Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Simon Ekpa, olórí ikọ̀ IPOB kan tó dèrò àtìmọ́lé ní Finland

Simon Ekpa

Oríṣun àwòrán, Simon Ekpa/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Ọmọ bibi ijọba ibilẹ Ohaukwu nipinlẹ Ebonyi ni Simon Ekpa ti wọn si bi ni Ọjọ kọkanlelogun, ọsu kẹta odun 1985.

O jẹ ọmọ ọba Nwangbo ni Ngbo ati Lolo Nwangbo.

Orilẹede Finland ni Simon n gbe nibi to ti n saaju ipe fun ominira fun Biafra, to si sọ fun awọn ẹẹya igbo lorilẹede Naijiria lati kopa ninu eto idibo ti ijọba apapọ ba kuna lati tu Nnamdi Kanu silẹ.

Simon, lori opo ayelujara Twitter rẹ sapejuwa ara rẹ gẹgẹ bi ajafẹtọ ọmọniyan, oludasilẹ, agbẹjọrọ, oloṣelu, agbẹnusọ Biafria ati bẹbẹlọ.

O kede ọjọ marun un lati ọjọ kẹtalelogun titi di ọjọ kẹjidinlọgbọn gẹgẹ bi ọjọ konilegbele rẹ, to si ti da rukerudo silẹ ni apa guusu ila oorun naa.

Ibẹrẹ Simon Ekpa

Lẹyin to pari ile girama, o gbera lọ fasiti Aberystwyth nibi to ti gba imọ Master ninu ofin.

O tẹsiwaju lọ ABMS Education ni Switzerland nibi to gba oye PhD ofin okowo.

Nigba to wa ni ewe, Simon Ekpa jẹ elere idaraya fifo, to si ni okiki laarin awọn akẹgbẹ rẹ.

O figba kan soju orilẹede Naijiria nibi idije ilẹ Africa. Lọdun 2003 ni idije awọn ọjọwẹwẹ elere idaraya ni ilẹ Afrika, Simon gba ami ẹyẹ fadaka ni ere fifo.

Gbogbo nnkan lọ daada fun Simon, sugbọn o farapa, to si fi orukun ṣeṣe, eyi ti ko gba laaye layi tẹsiwaju ninu ere idaraya.

O gbera lọ si orilẹede Finland ni ọdun 2007 fun itọju ati iṣẹ abẹ fun orunkun rẹ.

Nibẹ ni Simon ni ri igbesi ayeye tuntun, bẹrẹ iṣẹ agbẹjọro, to si bẹrẹ mọlẹbi.

Lẹyin to pinnu to duro si ilu Lahti, Simon kọ ede Finland, ti wọn si tun fun ni iwe igbelyu, to si tun kopa ninu iṣẹ ologun.

O darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu NCP ni orilẹede Finland, to si kopa ninu eto iidbo lọdun 2022.

Lati ọdun 2012 ni Simon Ekpa ti n se oṣelu loorekore.

O da ileeṣẹ Ekpa &Co to n risi ileeṣẹ to n risi ofin irinajo.

Ko gbagbe ile

Simon Ekpa

Oríṣun àwòrán, @AbumNwaChineke

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Pẹlu bi o ṣe jẹ pe Simon Ekpa ko se gbe orilẹede Naijiria nọ , ko fi igba kankan gbagbe orisun rẹ ati awọn nnkan ti awọn eeyan ilu rẹ n la kọja.

O darapọ ,ọ awọn to n pe fun ominira ilẹ Biafra, to si gbe sori.

O kede ara rẹ gẹgẹ bi olootu ijọba fun Biafra, to si da BRIGIE silẹ to jẹ igbmọ awọn olori Biafra ti wọn gbe ni ilu.

BRGIE ni awọn minisita igba kaakiri agbaye.

O ni, “Awọn eeyan mi n la ọpọ inira kọja, akọkọ labẹ ijọba ologun, ikeji ni ijọba ton wa lode yii, eyi ti ako fọwọ si.

“Ija yii ti n lọ fun ọpọ ọdun, inu mi si dun si bo se jẹ pe awọn eeyan fun mi anfaani lati jẹ olori wọn.”

Ni ọdun 2023, Ileeṣẹ ọlọpaa Finland gba Simon Ekpa mu, ẹni to kede konilegbele ni ẹkun guusu ila oorun orilẹede Naijiria saaju eto idibo aarẹ lọjọ Satide ọdun to lọ ni ile rẹ lọjọbọ, Ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji, ọdun 2023.

Saaju ki ọwọ to tun tẹ Simon lọdun 2024, Ijọba Naijiria ni awọn ko ni fi ọwọ kekere mu Ekpa ti ijọba Finland ba kuna lati ṣe oun to yẹ lori dunkoko ọkunrin naa lati da eto idibo ru.

Agbẹnusọ ileeṣẹ iroyin Finland, Helsingin Sanomat sọ fun BBC pe akọroyin wọn lọ si ile Ekpa lati lọ ṣe ifọrọwọrọ sugbọn wọn ri bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe n gbinyanju lati mu Ekpa lọ si agọ wọn.

Akọroyin naa, Matilta Jokinen sọ fun BBC pe nigba ti oun bẹrẹ lọwọ awọn ọlọpaa pe kini Ekpa ṣe ti wọn fi gbe, o ni wọn ko da oun lohun.

Simon Ekpa kì í ṣe ọmọ ẹgbẹ́ IPOB, ẹ má kó wa papọ̀ – IPOB

Simon Ekpa

Oríṣun àwòrán, X/Simon Ekpa

Ẹgbẹ adijagbara ominira Biafra ti kede sita pe Simon Ekpa ti awọn ọlọpaa mu lorilẹede Finland ki i se ọmọ ẹgbẹ awọn, ti ko si si ajọṣepọ kankan laarin wọn.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ana ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 ni ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Finland kede pe awọn ti mu Simon Ekpa.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ IPOB, Emma Powerful fi lede fun awọn akọroyin, o ni ẹgbẹ IPOB ko faramọ bi awọn ileeṣẹ iroyin kan se n pe Simon Ekpa ni olori IPOB nitori ko ti ẹ fi igba kankan jẹ ọmọ ẹgbẹ naa.

IPOB ni “Simon ko ki ṣe ọmọ ẹgbẹ IPOB ti Mazi Nnamdi Kalu, ẹni to wa ni ahamọ DSS fun ọdun mẹrin jẹ olori fun.

Ki lo sẹlẹ saaju?

Ni ana ode yii ni ọlọpaa orilẹede Finland fi ṣikun ofin mu Simon Ekpa, ẹni to pe ara rẹ ni olori ẹgbẹ agbesunmọmi IPOB.

Iroyin lati orilẹede naa sọ pe ile ẹjọ kan lagbegbe Päijät-Häme ti paṣẹ pe ki wọn lọ fi afurasi naa si ọgba ẹwọn fun akoko diẹ nibi ti yo yi maa gba atẹgun.

Ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin ọhun ni pe o n ru awọn eeyan soke lati wu iwa ọdaran pẹlu erongba igbesunmọmi.

Ile ọjọ naa sọ pe Simon Ekpa n pin ọrọ igbesunmọmi ati iyapa lori ayelujara.

Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2021 ni ọkunrin naa wu iwa ọdaran ọhun.

Igba keji ree ti ọwọ agbofinro yoo tẹ Ekpa ni Finland.

Igba akọkọ ti wọn mu ni inu oṣu keji ọdun 2023 amọ wọn fi silẹ lẹyin wakati diẹ.

Ni bayii ti ọwọ ofin tun tẹ ẹ, a ko tii le sọ ibi ti ọrọ naa yoo yọri si.

Ekpa lo n ṣe iwuri fun awọn ọmọ ẹgbẹ IPOD lati maa da ilu ru, bẹẹ naa lo tun n ki wọn laya lati maa kọju ija si awọn agbofinro ni Naijiria.

Ohun ti oun atawọn alatilẹyin rẹ n ja fun ni iyapa ilẹ Igbo kuro lara orilẹede Naijiria ati itusilẹ Nnamdi Kanu ni ahamọ ijọba apapọ.

“Ko ki n ṣe ọmọ ẹgbẹ, bawo lo ṣe fẹ jẹ olori ẹgbẹ IPOB. IPOB ni igun lorilẹede Finland, ko si ninu awọn ẹgbẹ wa ni orilẹede naa tabi ni ibikibi.”

Powerful ni ọpọ awọn ẹgbẹ IPOB ni wọn ri Simon Ekpa gẹgẹ bii olugbala wọn to ni ero Biafra lọkan ṣugbọn wọn ti ri pe o jẹ eeyan ti wọn san owo fun lati ba ẹgbẹ naa jẹ.

“O gba awọn janduku lati da wahala si lẹ ni ilẹ Igbo ni ọdun 2021. Oun lo pe ara rẹ ni olootu ijọba Biafra, ti ẹgbẹ rẹ si n da wahala silẹ kaakire pẹlu orukọ IPOB.

“Gbogbo mọlẹbi IPOB lo kọ lati tele ilana ti Simon Ekpa gbe kalẹ lati gba ominira Biafra .

“Ẹgbẹ rẹ ati ileeṣẹ ologun Naijiria ni wọn wa ni di awọn iṣẹlẹ ijinigbe, ifipabalopọ, iku ati dida na sun awọn dukia araalu ni ilẹ Igbo.”

Powerful tẹsiwaju pe awọn pe akiyesi ileeṣẹ BBC ati awọn alaṣẹ Finland lati ma se pe Simon Ekpa ni olori IPOB nitori ko ki n se ọmọ ẹgbẹ rara.

Inú wa dùn bí wọ́n ṣe mú Simon Ekpa ní Finland, à ń retí rẹ̀ ní Naijiria – Iléeṣẹ́ olọgun Naijiria

Aworan Simon Ekpa ati olori ologun orileede Naijiria

Oríṣun àwòrán, @AbumNwaChineke/Nigeria Army

Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria ti kan sara si bi awọn agbofinro orilẹede Finland se mu olori ẹgbẹ ajijagbara IPOB, Simon Ekpa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ologun, Ọgagun Edward Buba ati Brigadier General Tukur Gusau ninu atẹjade ti wọn fi lede ṣapejuwe bi wọn se mu Simon Ekpa gẹgẹ bii aṣeyọri nla.

Bakan naa agbẹnusọ fun Ọga ologun CDS. General Christopher Musa ni oun dun pupọ lori aṣeyọri naa.

“Inu CDS dun pupọ pẹlu bi wọn se mu Simon Ekpa ni Finland, ti a n lero pe wọn yoo fi sọwọ si orilẹede Naijiria lati wa koju ofin.”

Buba tun jẹ ko di mimọ pe bi wọn se mu Simon Ekpa fihan pe awọn orilẹede agbaye n sisẹ papọ, ti wọn si fọwọsowọpọ pẹlu orilẹede Naijiria lati gbe ogun ti iwa ibajẹ.

“CDS ti n pe fun pe ki mu Simon Ekpa fun gbogbo nnkan to ti da silẹ lorilẹede Naijiria.

“Inu wa dun pupọ pẹlu bi wọn se mu, ti a si mọ loore pe awọn orilẹede agbaye n ba orilẹede Naijiria sisẹ papọ lati gbe ogun ti iwa ọdaran.”

Saaju ni orilẹede Naijiria ti kede sita pe awọn n wa Simon Ekpa ati eeyan mẹrindinlọgọrun mii fun ẹsun pe o n da wahala silẹ ni awọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria.

Simon Ekpa, olórí ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí IPOB dèrò àtìmọ́lé ní Finland

Ọlọpaa orilẹede Finland ti fi ṣikun ofin mu olori ẹgbẹ agbesunmọmi IPOB, Simon Ekpa.

Iroyin lati orilẹede naa sọ pe ile ẹjọ kan lagbegbe Päijät-Häme ti paṣẹ pe ki wọn lọ fi afurasi naa si ọgba ẹwọn fun akoko diẹ nibi ti yo yi maa gba atẹgun.

Ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin ọhun ni pe o n ru awọn eeyan soke lati wu iwa ọdaran pẹlu erongba igbesunmọmi.

Ile ọjọ naa sọ pe Simon Ekpa n pin ọrọ igbesunmọmi ati iyapa lori ayelujara.

Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2021 ni ọkunrin naa wu iwa ọdaran ọhun.

Igba keji ree ti ọwọ agbofinro yoo tẹ Ekpa ni Finland.

Igba akọkọ ti wọn mu ni inu oṣu keji ọdun 2023 amọ wọn fi silẹ lẹyin wakati diẹ.

Ni bayii ti ọwọ ofin tun tẹ ẹ, a ko tii le sọ ibi ti ọrọ naa yoo yọri si.

Ekpa lo n ṣe iwuri fun awọn ọmọ ẹgbẹ IPOD lati maa da ilu ru, bẹẹ naa lo tun n ki wọn laya lati maa kọju ija si awọn agbofinro ni Naijiria.

Ohun ti oun atawọn alatilẹyin rẹ n ja fun ni iyapa ilẹ Igbo kuro lara orilẹede Naijiria ati itusilẹ Nnamdi Kanu ni ahamọ ijọba apapọ.