Ìjọba ṣàlàyé ìdí tó fi gbé pápákọ̀ òfurufú ìpínlẹ̀ Osun kúrò ní Ido-Osun lọ sí Ede

Oríṣun àwòrán, Senator Ademola Adeleke/X
Igbakeji gomina ipinlẹ Osun, Kola Adewusi, ti ṣalaye idi ti ijọba fi pinnu lati gbe papakọ ofurufu ipinlẹ naa ti ijọba fẹ kọ si Ido-Osun tẹlẹ lọ si ilu Ede.
Igbakeji gomina Osun fidi ọrọ yii mulẹ lori eto kan lori redio eyi to kopa ninu rẹ niluu Osogbo l’Ọjọru.
Gẹgẹ bi o ṣe ṣalaye lori eto naa, ijọba pinnu lati gbe papakọ ofurufu ọhun lọ silu Ede tori ko si ilẹ to le to fun kikọ papakọ ofurufu nla naa ni Ido-Osun nibi ti wọn fẹ kọ ọ si tẹlẹ.
Ti ẹ o ba gbagbe, lana ọjọ Iṣẹgun lawọn eeyan Ido-Osun ṣe ifẹhonuhan lori igbesẹ ijọba lati gbe papakọ ofurufu ọhun kuro lagbegbe wọn.
Awọn eeyan ilu naa sọ lasiko iwọde ti wọn ṣe wi pe igbesẹ idẹyẹsini ni ijọba gbe ati pe ko si otitọ ati ododo ninu igbesẹ naa.
Nigba ti wọn n fi ẹhonu wọn han, awọn ọtọkulu lati Ido-Osun bii Eesa Ido-Osun, Oloye Oyewale Basiru Oyeleke ati aarẹ ẹgbẹ idagbasoke Ido-Osun, Alagba T.A. Adeleye to fi mọ Ọgbẹni Abiodun Awolola lo ke pe ijọba lati yi igbesẹ rẹ pada.
'Ọpọ dukia ni yoo ṣofo ti ijọba ba tẹsiwaju lati kọ papakọ ofurufu naa si Ido-Osun'
Igbakeji gomina ipinlẹ Osun sọ pe ọpọ dukia ni yoo ṣofo ti ijọba ba tẹsiwaju lati kọ papakọ ofurufu naa si Ido-Osun.
Bakan naa lo ṣalaye pe akanṣẹ iṣẹ naa yoo tun na ijọba lowo to pọju ni Ido-Osun tori gbogbo ti papakọ ofurufu naa ba jẹ dukia wọn ni ijọba gbọdọ fun lowo gba mabinu.
‘’Ti a ba wo o daadaa, ile ẹkọ ọmogun ofurufu Naijiria n bẹ nibẹ, amọ, ko le rọrun fun ijọba lati kọ papakọ ofurufu sibẹ.
Ti a ba fi le gbe papakọ ofurufu yii si Ido-Osun, ko ni saye nibẹ fun ọpọlọpọ baalu ti papakọ ofurufu naa ba di nla tan lọjọ iwaju.
A ni lati wo ọjọ iwaju, koto nla kan ti yoo jẹ owo gọbọi lati di tun wa ni Ido-Osun.
Bakan naa, ko si ilẹ fun kilomita mẹta ati abọ ti baalu maa fi n sare ko to gbera ni Ido-Osun, nitori naa, a ni lati wa ibi ti ilẹ ti tẹju daadaa.
A o ni iṣoro kankan pẹlu awọn eeyan Ido-Osun, koda, ọrẹ ijọba ni ọba ilu naa.
Ti awọn to tako gbigbe papakọ ofurufu naa lọ Ede ba ri ilẹ ti yoo to fun akanṣẹ iṣẹ yii niluu Osogbo, ki wọn fi han wa.
Gomina Ademola Adeleke ṣetan lati kọ papakọ ofurufu naa sibẹ tori ki i ṣe oju ṣaju,’’ Ọgbẹni Adewusi ṣalaye.















