Kí ló lé fà á tí obìnrin yìí fi gbé ọmọ rẹ̀ pamọ́ sí abẹ́ tábìlì fún ọdún mẹ́ta?

Oríṣun àwòrán, CPS
Obinrin kan to gbe ọmọ obinrin rẹ pamọ sinu ibi to n ko iwe si fun ọdun mẹta ni ileẹjọ ti ran lọ si ẹwọn ọdun meje ati oṣu mẹfa.
Awọn olupẹjọ ṣawari ọdọmọbinrin kan, ẹni ti ko ri oorun tabi gba atẹgun lati igba ti wọn ti bi si aye nigba ti alejo kan lọ si ile wọn to si gbọ igbe ọmọ naa.
Lati le daabo bo ọmọ naa, a ko ni darukọ orukọ rẹ ati ti mọlẹbi rẹ.
Awọn alaṣẹ ti ni ki iya ọmọ naa lọ rọọkun ni ọgba ẹwọn lẹyin to gba pe oun jẹbi ẹsun naa nile ẹjọ Chester Crown.
Ninu idajọ rẹ, adajọ Steven Everett ni obinrin naa ko jẹ ki ọmọ naa ni anfani si ifẹ, itọju to peye ati lati le ba awọn eeyan yooku sọrọ.
“Ọmọ naa ti n pada bọ sipo lẹyin to bọ lọwọ inira ọhun.”

Oríṣun àwòrán, PA Media
Ile ẹjọ gbọ pe iya ọmọ naa n gbe e pamọ nitori awọn mọlẹbi rẹ ni, abẹ bẹẹdi lo n gbe e si lati ma ba a jẹ ki ololufẹ rẹ ikọkọ mọ.
Rachel Worthington, agbẹjọro lati Crown Prosecutive Service ṣalaye pe, ọmọ naa ko dahun si orukọ rẹ nigba ti wọn ri i ati pe wọn fi silẹ fun ọpọ igba lati wa ounjẹ fun ara rẹ.
‘Abẹrẹ ni wọn fi n fun ni miliki’
Ile ẹjọ gbọ pe ọmọ naa ko jẹ ounjẹ to se ara loore, to fi jẹ pe o dabi ọmọ oṣu meje, to si jẹ pe ọmọ ọdun mẹta ni.
Ati pe abẹrẹ ni wọn fi n fun ni miliki mu.
Ọpọ aisan lo n se ọmọ naa ti iya ko si gbiyanju lati wa itọju fun un.
Ọdun 2020 ni wọn bi ọmọ naa ti wọn si ṣawari rẹ ni ọdun 2023 nigba ti alejo kan wọle wọn, to si ṣawari ọmọ na lori ibusun.
Alejo naa ransẹ pe ijọba, ti wọn si wa gbe ọmọ naa.
Oṣiṣẹ ijọba ni, “Mo wo iya rẹ, mo bere pe, se ibi ti ẹ n gbe ọmọ yii si? Iya naa dahun pe idaniloju pe bẹẹni, ibẹ ni oun n gbe si.

Oríṣun àwòrán, CPS
‘Ko ki n se ara mọlẹbi’
Obinrin ọhun ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa ni oun ko mọ pe oun loyun, ti ẹru si n ba oun lasiko to bimọ.
O ni oun ko gbe ọmọ rẹ ninu ile iwe igbewe si ni gbogbo igba, ati pe oun ko ki n ti ibẹ.
O sọ fun awọn ọlọpaa pe ọmọ naa ko ki n se ara mọlẹbi.
Pẹlu omije, obinrin naa ṣalaye bi ọpọ awọn ọmọ yooku ko se ba oun gbe mọ, paapa awọn ọmọ to tọ.
Adajọ Everett ni ohun ti obinrin naa se lo jẹ ohun iyalẹnu.
“Lati ọdun mẹindinlaadọta ti mo sisẹ, n ko ri iru eyi ri.”








