Ojúṣe taa ni láti pàárọ̀ mítà tó gbó tàbí bàjẹ́ ní Naijiria?

Oṣiṣẹ amunawa

Oríṣun àwòrán, Twitter/@IkejaElectric

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Àjọ tó ń mójútó kárà-kátà iná mọ̀nàmọ́ná ní Nàìjiríà, Nigerian Electricity Regulatory Commission (NERC) ti kìlọ̀ fáwọn iléeṣẹ́ tó ń pín iná pé, ojúṣe wọn ni láti pààrọ̀ mítà fáwọn oníbàárà wọn tí èyí tí wọ́n ń lò bá ní ìyọnu.

Ìkìlọ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn iléeṣẹ́ tó ń pín iná mọ̀nàmọ́ná bíi Ikeja Electricity Distribution Company àti Eko Electricity Distribution Company, EKEDC sọ fún àwọn oníbàárà wọn kan pé kí wọ́n wá san owó láti fi pààrọ̀ àwọn mítà tó ti gbó.

Àtẹ̀jáde kan tí NERC fi sórí ìkànnì X wọn sọ pé bí àwọn iléeṣẹ́ DISCO ọ̀hún ṣe ní káwọn oníbàárà wá san owó láti gba mítà mìíràn lòdì sí àdéhùn tí wọ́n tọwọ́bọ̀.

NERC ní ìgbésẹ̀ àwọn iléeṣẹ́ náà lòdì sí abala NERC/246/2021 táwọn jọ fẹnukò lé lórí tí mítà àwọn oníbàárà bá bàjẹ́.

Àtẹ̀jáde náà fi kun pé òfin náà làá kalẹ̀ pé oníbàárà tó bá ti ní mítà kò gbọdọ̀ padà sí ṣíṣí owó fun lẹ́yìn tí oṣù bá parí.

“Tí mítà oníbàárà kan bá bàjẹ́ tàbí tí ọjọ́ bá ti lọ lórí rẹ̀, ojúṣe iléeṣẹ́ tó ń pín iná ni láti fún ní mítà mìíràn lọ́fẹ̀ẹ́, níwọ̀n ìgbà tó bá jẹ́ pé òun kọ́ ló bà á jẹ́.”

Àwòràn àwọn mítà lára ilé

Oríṣun àwòrán, Getty Images

NERC tẹnumọ́ ọ pé àwọn ní ìfarajìn láti máa dá ààbo bo àwọn oníbàárà àti pé kí àwọn iléeṣẹ́ tó ń pín iná máa tẹ ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn lójú mọ́lẹ̀.

Bákan náà ni wọ́n rọ àwọn èèyàn láti fi ẹjọ́ iléeṣẹ́ tó ń pín iná tó bá tàpá sófin yìí kí àwọn le gbé ìgbésẹ̀ tó bá yẹ.