“Bí a bá mú ajínigbé, tí a sì mú wọn lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan ni wọn yóò tú u sílẹ̀”

Àkọlé fídíò, “Bí a bá mú ajínigbé, tí a sì mú wọn lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá lọ́sẹ̀ kéjì ni wọn yóò tú u sílẹ̀”
“Bí a bá mú ajínigbé, tí a sì mú wọn lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan ni wọn yóò tú u sílẹ̀”

Ni ẹkun gusu ipinlẹ Kwara, ọrọ ijinigbe ti di tọrọfọnkale bayii pẹlu bi o ṣe jẹ wi pe lemọlemọ lawọn ajinigbe n ṣọṣẹ lẹkun naa.

Ninu iwadii BBC, iṣẹlẹ ijinigbe ti mu ki ọpọlpọ awọn ọbalaye atawọn ọtklu ninu ilu o fi aafin ati ile wọn silẹ nitori ibẹru didi ẹran ijẹ fun awọn oniṣẹ ibi yii.

Ninu ọr to ba BBC sọ, Kabiyesi Olomu ti ilu Omuaran, Ọba Abdulraheem Ọladele Adeoti sọ pe ọr naa ti sọ awọn alagbara agbegbe naa di ọdẹ.

Ọba Adeoti ṣalaye pe, ọpọlọpọ igba gan ni awọn ajionigbe naa n kọ lẹta si awọn ọba alaye gan pe wọn n bọ wa ji wọn gbe ti awọn ọba ko si le sun si aafin mọ.

“Ni apejuwe, Ọlọra ti ilu Ọra ni Ifẹlodun, wọn kọ lẹta sii pe awọn yoo ji i gbe...Aimoye ọba ni Ifẹlodun ni ko le sun ile rẹ mọ.”

o ni pẹlu bi ọrọ naa ṣe ri bayii ibẹrubojo ni awọn olugbe ẹkun naa fi n rin bayii koda ni ọsan gangan nitori pe “ojojumọ lo ku ti wọn n gbe eeyan”.

Ọbalaye naa ni tẹlẹtẹlẹri, inu oko lawọn amokunṣika yii ti maa n gbe eniyan, amọ bayii, wọn a maa wọ inu ile wa gbe eniyan.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn n ṣiṣẹ takuntakun lati dẹkun gulegule ijinigbe ni ẹkun gusu ipinlẹ Kwara.