Ìdí tí mo ṣe fún ọkọ mi ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tí a ṣe ìgbéyàwó - Wuraola

Aworan ọwọ ọkọ ati aya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Yoruba bọ wọn ni ai rin jinna lai ri abuke ọkẹrẹ, obinrin kan to n jẹ Wuraola Surajudeen lo ti sọ fun ile ẹjọ agbegbe niluu Ilorin l’Ọjọru wi pe oun fẹ kọ ọkọ oun silẹ lẹyin ọsẹ meji tawọn ṣe igbeyawo.

Wuraola sọ fun ile ẹjọ naa pe oun ṣetan lati kọ Surajudeed Iya-Onitasi silẹ tori kosi ifẹ rẹ lọkan oun mọ.

Arabinrin naa sọ fun ile ẹjọ wi pe oun ti ṣe igbeyawo pẹlu ẹnikan ri tẹlẹ ki oun to fẹ Iya-Onitasi.

Wuraola ni oun kuro ninu igbeyawo toun ṣe tẹlẹ tori wahala lati ọdọ iya ọkọ oun.

‘’Ọkọ ti mo fẹ tẹlẹ di alakatakiti ẹsin lẹyin igbeyawo wa eyi tinu awọn obi mi ko dun si.

Lẹyin naa ni mo ri ọkọ ti mo ṣẹṣẹ fẹ, ti a si jọ bẹrẹ irinajo naa.

Amọ, kete ti a ṣe igbeyawo tan ni mo ri wi pe mo kan ṣadeedee korira rẹ,’’ Wuraola lo sọ fun ile ẹjọ bẹẹ.

Ṣaaju ni ọkọ arabinrin naa ti sọ fun ile ẹjọ wi pe ṣadeedee ni iyawo oun kuro nile lai sọ foun ti o si sọ pe igbeyawo awọn ti su oun.

Ọkunrin naa ni oun gbiyanju lati ri pe igbeyawo naa ko tuka, amọ, o ni Wuraola fi aake kọri pe lilọ loun yoo lọ.

Iya-Onitasi sọ pe idi niyi toun ṣe fi i silẹ.

Lẹyin naa ni aarẹ ile ẹjọ ọhun, Hammed Ajumonbi, paṣẹ pe ki olupẹjọ da owo ori ti ọkunrin naa san lori rẹ pada.

Ọgbẹni Ajumonbi wa sun igbẹjọ siwaju si ọjọ kẹrin oṣu Kejila