Abiola Fisher, òyìnbó tó fi ìlú òyìnbò sílẹ̀ wá ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ ní Nàìjíríà
O le ni ọgbọn ọdun ti Arabinrin Abiọla Fisher fi gbe ilẹ Gẹẹsi ko to wa si orilẹede Naijiria. Ko si ohun meji to mu ko wa si orilẹede Naijiria ju wi pe o ri pọ anfani ilẹ lati dako ọgbin eyi to si ri gẹgẹ bi anfani nla lati pa owo gọbọi.
Gẹgẹbi ọrọ to ba BBC sọ, abẹwo ikini loun kọkọ wa ṣe ni Naijiria ti oun fi ri bi ilẹ ṣe pọ lọ laisi ẹni to n lo wọn fi ṣe ọgbin lati dẹkun wahala ounjẹ lorilẹede Naijiria.
O ni eyi gan lo mu oun pinnu lati pada wa si orilẹede Naijiria, lati le wa ṣe iṣẹ agbẹ.
"Mi o ti i ṣe iṣẹ agbẹ tẹlẹ ki n to wa si Naijiria, nnkan ti mo pada wa ṣe ni Naijiria ni iṣẹ agbẹ."
- Ẹnu pé mo fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ gba oyè PhD ni mo pàdánù ojú, ta ọpọ̀lọpọ̀ dúkìá mi sí – Ajagunfẹ̀yìntì tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ọ̀mọ̀wé lọ́dún 85
- Àìrí onímọ̀ràn gidi, fífi ojú olóore gúngi, kún ara ohun tó fa ìjákulẹ̀ mi - Olajumoke Oníbúrẹ́dì
- ‘Àìrí àkójọ nídìí iṣẹ́ ìmọ̀ kọ̀mpútà ló sọ wá di Taye-Kehinde alámàlà’
- “Bí a bá mú ajínigbé, tí a sì mú wọn lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan ni wọn yóò tú u sílẹ̀”

Lara awọn oko ti arabinrin Fisher da ni oko ẹyin, oko koko, oko gbaguda, oko agbado, oko ọgẹdẹ ati bẹẹbẹẹ lọ.
O ni ọpọ awọn ilẹ to wa kaakiri Naijiria ti ko si iṣẹ kankan lori wọn lawọn eeyan yoo ti lo o fun iṣẹ agbẹ arota lawọn orilẹede loke okun.
Ọrọ arabinrin Fisher jẹ iyalẹnu pupọ, nitori pe lasiko yii, ọpọ ọdọ lorilẹede Naijiria ni wọ̀n n 'japa' lọ si oke okun pẹlu ironu pe ko si iṣẹ ni Naijiria.
Lori bi awọn agbẹ ṣe n sa fi oko silẹ lọ wa nnkan miran ṣe, arabinrin Fisher sọ pe: Áwọn agbẹ ti wọn n fi oko silẹ, ebi lo maa le wọn pada."





