Aremu Afolayan bú sẹ́kún, tọ̀rọ̀ àforíjìn lọ́wọ́ Kunle Afolayan lẹ́yìn ìjà ogójì ọdún

Aworan Kunle Afolayan ati Aremu Afolayan

Oríṣun àwòrán, City Egbe

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja oṣere tiata, Aremu Afolayan ti tọrọ aforijin lọwọ ẹgbọn rẹ, Kunle Afolayan.

Gẹgẹ bii Aremu Afolayan se sọ o ti to ogoji ọdun ti ede ayede ti bẹ silẹ laarin ọmọ iya mejeeji naa, to si jẹ iku iya wọn so wọn papọ pada.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kejidinlogun oṣu kọkanla ni isin orin onigbagbọ fun iya naa waye niluu Komu nipinlẹ Oyo, ti fọnran to jade si ṣafihan bi ija naa se pari laarin ọmọ iya mejeeji naa.

Nigba to n sọrọ nibi eto isinku naa, Aremu Afolayan tọrọ aforijin lọwọ ẹgbọn fun bi wọn ko ṣe sọrọ fun bi ogoji ọdun ati fun gbogbo nnkan to waye lori ayelujara Instagram

“Ohun to nira lati se fun ogoji ọdun, mama mi fun mi ọjọ kan lati se atunse.

“Emi ati ẹgbọn mi a ki n sọrọ. Ẹgbọn mi ti kọle fun maami sugbọn wọn o le duro, Brọda Kunle, ẹ se.

“Ko si owo mi ninu ile yii o ṣugbọn ẹgbọn Kunle kọ fun gbogbo wa.

”Ẹ ma binu si gbogbo nnkan ti mo mu yin la kọja lori ayelujara

“Mo nifẹ rẹ gan an

Mi o ki i se ẹgbọn Aremu, baba rẹ ni mo jẹ- Kunle Afolayan

Nigba to n sọrọ, Kunle Afolayan ni oun ko ki n se ẹgbọn nikan fun aburọ rẹ Aremu ti oun si tun jẹ Baba fun pẹlu.

O ni oun ni oun tọ fun ọdun mẹwaa.

“Awọn obinrin lo kọ si lọkan, ti wọn ya wa”

Kunle Afolayan fun ra rẹ lo kede iku mama, Omoladun Afolayan loju opo Instagram rẹ .

Oriṣiiriṣii fọto ni gbajugbaja olootu ere naa fi kede iku mama rẹ to fi mọ aworan ti mama ya pẹlu awọn ọmọ ati ọmọ-ọmọ.

O ni lati gba pe iya naa ti lọ sugbọn igbesi aye rere ti iya naa gbe n tu awọn lọkan.

Ọpọ awọn oṣere tiata lo peju sibi eto isinku naa bii Jide Kosoko, Adebayo Salami, Lola Idije, Femi Adebayo, Anthar Laniyan, Lola Idije, Dele Odule ati awọn mii.