Ẹ jáwọ́ nínú èróńgbà láti yan Iyalode ìpínlẹ̀ Oyo – Olubadan ṣèkìlọ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Apapọ ajọ Olubadan ti kede pe ọna to lodi si ofin ati aṣa ilẹ Ibadan ni yiyan eeyan sipo ilu Ibadan lai si aṣa Olubadan ti ilẹ Ibadan.
Saaju ni awọn ẹgbẹ kan kede pe awọn fẹ fi oye Iyalode ipinlẹ Oyo jẹ.
Apapọ olubadan ti ṣapejuwe igbesẹ naa gẹgẹ bii eyi to lodi sofin, ti ko si si akọsilẹ fun irufẹ ipo naa nibi kibi labẹ ofin.
Lasiko ipade kan ti Olubadan ti ilẹ Ibadan, Oba Owolabi Olakuleyin le waju fun ni ikede naa ti waye.
Ipade oni wakati meji naa ni ọpọ awọn oloye wa ni ijoko lati gbe aṣẹ naa ti jade sita.
“Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni pe awọn ẹgbẹ kan fẹ fi jẹ oye Iyalode ipinlẹ Oyo.
“Oye Iyalode ki se oye kan ti eeyan kan le ma fi sere rara.
“Iru oye yii ni ko tọna, ti a ko si damọ nipinlẹ Oyo ninu iwe ofin ọdun 2000.
“Gbogbo ilu lo ni Iyalode ti wọn, ko ki n se oye kan ti ẹ kan le fun eeyan lai se oun to tọ.
“Se wọn sọ wipe Iyalode Ibadan, Oloye Theresa Laduntan Oyekanmi, ẹni to duro fun ọdun mejileologoji lati jẹ oye naa yoo wa labẹ eeyan ti wọn kan mu loju titi?”
Lara awọn oloye to wa ni ijoko ni Otun Olubadan, Oba Rasidi Adewolu Ladoja, Balogun Ibadan, Ọba Tajudeen Abimbola Ajibola, Otun Balogun, Oba Kolawole Adegbola, Osi Olubadan, Oba Eddy Oyewole Foko, Osi Balogun, Oba Olubunmi Dada Isioye, Ashipa Olubadan, Oba Abiodun Kola-Daisi, Ashipa Balogun, Oba Dauda Abiodun Azeez, Ekerin Olubadan, Oba Hamidu Ajibade ati Ekerin Balogun, Oloye Agba, Akeem Mobolaji Adewoyin.
Bakan na ni Olubadan paṣẹ fun awọn ẹgbẹ naa pe wọn ko gbọdọ fi ẹni kẹni jẹ oye ti wọn yoo waye ni ọjọ Kejidinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2024 ni gbọngan Mapo.
Olubadan koroju si bi awọn kan se n fi ara wọn jẹ oye laarin awọn onisowo.
Oba Olakuleyin wa rọ awọn araalu paapa awọn ọlọja lati ma jẹ ki ọrọ oṣelu se akoba fun iṣẹ ti wọn n ṣe.















