Lẹ́yìn tí UK àti Canada ba ojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ jẹ́, wo orílẹ̀-èdè márùn-ún tí o le Japa sí nírọ̀rùn

Awọn arinrinajo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Bi ilẹ yii o gbe mi, ma a gboko ibomii l ni Yoruba ma n wi.

Gbolohun yii ṣaba ma n waye nigba ti igbeaye ba su ẹnikan nibi to n gbe yala nitori awọn iṣẹlẹ kan, tabi awọn iriri ti onithun n ri, eyi to le mu ko fi ilu, ipo tabi aaye to wa silẹ lọ si ibomiran.

Lasiko yii ti ọrọ aje ko fi bẹẹ dara to ni Naijiria, ti ọpọlọpọ eeyan si n ke irora ebi ati iṣẹ, ẹgbẹlẹgbẹ ọmọ orilẹ-ede naa lo ti n wa ibomiran ti wọn le lọ lati lọ wa ọjọ iwaju rere.

Fun bi ọdun mẹrin sẹyin ni aṣa Japa ti gba ile, gba oko, pẹlu bi awọn ọdọ ṣe n tu jade kuro ni Naijiria.

Amọ lẹnu ọjọ mẹta yii, ni awọn orilẹ-ede bii United Kingdom ati Canada, ti ọpọ ọmọ Naijiria n ya wọ, nitori eto ọrọ aje, ati bo ṣe rọrun to lati gba iwe igbeluu lẹyin eto ẹkọ, ti ṣe atunto awọn ofin wọn.

Awọn atunto yii si lo ti mu ki irinajo si awọn orilẹ-ede naa fun Japa, yọ kuro ni ọkan ọpọ eeyan, paapaa awọn to fẹ ṣe bẹẹ ni ilana eto ẹkọ fasiti.

Eto idibo to waye laipẹ yii naa ni orilẹ-ede America, eyi to gbe Donald Trump wọle, naa ti da omi tutu si ọkan ọpọ eeyan to fẹ ẹ japa, nitori pe Trump ni oun yoo gbogun ti iru irinajo bẹẹ.

Ibeere to wa jẹ ẹgbẹẹgbẹrun eeyan to fẹ japa ni pe, nibo ni wọn le dori kọ?

Nitori naa la ṣe ṣe akojọpọ orilẹ--ede marun un yii ti o le lọ.

Germany

Akọkọ lara awọn orilẹ-ede yii ni Germany. Orilẹ-ede Germany jẹ ara awọn to l’agbara julọ ni ilẹ Yuroopu, ti ibẹ si kun fun idagbasoke ati ọrọ aje to duro daadaa.

Awọn akẹkọọ lati orilẹ-ede kaakiri agbaye kii fi Germany ṣere rara. Idi ni pe lẹyin eto ẹkọ, oriṣiriṣi ọna lo le gba lati fi ni iwe igbeluu. Lẹyin ti o ba pari eto ẹkọ tan, o le gba fisa ti yoo fun ọ ni anfaani lati wa iṣẹ fun ọdun kan aabọ. Ti o ba wa a ri iṣẹ tan, o le fi iṣẹ naa beere fun iwe igbeluu lẹyin ọdun diẹ.

Iwadii tun sọ pe awọn to n ṣe iṣ bii dokita, nọọi, ati onimọ ẹrọ ni anfaani to pọ rẹpẹtẹ lati japa lọ si Germany.

Singapore

Lootọ ni Singapore le ọw mọ bi awọn eeyan ṣe n wọle si orilẹ-ede naa, ṣugbọn oriṣiriṣi ọna lo wa fun awọn akẹkọọ lati wle sibẹ. Kiakia ni wa a ri iwe igbelu gba gẹgẹ bi akẹkọọ ti ti gba iṣẹ ni Singapore. Awọn akọṣẹmọṣẹ, imọ ẹrọ ati awọn iṣẹ ọlọpọlọ pipe mi ni ọna yii wa fun. Fun awọn to n da iṣẹ ara wọn silẹ ati olokowo, to si ni owo lati fi ṣowo ni singapore, ilana Global Investor Program (GIP) lo dara.

Awọn akẹkọọ jade naa le lo ilana naa lati fi da iṣẹ ara wọn silẹ ni Singapore.

Awọn ileeṣẹ nlanla bii Facebook, Google, Zoom, Byte Dance, lo wa ni singapore, ti wọn si n gba ọpọlọpọ oṣiṣẹ.

Switzerland

Lara awọn orilẹ-ede ti ko ṣe e fi ọwọ rọ sẹyin nilẹ Yuroopu, ni Switzerland wa.

Igbeaye rrun pupọ nibẹ, amọ ofin nipa iwọle sibẹ nira pupọ. Awọn ilana wọn to lati mu irẹwẹsi ọkan ba ẹni to ba fẹ ẹ japa lọ sibẹ. Amọ ṣa, o tun ni ọna ti o le gba.

Ọna naa gẹgẹ bi iwadii ṣe sọ, ni ki o wọle si ile ẹkọ giga ni Switzerland. Owo eto ẹkọ ni Switzerland kere pupọ. Ọsẹ mẹjọ si mejila si ni o ma n gba lati ri iwe irinna gba.

Iwe igbelu fun oṣu mẹfa ni wọn o kọkọ fun ọ ti o ba pari ẹkọ rẹ tan, laarin asiko yii ni wa fi wa iṣẹ, eyi to le fi gba iwe igbeluu.

Australia

Iwe igbeluu lẹyin eto ẹkọ jẹ nnkan gboogi to mu ki awọn akẹkọọ o maa ya wọ Australia lati ilẹ okeere. Botilẹ jẹ pe orilẹ-ede Australia lo tutu ju ni agbaye, eyi ko da awọn ọmọ Naijiria bi tirẹ ati awọn mii duro lati ma Japa lọ sibẹ.

Australia ni ọrọ aje to dara, gbogbo igba si ni anfaani ma n ṣi silẹ fun iṣẹ nitori pe ero to wa nibẹ ko pọ to iye ti wọn nilo.

Pẹlu ilana iwe igbeluu lẹyin eto ẹkọ, eyi ti wọn n pe ni subclass 485, to fun awọn akẹkọọjade lati ṣiṣẹ, o le di ẹni to n gbe ni Australia. Ilana iwe igbeluu fun awọn oniṣẹ ọpọlọ, ti wọn n pe ni Skilled Independent Visa, tabi eyi ti awọn ijọba agbegbe ma n lo, irọrun ni fun ọ lati gba iwe igbeluu ni Australia.

Belgium

Ilẹ Yuroopu ni Belgium wa, ti wọn si n sọ ede Gẹgẹsi ati Faranse. Eero kii ṣaba ya si orilẹ-ede yii bii UK, America, Canada ati awọn mii. Nitori naa lo ṣe le gbiyanju rẹ wo ti o ba fẹ japa.

Amọ o, o gbọd ti ri iṣẹ ki wọn o to le fun ọ ni iwe igbeluu. O le ti kọwe wa isẹ lati Naijiria, ni kia ti iṣẹ ba ti bọ si, o ni anfaani lati kọwe beere fun iwe igbeluu lẹyin ọsẹ meji ti o ti n ṣiṣẹ.

Bakan naa ni o le sọ ibẹ di ibugbe pẹlu ẹbi rẹ.

IKILỌ̀: Ki o to bẹrẹ igbesẹ lati Japa kuro ni Naijiria lọ si orilẹ-ede kankan, ri i daju pe o ni oye to to, ki o si ṣe iwadii to jinlẹ nipa orilẹ-ede naa. O le ṣe eyi lori ayelujara awọn oril-ede, lati mọ ọna to yẹ ki o gba, ko maa ba bọ si ọwọ gbajuẹ.