Gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára láti dènà Monkeypox gbérasọ ní Nàìjíríà

Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ fífún àwọn èèyàn ní abẹ́rẹ́ àjẹsára láti fi dènà àìsàn Monkeypox.
Ní ìlú Abuja, olú ìlú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ètò náà pẹ̀lú fífún àwọn èèyàn tó ṣeéṣe kí wọ́n tètè lùgbàdì àìsàn náà, bí àwọn òṣìṣẹ́ ìlera àtàwọn tó ní nǹkan ṣe pẹ̀lú àwọn tó ní àìsàn ọ̀hún rí.
Àjọ tó ń rí ètò ìlera ní alábọ́dé ní Nàìjíríà ìyẹn National Primary Healthcare Development Agency (NPHCDA) tó ń rí sí ètò abẹ́rẹ́ àjẹsára náà ní àwọn ìpínlẹ̀ tó wà lẹ́kùn gúúsù Nàìjíríà ni ètò náà ti máa kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀.
Wọ́n ní àwọn ìpínlẹ̀ bíi Bayelsa, Rivers, Cross River, Akwa Ibom, Enugu àti Benue tí àkọ́ọ́lẹ̀ àìsàn náà ti gbilẹ̀ ni fífún àwọn èèyàn ní abẹ́rẹ́ àjẹsára náà yóò ti kọ́kọ́ gbérasọ.
Dókítà Hafsat Abdullazeez tó jẹ́ alákoso àjọ Institute of Virology, Abuja sọ pé abẹ́rẹ́ àjẹsára ọ̀hún tó wà ní Nàìjíríà kò tó nǹkan, èyí ló sì fà á táwọn fi fẹ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn tó nílò rẹ̀ jùlọ.
Ní ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹjọ, ọdún 2024 ni Nàìjíríà rí abẹ́rẹ́ àjẹsára Monkeypox ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá gbà láti orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.
Nàìjíríà ni orílẹ̀ èdè kẹta nílẹ̀ Áfíríkà, lẹ́yìn Rwanda àti Democratic Republic of Congo (DR Congo), tí yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní fún àwọn èèyàn ní abẹ́rẹ́ ajẹsára Monkeypox.
Àwọn òṣìṣẹ́ ìlera sọ̀rọ̀ lórí ìdí tí abẹ́rẹ́ àjẹsára náà ṣe pàtàkì
Alim Hammawa tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìlera tó gba abẹ́rẹ́ àjẹsára náà ní ilé ìwòsàn Federal Medical Centre, Abuja ṣàlàyé pé nítorí àwọn máa ń ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn tó pọ̀ ni òun ṣe gba abẹ́rẹ́ àjẹsára náà.
Ó gba àwọn èèyàn lámọ̀ràn pàápàá àwọn òṣìṣẹ́ ìlera láti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára náà lójúnà àti dá ààbò bo ara wọn lọ́wọ́ àìsàn náà.
Shola Abosede tí òun náà jẹ́ òṣìṣẹ́ ìlera nílé ìwòsàn kan náà ní inú òun dùn pé òun gba abẹ́rẹ́ àjẹsára yìí lẹ́yìn tí òun ti ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn tó ní àìsàn Monkeypox.
Abosede ní abẹ́rẹ́ àjẹsára tí òun gbà yóò dá ààbò bo òun pàápàá lásìkò yìí tí àìsàn náà ń jà káàkiri Nàìjíríà.
Láti ìgbà tí ọdún yìí ti bẹ̀rẹ̀, èèyàn 118 ni Nàìjíríà ti ní àkọ́ọ́lẹ̀ rẹ̀ pé wọ́n ní àìsàn ọ̀hún ní ìpínlẹ̀ méjìdínlọ́gbọ̀n àti Abuja.
Nàìjíríà wà lára àwọn orílẹ̀ èdè tí àjọ tó ń rí sí ìlera lágbàáyé, World Health Organization (WHO) fẹ́ fún ní abẹ́rẹ́ àjẹsára 899,000 láti fi kojú àjàkálẹ̀ àìsàn yìí.
Láti bíi ọdún mélòó kan sẹ́yìn ni àìsàn Monkeypox ti ń jà ní orílẹ̀ èdè DR Congo , tó sì ti ṣe ikú pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.
Èyí ló mú kí WHO kéde àìsàn náà bí èyí tó nílò àmójútó ní kíákíá lóṣù Kẹjọ.















