Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn ọmọlẹ́yìn ààrẹ tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ dìbò yàn ní Ghana tó ń dá rògbòdìyàn sílẹ̀

Aworan ọlọpaa at'awọn eeyan

Oríṣun àwòrán, EPA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn ọlọpaa ti fọwọ ṣinkun ofin mu eeyan to le lọgọrun un ti pupọ ninu wọn jẹ ololufẹ aarẹ ti wọn sẹsẹ dibo yan ni Ghana, Ọgbẹni John Mahama.

Ẹsun titẹ oju ofin mọlẹ ni wọn fi kan awọn eeyan naa.

Awọn eeyan yii ti wọn n wa iṣẹ ni a gbọ pe wọn ti ba ọpọ dukia ijọba jẹ, ti wọn si tun ji oriṣiiriṣii nnkan lọ.

Koda, wọn ni awọn eeyan naa tun ṣe ikọlu s'awọn ọlọpaa ati sọja eyi to jẹ ki ọpọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo farapa.

Awọn eeyan ọhun tun fọwọ ba ọfiisi ajọ eleto idibo leyin ikede esi ibo aarẹ ati ti ile aṣofin eyi ti inu wọn ko dun si b'awọn aṣòfin kan ṣe fidi rẹmi ninu eto idibo naa.

Ọgbẹni Mahama ti bu ẹnu atẹ lu iwa biba nnkan jẹ naa, o si ti ke pe Aarẹ Nana Akufo-Addo at'awọn ẹṣọ eleto aabo lati wa nnkan ṣe si ọrọ naa.

Ẹwẹ, Igbakeji Aarẹ Bawumia to fidirẹmi ninu eto idibo naa ti rọ aarẹ ti ìlú ṣẹṣẹ dibo lati b'awọn ololufẹ rẹ sọrọ.

Ida 56.6% ibo ni Mahama ri nigba ti Bawumia ni ida 41% ninu eto idibo naa.

Ẹgbẹ oṣelu NDC to jẹ ẹgbẹ Mahama tun ni aga 186 ninu ibo ile aṣofin nigba ti ẹgbẹ NPP ni 76.

O wọpọ ni Ghana k'awọn ololufẹ aarẹ ti wọn ba ṣẹṣẹ dibo yan maa ṣe iwọde pe ki ijọba to wa lori oye ko awọn eeyan rẹ kuro nigba ti wọn ko tiẹ tii ṣe iburawọle fun aarẹ tuntun.

Iru rogbodiyan yii ti ṣẹlẹ sẹyin lati ikede aarẹ tuntun ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti kìlọ fun gbogbo awọn to n da rogbodiyan silẹ pe ki wọn lọ ki ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ.

Ni bayii, eeyan mẹfalelọgọrun l'awọn ọlọpaa ti mu to fi mọ awọn ti wọn sọ ina si ọfiisi ajọ eleto idibo to wa lapa ila oorun Ghana.

Ileeṣẹ ọmogun naa ti kìlọ fawọn to n da wahala silẹ pe ki wọn lọ semẹdọ.

Bakan naa l'awọn biṣọọbu ìjọ Aguda ti bu ẹnu ẹtẹ lu iwa jagidijagan t'awọn eeyan naa n hu.

Wọn wa ke si awọn olori ẹgbẹ oṣelu pe ki wọn kilọ fawọn ọmọlẹyin wọn.

Ọjọ keje oṣu Kinni ọdun 2025 ni ayẹyẹ iburawọle fun Mahama yoo waye ni Ghana.