Èyí làwọn ohun tí o lè ṣe láti dènà ààrùn Mpox tó gbode kan báyìí

Aworan eeyan to ni aisan Mpox

Oríṣun àwòrán, Reuters

    • Author, David Wafula and Gem O'Reilly
    • Role, BBC News
    • Reporting from, Nairobi and London
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ileeṣẹ Afirika fun Iṣakoso Arun (CDC) ti kede ilu o faraọ lori aisan mpox lọjọ isẹgun, ọjọ kẹtala oṣu kẹjọ ọdun 2024.

Ikilọ lori aisan mpox, eyi ti wọn n pe ni Monkeypox tẹlẹ, bọ si ipele tuntun to ṣe pataki ninu gbigbe ogun ti ilẹ Afrika.

Igbimọ awọn amoye ṣe atilẹyin ipinnu naa.

Aisan naa ti n tan kaakiri orilẹede Democratic Republic of Congo, ti awọn amoye si n sọ pe aisan naa jẹ to lewu ju ti wọn ti rii.

Ajakale ni awọn apakan ti iwọ-oorun ati aringbungbun Afirika, lo ti n peleke si ni ilẹ Adulawọ fun ọpọ ọdun.

Ẹwẹ, ni ọdun aisan yii ti peleke si ni awọn orilẹede Afrika mẹrindinlogun

Ni ipari Oṣu Keje, CDC gbe iroyin sita pe apapọ awọn eeyan to ni aisan lo jẹ 37,583 lati ibẹrẹ ọdun 2022 ti eeyan 1,451 si ti jade laye lati awọn Orilẹ-ede mẹdogun Afirika

ACDC n kilọ pe o seese ki agbara ma ka aisan yii, ti wọn si ti bere fun ajesara diẹ sii.

“Eyi kii ṣe ni ọrọ Afirika nikan, mpox jẹ aisan to n dunkoko mọ agbaye, ewu ti ko mọ aala, ko mọ ẹya,,” Jean Kaseya, Ọga agba ACDC ṣalaye.

“O jẹ aisan wọ inu ago ara wa, wa ibi ti a ti kudiẹ si ninu ara , to si jẹ pe asiko yii lo yẹ ki a parapọ lati lo gbogbo iriri ti a fi koju aarun Korona fi koju rẹ.”

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Michael Marks, ọjọgbọn ti oogun lati fasiti ti Ile-iwosan ti Ilu London (LSHTM), sọ fun BBC pe “o ṣee ṣe ki itankalẹ aisan yii jasi ka da ọpọ nnkan duro lagbaye.

Ẹwẹ, o tẹnumọ pe o ṣe pataki pe ajọ agbaye bẹrẹ si ni pese iranlọwọ fun awọn orilẹ-ede bii DR Congo.

“Kii ṣe fun wa ni ile Europe lati dahun nikan nitori a ni kiyesi lori bi yoo se wọ awọn orilẹ-ede wa,” o sọ. “Ohun ti a ni lati gba jumọ bayii bi a se le pese alaafia fun awọn eeyan to n fi ara wọn lelẹ, ati bi wọn yoo se ni anfani si ajẹsara ati itọju to peye.

"Ti ikede ilu o faraọ lori ilera gbogbo eniyan ni irinsẹ ti yoo pese iranlọwọ fun DR Congo, iyẹn dara pupọ..”

Ọjọgbọn Marks ni otitọ ni pe aisan yii ti n tan kaakiri awọn orilẹede to wa ni tosi bii bii Rwanda, Uganda ati Burundi ati pe eewu si Europe ati Amẹrika si jẹ kekere.

O fikun: “Ọkan ninu awọn ba wa lẹru ni akoko yii ni pe a ko mọ ẹru nnkan yii ati iye awọn eeyan to n se ti a ko ti mọ, nitori naa a ko mọ otitọ nipa iye eeyan to ti lugbadi aisan yii.”

Ki ló ń jẹ́ Mpox?

Arun Mpox jẹ aisan to n waye nipasẹ kokoro-aarun monkeypox, ọmọ ẹgbẹ kana ni pẹlu igbona(small pox).

Ni akọkọ, ara ẹranko ni wọn ti ma n ko aarun yii si ara eeyan, to si n waye ni awọn orilẹede Adulawọp kan

Ni awọn agbegbe wọnyi, ẹgbẹẹgbẹrun awọn aisan yii lo ti waye, ti ọpọ eeyan si n padanu ẹmi wọn lọdọdun- paapa awọn ọmọde ti ọjọ ori wa labẹ ọdun mẹdogun, to si jẹ pe awọn ni wọn buru ju.

Aisan yii pin si ọna meji, Akọkọ lo fa aisan to kalẹ ni gbogbo agbaye ni ọdun 2022, to tan ka orilẹede to le ni ọgọrun un

Ikeji, eyi lo lagbara ju to n waye ni aringbungbun Afirika - clade 1b. Eyi lo wa lẹyineyi tuntun ti wọn sẹsẹ ṣawari laipẹ ni DR Congo , to n tan ka lọ si Kenya, Rwanda, ati Uganda.

Ki awọn apẹẹrẹ aarun yii?

Mpox tabi Monkeypoxni eeyan le ko lati ara eeyan mi to ba ni aisan naa. Awọn apẹẹrẹ to ma n mu dani ni iba, orififọ, ki ara m wu, ẹyin didun ati egun didun

Ni kete ti iba ba ti waye ni ara yoo bẹrẹ si ma su, bẹrẹ lati oju lọ si gbogbo ara, paapa atẹlẹwọ ati abẹ ẹsẹ.

Ara sisu, eyi ti o le ma ja ni lara jẹ tabi ko ma dun eeyan ni yoo ma lọ lati ipele kan si ipele mi ko to sarajọ, eyi to yoo pada bẹ.

Awọn akoran yii ni wọn amkuro fun ara wọn lẹyin ọjọ mẹrinla si mọkanlelogun.

Awọn iṣẹlẹ aisan ma n se ikọlu si gbogbo ara, paapa oju, ẹnu ati ibi nnkan ọmọ kunrin tabi obinrin.

Ajo Ilera Agbaye, WHO ti gba ni mọran pe ti eeyan ba ti ni aarun Mpox, o yẹ ki o ya ara sọtọ ni ile fun iye akoko ti akoran naa yoo fi lọ.

Ibora ati iwọ iboju tun le ṣe iranlọwọ lati yago fun itankale.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Aworan Dr Joe Phaahla

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bawo lo se le ko aisan Mpox ati ìsọ́rí àwọn èèyàn tó n ko aisan yii ju?

Ọna to fi le ko aisan yii ni fifi ara kan eeyan to ba ni aisan naa, eyi le waye lati ara ibalopọ tabi to ba to ba sunmọ eeyan, fun apẹẹrẹ, to ba sumọ ọmọ rẹ.

Ojogbon Marks sọ pe bo ti jẹ pe eeyan le ko aisan naa to ba farakinra pẹlu eeyan to ni arun naa amọ nini ibalopọ pẹlu ẹlomii n ko ipa nla lori ọrọ eyii.

Eyi ti fa itankale ni ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede Afirika ati pe o ti fa awọn abajade apaniyan fun awọn ọdọmọkunrin ni South Africa.

Ni Oṣu Kẹfa, eniyan meji ku iku Mpox ni South Africa, o kere ju wakati mẹrindinlogun lẹyin iku akọkọ ti orilẹ-ede latra aisan naa.

Eyi tẹle awọn eeyan mẹfa mii, ti wọn si dero ile iwosan

Gbogbo awọn eeyan ti wọn lugbadi aarun yii ni wọn jẹ ọkunrun ti wọn wa ni ẹni ọgbọn ọdun si ọdun mọkandinlogoji

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn abẹrẹ ajẹsara wo lo wa fun Mpox?

Ọjọgbọn Marks sọ pe iṣoro ti wọn n koju nipa aisan yii ni ipese ajesara, o ni iye ajẹsara to wa ni ilẹ ko to fun iye orilẹede to nilo abẹrẹ ajẹsara naa.

Dokita Adeola Fowotade, onimọ nipa aisan to n ti ara kokoro aifojuri jade, ti Ile-iwosan University College, Ibadan ni Nigeria sọ pe ọsẹ meji sẹyin, awọn orilẹede meji, Democratic Republic of Congo ati Nigeria ṣe afihan pe wọn ti ṣetan lati fun ni iwe-aṣẹ ajesara ti wọn nilo.

O sọ pe “Eyi jẹ igbesẹ iyin si iranlọwọ lati se adinku itankale aisan yii ni awọn orilẹ-ede Afirika ati pe

Mo nireti pe awọn orilẹ-ede yoo gba ipese naa,”

Ṣugbọn Dokita Fowotade tun kilọ nipa pataki pipese ajesara pẹlu ipolongo alaye to nilo.

“Alaye ti ko tọ n ṣe ṣiyemeji ajesara,”