Bíṣọ́ọ̀bù TD Jakes sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn tó kojú ìpèníjà ìlera níbi tó ti ń wàásù

TD Jakes

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gbajugbaja oniwaasu agbaye ni, Biṣọọbu Thomas Dexter Jakes ti ọpọ mọ si TD Jakes ti sọrọ soke fun igba akọkọ lẹyin ti o ni ipenija ilera lasiko to fi n waasu ni ile ijọsin rẹ lọjọ Aiku to kọja.

Oniwaasu n waasu lọwọ ni ile ijọsin Potters House ni ilu Dallas lorilẹede Amẹrika lo ṣa dede bẹrẹ si ni gbọn ti ẹrọ agbagbe ọwọ rẹ si bọ silẹ.

Ninu fidio kan to kaakiri ninu eyi ti wọn ti ṣe afihan ohun to ṣẹlẹ sii, iranṣẹ Ọlọrun naa ko lee gbe ọwọ lasiko iṣẹlẹ naa eyi ti awọn ẹbi ati ijọ rẹ tka si gẹgẹ bi “iṣẹlẹ ilera.”

Lati igba ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ lawọn eeyan kaakiri agbaye ti n gbadura fun ipadabọsipo ilera ojiṣẹ ọlọrun naa.

Aworan TD Jakes

Oríṣun àwòrán, screenshot

Lẹyin ọjọ mẹrin ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, Biọọbu TD Jakes ti gbe fidio kan sita loju opo ayelujara rẹ nibẹ lo si ti n dupẹ pupọpupọ lọwọ gbogbo agbaye fun adura wọn.

Ninu fidio naa ti ko ju bi iṣẹju kan lọ, Biṣọbu Jakes joko sori aga ti wọn maa fi n gbe awọn alaarẹ, awọn dokita si yii ka.

O ni”Mo dupẹ pupọ lọwọ mutumuwa to fi aduran ranṣẹ si mi, fun gbogbo iduro ṣinṣin yin mo dupẹ.”

Biṣọọbu TD Jakes tun tẹsiwaju ninu ọr rẹ naa pe, “mi o bẹru lati ku, mi o fẹda ọgbẹ si ọkan awọn ọmọ mi atawọn to nifẹ mi, ijọ mi ṣi nilo mi.

Ninu awọn ọrọ akọle ti wọn kọ si abẹ fidio naa, wọn fi kun un pe, “Mo dupẹ pe mi o ni aisan rọparọsẹ, nnkan i ba yiwọ ka ni kii ṣe Ọlọrun to da si ọrọ naa.”

O ni lọwọ yii, oun n tẹpa mọ bi oun yoo ṣe tete bọ sipo ilera to peye.

Àwọn ẹbí Bíṣọ́ọ̀bù T. D Jakes sọ̀rọ̀ lórí ìlera rẹ̀ lẹ́yìn tó ní ìpèníjà lásìkò ìwàásù
T.D. Jakes Ministries

Oríṣun àwòrán, T.D. Jakes Ministries

Ara Ògbóǹtarìgì oníwàásù, ẹni tó tún máa ń sọ̀rọ̀ ìṣítí nílẹ̀ Amẹ́ríkà, Bíṣọ́ọ̀bù T. D Jakes ti ń bọ̀ sípò padà lẹ́yìn tó ní ìpèníjà ìlera lọ́jọ́ Àìkú.

Nínú fídíò kan tó gba orí ayélujára kan lọ́jọ́ Àìkú ṣàfihàn bí olùdásílẹ̀ ìjọ Potters House Church náà ṣe ní ìpèníjà lásìkò tó fẹ́ parí ìwàásù rẹ̀.

Nínú fídíò náà, Bíṣọ́ọ̀bù náà ń sọ fún àwọn ọmọ ìjọ pé ṣé wọ́n ti ṣàbẹ̀wò sí ilé ìwòsàn rí láti lọ ṣe kóríyá fún aláàárẹ̀ àmọ́ tó jẹ́ pé àwọn ni wọ́n gba ìṣítí bọ̀?

Ó fi kun nínú ọ̀rọ̀ náà pé èèyàn lè rò pé òun ń fún èèyàn ní nǹkan tó sì jẹ́ pé onítọ̀hún ló ń gba èyí tó pọ̀ jù dípò.

Àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ sì ń pàtẹ́wó bó ṣe ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí.

Lẹ́yìn tó sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí tán ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ̀n lórí àga tó fi jókòó níwájú pẹpẹ.

Bí ó ṣe ń gbọ̀n ni gbohùngbohùn tó fi ń sọ̀rọ̀ jábọ́ lọ́wọ́ rẹ̀, táwọn pásítọ̀ àti àgbà ìjọ náà mìíràn sì sáré síi.

Láti ìgbà tí fídíò náà ti gba orí ayélujára ni àwọn ènìyàn káàkiri ti ń ṣe àfihàn ara wọn níbi tí wọ́n ti ń gbàdúrà fún Bíṣọ́ọ̀bù náà.

CCCC

Àtẹ̀jáde náà di kun pé àwọn dúpẹ́ fún ìfẹ́, àdúrà àti àtìlẹyìn táwọn èèyàn ṣe fún olórí ìjọ àwọn.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ wákàtí tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ni àwọn ọmọ Bíṣọ́ọ̀bù náà, Sarah Jakes àti ọkọ rẹ̀, Toure Roberts gbé fídíò kan jáde láti sọ̀rọ̀ lórí ìlera T. D Jakes.

Sarah Jakes àti ọkọ rẹ̀ ní ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Àìkú jẹ́ fáwọn àti pé àwọn fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ara bàbá àwọn ti ń balẹ̀.

Sarah fi kun pé àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ti ń tọ́jú bàbá òun àti pé àwọn ti ń gbìyànjú láti ri pé ó ń dìde jókòó.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Ta ni Bíṣọ́ọ̀bù T. D Jakes?

Bíṣọ́ọ̀bù T. D Jakes

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Yàtọ̀ sí pé Bíṣọ́ọ̀bù Thomas Dexter Jakes jẹ́ oníwàásù, oníṣòwò tó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwò ni.

Iléeṣẹ́ rẹ̀, TD Jakes enterprises ní àwọn ẹ̀ka káàkiri níbi tí wọ́n ti máa ń ṣe orin, ṣe ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn nǹkan míì.

Bákan náà ló tún ní ilé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀sìn, èyí tí wọ́n ti máa ń kọ́ àwọn olórí ẹ̀sìn nímọ̀ lórí ayélujára.

Lójú òpó ìtàkùn àgbáyé ilé ìjọsìn náà tó wà lórí ayélujára, ọdún 1996 ni wọ́n ní Bíṣọ́ọ̀bù dá ìjọ náà sílẹ̀.

Ó wà lára àwọn ilé ìjọsìn tó tóbi púpọ̀, tó sì lórúkọ ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà pẹ̀lú ọmọ ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún ọgbọ̀n.

Ọmọ rẹ̀, Sarah Jakes àti ọkọ rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn pásítọ̀ ìjọ náà.

Ní ọdún 1981 ni Bíṣọ́ọ̀bù gbé Serita Ann Jamison ní ìyàwó.

Ọmọ márùn-ún ni àwọn méjèèjì bí fúnra wọn, tí wọ́n sì ti ní ọ̀pọ̀ ọmọọmọ.