Mo ní láti lúwẹ̀ẹ́ lọ gbé àwọn èèyàn kúrò nílé wọn lásìkò omíyalé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Kareemot Salami and Kelechi Anozia
- Role, BBC News
- Reporting from, Lagos
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Ni gbogbo igba ti ojo ba rọ ni Francis Okotieboh, ẹni aadọta ọdun ma n foya.
Fun ọpọ ọdun, olugbe Oke Ishagun, ibi ti omiyale ti wọpọ nipinlẹ Eko, ti ri ọpọ omiyale agbara ya sọbu.
O ṣalaye pe “Mo ni lati luwẹ lo gbe awọn eeyan kuro ni ile wọn lasiko omiyale, fi ẹmi ara mi lewu.”
Ohun to ṣẹlẹ yii buru gan to fi jẹ pe Okotieboh ti padanu ọpọ dukia rẹ.
O sọ pe “N ko ni dukia kankan mọ.”
“Ẹrọ amohunmaworan, gbogbo nkan, aga, ẹrọ amu nnkan tutu, gbogbo nkan ti lọ. N ko ni nkankan mọ.
"Lẹyin ibusun mi ati aṣọ lori ibusun mi. Ti mo ba ti ji ni aarọ, ma wẹ, ma dẹ jade lọ sibi iṣẹ mi. Bayii ni ọpọ awọn eeyan to n gbe ni Oke Ishaun ṣe n gbe igbesi aye wọn.”

Omiyale to n waye loorekoore
Nipinlẹ Eko lo n koju omiyale loorekoore.
Ojo to n rọ lọdun n fa ọpọ omiyale to si n fa ọpọ omi adagun ni ọpọ igba ni awọn agbegbe kan. Omiyale yii ti fa ọpọ ajalu si awọn dukia awọn eeyan ati igbesi aye wọn.
Ipinlẹ Eko jẹ ile fun eeyan milọnu mọkanlelogun, ti ọpọ ninu wọn si n gbe awọn agbegbe ti wọn ko ni idagbasoke aye ode oni. O jẹ ilu kan to sumọ omi, ti ọpọ odo si yika . Eyi tumọ si pe ọpọ ile lo wa lori omi nipinlẹ Eko.
Ni oṣu Kinni, ọọfisi ajọ isọkan agbaye gbe atẹjade kan sita lori oju ọjọ ati irinna awọn eeyan, atẹjde naa ṣalaye pe ti igbesẹ ko ba waye, o ṣeese ki ilẹ riri waye ni ọdun 2050.
“Ipinlẹ Eko ati agbegbe Niger Delta jẹ agbegbe kan ti odo, okun yika,” iwadii naa ṣalaye bẹẹ.
“Mo gbagbọ pe iṣoro yii lo jẹ ti ipinlẹ Eko nikan. Iṣoro omi wa ni Eko, ti wọn se itọju awọn idọti daada,” onimọ nipa idagbasoke ilu ṣalaye.
“Ayipada oju ọjọ n ṣokufa gboogi ninu rẹ. A n ri ayipada oju ọjọ, ti ojo nla si n rọ lemọlemọ, eyi to n fa omi niluu naa."
Ni Oke Ishagun, Francis Oktieboh ni omiyale n pọ si nitori awọn iṣẹ ti ko da ti awọn agbasẹ ṣe n ṣe to n dakun iṣoro omiyale.
“Ni ọdun to kọja, ọmọ mẹta lo ba omi lọ lasiko omiyale. Wọn padanu ẹmi wọn ki awọn eeyan to gbe sita ninu omi," Oktieboh lo ṣalaye.
Awọn ajọ Red Cross ni awọn ti gbe awọn igbesẹ oloore fun awọn eeyan to lugbadi iṣẹlẹ omiyale nipinlẹ Eko ati awọn ipinlẹ mii lorilẹede Naijiria.
Ige Oladimeji, oṣiṣẹ Red Cross nipinlẹ Eko sọ pe ni ọdun yii, ajọ naa ti pese iranlọwọ fun eeyan 200 lasiko omiyale lati koju iṣoro.
O sọ pe “Ni ọdun yii, ọpọ awọn ile ni lo ti dawo.
“A ti pese idanilẹkọ fun awọn agbegbe lo bi wọn se le tọju ara wọn, ti pese ohun ifọwọ ẹgbé run meji fun wọn pẹlu owo."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Siṣe amojuto oju ọna omi
Onimọ nipa idagbasoke ilu, Mustapha Ewenla sọ pe ọna ti ọpọlọpọ n lo nipa oju ọna omi ni ko bojumu, ti ilu si ni lati gbe ọpọ igbesẹ lati koju iṣoro omiyale.
O sọ pe “Ijọba nilo lati ṣe akitiyan nipa kikọ awọn awọn ọna oju omi agbara ati idilọwọ awọn eeyan lati kọ ile sori awọn ọna omi ati odo,”
Ṣugbọn ijọba sọ pe iṣoro naa ni wọn ti n mojuto tẹlẹ, pẹlu awọn ilọsiwaju atunṣe to n waye.
Kọmisona fun Ayika ati Awọn orisun omi ti ipinlẹ, Tokunbo Wahab sọ pe “Ipinlẹ Eko n koju awọn iṣoro pe o wa ni ayika odo nla, okun ati omi nla.
“Awọn eeyan ko bikita ti wọn si mu ofin sọwọ, ti wọn si pinnu lati di oju ọna omi eyi to n fa omiyale,” o sọ.
“Ṣugbọn ohun ti a ti ṣe ni laarin ọdun kan sẹyin ni lati rii daju ati tẹnumọ pe gbogbo ọna omi lo gbọdo mọ toni toni.”

Kọmiṣọnna fun ọrọ ayika ati idagbasoke ilu nipinlẹ Eko, Oluyinka Olumide, sọ pe ijọba ti bẹrẹ awọn iṣẹ akanṣe lati mu adinku ba ikun omi.
“Gbogbo awọn ọna omi ni a ti ni idanimọ kedere fun, ti a si n pinnu pe a ko ni buwọlu ile kikọ ni awọn agbegbe naa, ”Olumide lo sọ bẹẹ.
O sọ pe ọfiisi rẹ ṣe idaniloju pe ko si awọn ifọwọsi ikole ni awọn agbegbe ti omi wa
Olumide sọ pe: “Ti a ba le ṣe agbekalẹ ojutu igba pipe si awọn iṣoro yiii, a le yanju wọn diẹdiẹ.”
Ni adugbo rẹ ti Oke Ishagun, Francis Okotieboh nireti pe ijọba yoo ṣe ohun to tọi lati daabobo ohun-ini ati aabo awọn ẹmi awọn olugbr.
"O yẹ ki ojutu kan wa titilai si ọrọ ẹkun omi nipinlẹ Eko."
“Ijọba mọ ohun to tọ lati ṣe si odo odo, wọn kii ṣe alakobere.”























