Mi ò kó ọ̀rọ̀ mi jẹ lórí àwọn 'ọ̀rọ̀ àlùfàǹsá' tí mo sọ nípa Naijiria-Kemi Badenoch

Aworan Kemi Badenoch

Oríṣun àwòrán, EPA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Kemi Badenoch ni oun duro lai yẹsẹ lori gbogbo ọrọ ti oun sọ nipa orilẹede Naijiria eleyi ti ọpọ ti n tọka si gẹgẹ bi ọrọ alufansa.

Lara awọn eeyan to ti nọ ika si aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu orilẹede UK naa ni igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria.

Olori ẹgbẹ oṣelu Conservative, ẹni ti wọn bi ilẹ UK ṣugbọn o gbe fun ọpọ igba lorilẹede Naijiria, ṣapejuwe akoko rẹ lorilẹede gẹgẹ bii eyi ti o kun ibẹru ati iwa ibajẹ.

Ni ọjọ Aje, Igbakeji aarẹ, Kashim Shettima gba Badenoch ni amọran pe ki o yọ orukọ Kemi kuro lara orukọ rẹ ti ko ba ba ni aponle fun orilẹede Naijiria.

Nigba to ti wọn nipa ọrọ Shettima, agbẹnusọ Badenoch ni o duro le ohun gbogbo ohun to sọ pata nipa orilẹede Naijiria.

"Oun ni olori ẹgbẹ oṣelu alatako ati idunu nla lo jẹ fun bi o de n dari ẹgbẹ oṣelu alatako ni orilẹede yii.

"O sọ otitọ. O sọ bi ọrọ ṣe ri. Ko ni pada lori ọrọ rẹ."

Lasiko to n sọrọ lori irinajo lọ oke okun niluu Abuja, Shettima ni inu ijọba Naijiria dun si Badenoch bo ti lẹ jẹ pe o sọrọ odi nipa orilẹede abinibi rẹ.

Ọpọlọpọ atẹwọ lo jẹyọ nigba ti Shettima ni: " Oni lo ni ẹtọ si ọrọ rẹ; o ni ẹtọ lati yọ Kemi kuro ninu orukọ rẹ ṣugbọn eyi ko ni ki ayipada de ba pe o wa lati ọkan ninu orilẹede eeyan dudu to lokiki ju,. To jẹ Naijiria.

Bakan naa ni Shettima fi Badenoch ati olootu ijọba tẹlẹ ni UK, Rishi Sunak we ara wọn, to si ni Sunak ko fi igba kankan gbagbe orisun rẹ to jẹ orilẹede India

Ta ni Kemi Badenoch?

Orukọ abisọ rẹ ni Olukemi Adegoke, wọn ni ilu Wimbledon ni 1980 \augbọn o dagba niluu Eko lorilẹede Naijiria ati Amẹrika nibi ti iya rẹ ti jẹ olukọ.

O pada si ilẹ Uk ni ọmọ ọdun merindinlogun lati gbe pẹlu ọrẹ iya rẹ nitori ọrọ oṣelu ati kudiẹkudiẹ to ba de Naijiria lasiko naa.

O gba orukọ Badenoch lẹyin to fẹ ọkọ rẹ, Hamish Badenoch, ẹni to wa lati orilẹede Scotland.

Kemi ṣapejuwe orilẹede Naijiria gẹgẹ bi ilu ti ko si ofin, to si ranti gbogbo ohun to la kọja lasiko to gbe ni ilu Eko.

Ni ọsẹ to kọja lasiko irinajo rẹ lọ si US, o ni ilu Eko jẹ ilu kan ti ko ti si nkankan to n sisẹ