Wo ìye ọjọ́ tí Yahaya Bello yóò lò ní àhámọ́ EFCC

Ilé ẹjọ́ giga to wa ni Maitama nílùú Abùja ti ní kí gomina ana fun ipinle Kogi Yahaya Bello si wa ni ajọ EFCC di ọjọ́ kẹwàá osu kejìlá ọdún yii nígbà tí igbẹjọ yóò tún máa wáyé lóru ẹsun ìwà ibajẹ tí wọn fi kan an.
Adajọ Maryanne Anenih lọ sọ bẹẹ lasiko ti eto igbẹjọ náà ń waye nílé ẹjọ́ giga lónìí yìí.
Ninu oṣù kẹrin ọdún yii ni ajọ EFCC sọ pe awọn ń wa gomina ana Yahaya Bello , láti fara hàn ní ajọ wọn.
Ṣùgbọ́n iroyin sọ pe ní ana to jẹ́ ọjọ́ ketadinlọgbọn oṣù kọkànlá ọdún yii ni gomina ana, Yahaya Bello wa fi ara silẹ ni ajọ EFCC sugbọn ti agbanẹnusọr fún ajọ EFCC,Dele Oyewale ni irọ to jìnnà sí ootọ ni ọrọ ọhun pe awọn ni wọn lọ mú gomina Yahaya Bello. Láti ana sì ni Yahaya Bello tí wa ni ahamọ ajọ EFCC kò to di pe wọn gbee wa sì ilé ẹjọ́ gíga.
Ẹ̀sùn ìwà ibajẹ owó to lè ni ọgọ́rùn-ún bilionu naira ni wọn fi kan gomina ana náà,.

Komina ipinlẹ Kogi tẹlẹ, Yahaya Bello ti jẹwọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria, EFCC n fi kan an pe o ṣe owo to to ọgọrin biliọnu Naira baṣubaṣu.
Nigba ti igbẹjọ bẹrẹ, ọkan lara awọn oṣiṣẹ ile ẹjọ naa ka ẹsun mẹrẹrindinlogun ti wọn fi kan an lẹsẹẹsẹ si eti Bello atawọn meji miran ti wọn fi ẹsun kan pẹlu rẹ - Shuaibu Oricha ati Abdusami Hudu, gbogbo wọn lo si dahun pe awọn ko jẹbi.
Amofin agba, Joseph Daudu SAN to lewaju ikọ agbẹjọro fun Yahaya Bello, ti amofin agba, Kẹmi Pinhẹro, SAN ni o n ṣoju fun ajọ EFCC

Gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ, Yahaya Bello ti wa ni ile ẹjọ bayii.
Akọroyin BBC ni awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC gbe Yahaya Bello wọ ile ẹjọ giga apapọ to wa ni agbegbe Maitama nilu Abuja lowurọ jọru lati bẹrẹ igbẹjọ ẹsun ajẹbanu ti aj naa n fi kan an.
O ti to oṣu diẹ bayii ti Yahaya ti n sa bọrọ m ajọ EFCC lẹyin lẹyin ti ajọ naa kede pe wọn n wa a fun awọn aṣemaṣe kan to rọ mọ owo ilu lasiko to wa ni ipo gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Kogi.

Yahaya Bello yóò fojú ba ilé ẹjọ́ lónìí lẹ́yìn tó jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lé àjọ EFCC lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, X/Yahaya Bello
Gomina ana nipinlẹ Kogi, Yahaya Bello ti gba lati fara kalẹ fun ajọ to n gbe ogun ti iwa ibajẹ EFCC lori ẹsun sise owo ilu mọkumọku.
Yahaya Bello lọ si ọfisi EFCC lanaa ọjọ Isẹgun pẹlu awọn agbẹjọro.
Iroyin to tun tẹ wa lọwọ ni pe Bello wa ni ọfisi EFCC mọjumọ.
Eyi waye lẹyin idajọ ile ẹjọ to tako ipe awọn gomina kan pe ki wọn fofin de ajọ EFCC lati ma wadi awọn gomina.
Bakan naa lo ṣeeṣe ki Yahaya Bello foju ba ileẹjọ lonii.
Saaju ni agbẹnusọ EFCC, Dele Oyewale fidi rẹ mulẹ pe Bello yoo foju ba ile ẹjọ giga to wa niluu Abuja ṣugbọn ko sọ ọjọ ti yoo waye.
Nibi igbẹjọ to wayẹ kẹyin, Adajọ Anenih sun igbẹjọ si ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2024.
Ki lo sẹlẹ saaju?
Níṣe ni ọrọ bẹyin yọ lori abẹwo tí wọn ni gomina tẹlẹ ri ni ipínlẹ Kogi, Yahaya Bello ṣe si ileeṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Nàìjìríà (EFCC).
Agbẹnusọ Yahaya Bello, Ohiare Michael sọ síta pe ọga oun ti lọ si ọ́fíìsì EFCC lati lọ jẹ ìpe tí wan ti n pe e láti bíi oṣu meloo kan sẹyìn.
Amọ EFCC fi atẹjade sita lori ìkannì ayelujara X wọn pe Yahaya Bello ko si ní akata awọn ati pe awọn ṣi n wa gẹgẹ bi awọn ti fi lede ṣaaju fun ẹsun ṣíṣe owo to le ni ọgọrin bilíọnu naira kumọkumọ.
Atẹjade ti agbẹnusọ Yahaya Bello, Ohiare Michael fi sita ni owurọ ọjọru lo ti sọ pe ọga oun ti lọ si olu ile iṣẹ EFCC to wa ní ìlu Abuja lati jẹ ìpe tí wọn fi ranṣẹ lati oṣu díẹ sẹyìn.
Michael sọ ninu atẹjade naa pe lẹyìn tí ọga aun ti kan sawọn agbẹjọro rẹ atawọn tí wọn jẹ eekan fún-un lo pinnu lati yọju si EFCC.
Bakan naa ni Ile-ẹjọ kotẹmilọrun to wa niluu Abuja, olu-ilẹ Naijiria ti paṣẹ fun gomina ana nipinlẹ Kogi, Yahaya Bello lati jọwọ ara rẹ fun igbẹjọ rẹ to wa niwaju ohun.
Bakan naa ni ile-ẹjọ kotẹmilọrun tun da Yahaya Bello lọwọ kọ lati ma ṣe gbe igbesẹ miran ti yoo tako fifoju ba ile-ẹjọ titi digba ti yoo fi yọju.
Onidajọ Ken Amadi lo gbe idajọ naa kalẹ lọjọ Iṣẹgun to kọja lasiko to n tẹwọ gba ẹjọ kotẹmilọrun ti ajo to n gbogun iwa ajẹbanu ati jibiti nilẹ Naijiria, EFCC gbe wa lati tako idajọ Onidajọ Isah Abdullahi Jamil ti ile-ẹjọ giga ipinlẹ Kogi nipa ẹjọ ti Bello pe ninu oṣu keji, ọdun 2024 lori ẹtọ rẹ.















