'Lẹ́yìn ìjà tó wáyé láàrín olùkọ́ àtàwọn olùgbé Ogbomoso, ọ̀sẹ̀ kan ní ilé ẹ̀kọ́ Are-ago yóò fi wà ní títìpa'

Oríṣun àwòrán, Ogbomoso Insight
Ẹgbẹ olukọ nipinlẹ Oyo NUT, ni ẹka to n ri si eto ẹkọ nipinlẹ Oyo lo ti ile ẹkọ Areago Community High School to wa ni apa ariwa Ogbomos pa.
NUT ni ile ẹkọ naa yoo wa ni titi pa fun ọsẹ kan titi awọn olukọ yoo fi ri idaniloju pe aabo to pe ye wa fun ẹmi wọn.
Nigba to n ba ileeṣẹ BBC Yoruba sọrọ, alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ tẹlẹ nipinlẹ Oyo, Adedoyin Samson Tojuade ni ko ki n se pe awọn olukọ ko yọju si ibi iṣẹ wọn ṣugbọn ọfisi Tescom to wa niluu Ogbomoso ni wọn wa.
Tojuade ni awọn olukọ se koko ati pe lọwọ e lewu pe ki wọn lọ si ile ẹkọ lai ri idaniloju.
“Ni ọsẹ to kọja, mẹrin ninu olukọ wa ni wọn ti mọle ni agọ ọlọpaa, nigba to ya, awọn olukọ to wa ni ile ẹkọ ni awọn janduku kan lọ se ikọlu si.
Á ri pe ohun to kan bayii ni lati kuro ni ile ẹkọ naa titi ọrọ naa yoo fi ni iyanju.”
Tojuade ni ẹgbẹ oṣiṣẹ ti gbe ẹjọ naa lọ ba ijọba ipinlẹ Oyo, to si jẹ pe ẹka ijọba to n risi eto ẹkọ lo ti ile ẹkọ naa pa fun ọsẹ kan.
“Mo n sọ fun bayii pe wọn ti pe ipade laarin awọn olukọ, olugbe agbegbe, awọn obi ati awọn ti ọrọ lori ọna lati wa ojutu si iṣẹlẹ naa.
“Mo lero pe wọn yoo yanju ọrọ naa lonii, ti awọn ara agbegbe naa yoo si fi da wa loju pe ohunkohun ko ni sẹlẹ si awọn akẹgbẹ wa.”
Lẹ́yìn ìjà tó wáyé láàárín olùkọ́ àti olùgbé Ogbomoso, títìpa ni ilé ẹ̀kọ́ girama Are-ago wà

Oríṣun àwòrán, Ogbomoso Insight
Diẹ ninu awọn olukọ ati akẹkọọ ile ẹkọ girama Areago Community High to wa ni ijọba ibilẹ ariwa Ogbomoso lo wa si ile ẹkọ naa l'ọjọ Aje.
Eyi ko sẹyin ohun to waye ni ọsẹ to kọja laarin awọn Olukọ ati olugbe agbegbe naa, ti eeyanh mẹrin ninu awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ naa si dero ahamọ.
Ninu awọran to tẹ wa lọwọ lọjọ Aje, awọn akẹkọọ diẹ lo wa ni ayika ile ẹkọ naa, ti ko si si olukọ tabi ọga ile ẹkọ ni ile ẹkọ ọhun.
Ninu iroyin ti iwe iroyin abẹle kan, Ogbomoso Insight, gbe jade lẹyin abẹwo si ile ẹkọ naa, ọpọ akẹkọọ ni wọn ko si ni yara ikẹkọọ wọn, ti ọpọ miran si n gba bọọlu lori paapa ile ẹkọ naa.
Akẹkọọ to ba akọroyin sọrọ ni, “A ko ri awọn olukọ wa lonii. A ko mọ idi ṣugbọn mo mọ pe o ni nnkan se pẹlu ohun to waye ni ọsẹ to kọja”
Saaju ni ẹgbẹ awọn olukọ NUT ti ni olukọ ile Areago kankan ko ni pada si ile ẹkọ naa titi idaniloju pe aabo yoo wa fun ẹmi wọn.
Alaga NUT nijọba ibilẹ ariwa Ogbomoso, Tunde Oladapo lo kede ọrọ naa fun awọn akọroyin.
Oladapo ni gbogbo olukọ yoo peju si ileeṣẹ TESCOM lọjọ Aje, ọjọ kẹdọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2024.
“O ya mi lẹnu pe awọn olugbe agbegbe naa lu awọn olukọ lasiko ti a wa ni ileeṣẹ ọlọpaa lati gba beeli awọn eeyan to wa ni ahamọ.
“A ko le fi ẹmi awọn eeyan wa wewu."
Ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàárín olùkọ́ àtàwọn olùgbé Ogbomoso, igba kejì ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́, olùkọ́ méjì dèrò àhàmọ́
Oṣiṣẹ ile ẹkọ Areago Community High School niluu Ogbomoso lo ti dero ahamọ lẹyin ti rogbodiyan bẹ silẹ laarin awọn akẹkọọ ati awọn olugbe agbegbe naa.
Igbakeji ọga ile ẹkọ, Ọgbẹni Ajayi; olukọ meji, Ọgbẹni Oladeji ati Ọgbẹni Adekunle pẹlu ọdẹ to n sọ ile ẹkọ naa si ti dero ahamọ.
Ohun ti a ri gbọ nipe wọn ti awọn eeyan ti mu si ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni agbegbe Owode niluu Ogbomoso.
Ohun ti a ri gbọ ni pe ija naa bẹ silẹ lọjọbọ ọsẹ to kọja nigba ti awọn akẹkọọ ile ẹkọ n pariwo le awọn obinrin kan ti wọn jẹ olugbe agbegbe naa ti wọn fẹ gba inu ile ẹkọ naa pẹlu ọkada.
Awọn olugbẹ naa ni wọn ko jẹ ki wọn kọja nitori ẹgbẹ awọn obi ati olukọ ile ẹkọ n kọ ferese ile ẹkọ naa lọwọ.
A ko ni pada si ile ẹkọ ti a ko ba ri idaniloju pe aabo wa fun ẹmi wa
Ẹwẹ ẹgbẹ awọn olukọ NUT ti ni olukọ ile Areago kankan ko ni pada si ile ẹkọ naa titi idaniloju pe aabo yoo wa fun ẹmi wọn.
Alaga NUT nijọba ibilẹ ariwa Ogbomoso, Tunde Oladapo lo kede ọrọ naa fun awọn akọroyin.
Oladapo ni gbogbo olukọ yoo peju si ileeṣẹ TESCOM lọjọ Aje, ọjọ kẹdọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2024.
“O ya mi lẹnu pe awọn olugbe agbegbe naa lu awọn olukọ lasiko ti a wa ni ileeṣẹ ọlọpaa lati gba beeli awọn eeyan to wa ni ahamọ.
“A ko le fi ẹmi awọn eeyan wa wewu."















