Mọ̀ nípa bí o ṣe le dá ààbò bo ara a rẹ lọ́wọ́ àwọn àjálù tó le wáyé nínú balùwẹ̀

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọ eeyan lo ti padanu ẹmi wọn lasiko ti wọn n wẹ lọwọ, boya wọn yọ ṣubu tabi wọn fẹsẹkọ.

Yatọ si yiyọ ṣubu, ọpọ awọn kokoro ti a ko foju ri lo wa ninu baluwẹ ti wọn si le ṣe ijamba lara eeyan.

Ọjọgbọn John Oxford lati fasiti Queen Mary niluu London sọ fun BBC pe baluwẹ jẹ ibi kan tí ọpọ ijamba tí le waye ti eeyan ko ba ṣọra.

  • Ilẹ yiyọ

Dandan ni fun baluwẹ lati yọ lẹyin ti eeyan ba wẹ tan.

Laye atijọ, ọpọ baluwẹ lo ma wa ni ìta, ti wọn si n wẹ lori iyepẹ. Fun idi eyi, ilẹ yíyọ ko le waye sugbọn laye ti a wa yii, ọpọ baluwẹ lo wa ninu ile, to si jẹ pe amọ ti wọn fi wọ ile ma n yọ.

O se koko ki a farabale lasiko ti a ba n wẹ lọwọ ki a maa ba le yọ ṣubu.

  • Ọsẹ Abuwẹ :Ọsẹ yii ni o wa fun pe ko wẹ ara wa mọ sugbọn ti a ko se itọju awọn ọsẹ, o se ki awọn kokoro ti a ko le f’oju lasan ri wọ inu ọsẹ naa, ki wọn si fa ijamba.

Ọjọgbọn Oxford ni ti kokoro Bacteria le wa lara ọsẹ, ko si ma tan kaakiri eeyan kan si kan.

  • Ohun inu ara - Ti ba wẹ tan, aṣọ tí a n fi nu ara wa le akoba ti a ko ba se itọju rẹ daada.

Ọjọgbọn Oxford ni ko tọna kí eeyan meji ma lo ohun inura kana.

"Ohun ẹlẹgẹ ni ohun inu ara, tọna lati ma pin lọ rara.

"Ọpọ awọn kokoro yii le sọ mọ awọn towẹli yii, ti wọn yoo si wọ inu ara lia mọ."

  • Omi gbigbona :

Ni aye ode oni, ọpọ imọ lo ti gbode. Ninu baluwẹ igbalode, eeyan ni anfani si omi gbigbona ati tutu.

Ọpọ eeyan ni ko ni mọ pe oun ti mu omi gbigboba, ti wọn yoo si gbe orí sì abẹ ẹrọ to n da omi sara.

Eyi le ọpọ ijamba bi kí ara bo tabi ko jasi iku fun awọn miiran.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọna to fi le da bobo ara rẹ ninu baluwẹ

Iwadii fihan pe o ni awọn igbesẹ ti eeyan le gbe lati da bobo ara rẹ ninu baluwẹ.

Ma lo awọn eroja ilẹ wíwọ tí yoo fa ilẹ yíyọ.

Fifi ohun ti eeyan le dimu si ara ogiri. Tí eeyan ba ni anfani lati di nnkan mu lasiko to ba fẹ yọ, o ṣeese ko ma yọ ṣubu.

Ṣíṣe itọju ọṣẹ iwẹ naa le dẹkun awọn ijamba ninu baluwẹ paapaa lọwọ awọn kokoro ti a ko le f’oju lasan ri.

Aṣọ inu ara wa, a gbọdọ ṣe itọju rẹ, kí a si maa fọ loorekore.