Auxiliary, olórí ẹgbẹ́ awakọ̀ èrò tẹ́lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Oyo fojú ba ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ìjínigbé, ìpànìyàn

Alaga tẹlẹ fun ẹgbẹ awọn awakọ nipinlẹ Oyo, Mukaila Lamidi, ẹni ti ọpọ mọ si Auxiliary ti sọ fun ileẹjọ pe oun ko jẹbi gbogbo ẹsun mẹtadinlogun ti wọn ka si lẹsẹ.
Eṣun ijinigbe, iṣekupani ati idigunjale wa lara ẹsun ti wọn fi kan Auxillary pe wọn furasi pe o lọwọ ninu wọn.
Awọn ẹsun wọnyi ni ofin ko fi aye gba, ti ijiya si wa fun labẹ ofin orilẹede Naijiria.
Auxiliary farahan niwaju Onidajọ Bayo Taiwo ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo to wa ni Ring Road niluu Ibadan.
Saaju ni ẹjọ naa wa niwaju Onidajọ O. A. Adetujoye ko to di pe wọn gbe lọ siwaju Onidajọ Taiwo lẹyin ti agbẹjọro Auxililary, Olalekan Ojo, SAN kọ lati fi aye gba Onidajọ Adetujoye lati hnọ ẹsun meji papọ.
Eyi lo fa ti wọn da ẹjọ naa pada si ẹka to n risi idajọ.
Lẹyin ti Auxililary sọ fun ile ẹjọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn ka si lọrun, agbẹjọro fun ijọba pe awọn ẹlẹri sita lati wa sọ ohun ti oju wọn ri.
Ẹlẹrii meji, Fatia Isiaka ati Ademola Johnson jade sita lati sọ ohun ti oju wọn ri.
Lẹyin ọpọ atotonu, ileẹjọ sun igbẹjọ naa lọ si ọjọ karun un oṣu kejila ọdun 2025.
Ki lo waye laaarin Seyi Makinde ati Auxiliary?
Lẹyin gbogbo pọpọsinsin ayẹyẹ iburawọle fun saa keji gomina Seyi Makinde ni papa iṣire Ọbafẹmi Awolọwọ, ti ọpọ ṣi mọ si Liberty Stadium nilu Ibadan lọjọ Aje ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2023 ni awọn aṣoju ẹgbẹ awakọ ero mejeeji, iyẹn NURTW ati RTEAN ba ni ki awọn sin Gomina de ile rẹ to n bẹ ni agbegbe Ikọlaba lati kii ku oriire. Ni Ibẹ ni a gbọ wi pe Auxiliary ati awọn eeyan rẹ ti pade wọn ti ọrọ si di iṣu ata yan-an-yan-an.
Ọrọ yii lo bi Gomina Ṣeyi Makinde ninu ti o si pa aṣẹ wi pe ki wọn gba iṣẹ lọwọ Auxiliary ati awọn igbimọ alabaṣiṣẹpọ rẹ.
Lati igba ti ijọba si ti ṣe ikede yii ni ariwo ti n sọ lọtun losi lori iwa ipa ti awọn janduku kan ti ọpọ fura si pe wọn jẹ ara ọmọ ẹgbẹ awakọ ero to wa labẹ Auxiliary n hu lawọn agbegbe bii Olodo, Iwo Road ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ni gbogbo awọn adugbo yii ni awọn eeyan ti n ke gbajare wi pe awọn n gbọ iro ibọn lakọ-lakọ.
Ninu oṣu karun ọdun 2019 ni Makinde fi ofin de ẹgbẹ awakọ NURTW ati RTEAN nitori wahala ti wọn fa lori ipo adari, lẹyin eyii si ni o ṣe idasilẹ ajọ PMS to n mojuto igbokegbodo ọkọ eleyii ti Auxiliary ati igbimọ rẹ n ṣe akoso fun.Ki lo ti sẹlẹ saaju?
Lọdun to kọja ni Ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti ṣe afihan awọn ọmọlẹyin Auxiliary ti kele ofin gbe ninu ile ti wọn n gbe pẹlu ọga wọn.
Ọpọlọpọ ibọn ati ọta to fi mọ awọn nnkan ihamọra mii ni awọn agbofinro ba lọwọ wọn.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa fi lede loju opo Twitter ni wọn ti ni awọn ba igbiyanju awọn ti wọn mu naa lati da alaafia ipinlẹ Oyo ru.
Wọn ni o kere tan eniyan mejidinlọgọrin ni ọwọ awọn tẹ pẹlu ọpọlọpọ ibọn, onde ati owo iyebiye.












