn nigba ti wọn daamu ijọba naa ti wọn si n halẹ pe awọn yoo yan iṣẹ lodi, loṣu to kọja yii ni ijọba Kenya fi $7.4m silẹ, pe ki wọn fi sanwo awọn dokita to n kọṣẹ lọwọ naa.
Awọn ti iye wọn ju ẹgbẹrun kan ati igba lọ ( 1, 200).
Àwọn dókítà náà sọ̀rọ̀
"Lẹyin ti a ba lo ọdun mẹfa si meje nileewe lati kọ ẹkọ, a tun maa duro fun ọpọlọpọ oṣu ka too ri ibi ta a ti maa fi imọ-kun-imọ f'ọdun kan.
''Pẹlu gbogbo iṣe aṣekudorogbo yii naa, owo taṣẹrẹ ni ijọba tun lawọn yoo maa san fun wa. Ìyà n jẹ wa pupọ"
Dokita Abdi Adow, to n kọṣẹ lọwọ lọsibitu Mbagathi, Nairobi, lo sọ fun BBC bẹẹ.
Adow wa lara awọn dokita to n ro o pe ṣe kawọn japa ni, tabi kawọn pa iṣẹ dokita ti patapata.
Dokita mi-in to tun ba BBC sọrọ, to ni ka ma darukọ oun, sọ pe:
"Mo ti pinnu lati maa gba ẹmi la, labẹẹ bo ti wu ko ri, ṣugbọn ijọba ṣaa n wa ọna ti wọn yoo fi pa ipinnu mi mọ mi lara, wọn si fẹ ki ẹ̀jẹ́ ti mo jẹ nipa iṣẹ mi yii ba omi lọ."
Àwọn dókítà tó ti kú ní Kenya rèé

Oríṣun àwòrán, KMPDU
1)Dokita Timothy Riungu: Aisan itọ ṣuga n da a laamu, ṣugbọn wọn ko fun un laaye lati gba isinmi lẹnu iṣẹ fun ọdun meji gbako, gẹgẹ bi awọn ẹbi rẹ sẹ sọ.
Ọsibitu awọn ọmọde ni Dokita Riungu ti n ṣiṣẹ, eyi ti wọn pe ni
Kenyatta National Hospital, Nairobi.
Nigba to dele lo ṣubu lulẹ to si ku lẹyin iṣẹ ọjọ naa.
A gbọ pe o pẹ to ti n sọ fun awọn eeyan to wa nitosi lọsibitu, pe o ti rẹ oun.
Ṣugbọn pẹlu ẹ naa lo ṣiṣẹ yipo ọjọ naa, to fi dele to ku.
2) Dokita Desree Moraa Obwogi: O ti ṣiṣẹ fun wakati mẹrinlogoji (36 hours), bi awọn akẹgbẹ rẹ sẹ sọ, bo ti dele lo gba ẹmi ara rẹ loṣu Kẹsan-an ọdun yii.
Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27) ni Dokita Obwogi, ileewosan Gatundu, to wa ni Kiambu lo ti ṣiṣẹ.
Wọn ni oun naa ko le da ẹnu ara rẹ bọ, lo ba ro gbogbo ẹ pọ, o si fi opin si i.
3) Vincent Bosire Nyambunde: Ajọ KMPDU sọ pe oun naa pa ara rẹ ni. Ileewosan Kisii Teaching and Referral Hospital lo ti ṣiṣẹ.
4) Collins Kiprop Kosgei: Ọdun karun-un lo wa nileewe to ti n kọ nipa iṣẹgun oyinbo, iyẹn Yunifasiti ilu Nairobi, ko too pa ara rẹ.
5) Keith Makori: Ẹni ọgbọn ọdun to pa ara rẹ ni Aarin gbungbun Kiambu .
Ni bayii, awọn ọdọmọde dokita yii ti n ke gbajare lori ayelujara, labẹ akori: #PayMedicalInterns.
Wọn ni bii pe oore ti ko ni ọpẹ ninu ni iṣẹ awọn jọ loju ijọba, ati pe dokita meloo ni Kenya yoo padanu ki oju ijọba ibẹ too ja a.
Awọn alaṣẹ ijọba Kenya ko dahun si ibeere ti BBC bi wọn lori awọn ẹsun yii.
Minisita fun eto ilera, Deborah Barasa, nikan lo sọ pe ohun to n ṣẹlẹ n ṣafihan ohun t'oju awọn eeyan n ri ni, paapaa, awọn onimọ ilera.
O ni eto ti wa nilẹ lati yi nnkan pada, pẹlu atilẹyin lati ọdọ ijọba.
Akiyesi:Bi ohunkohun ba kan ọ ninu iroyin yii, wo awọn to le ran an lọwọ loju opo BBC Action Line.













