Ilé alájà mẹ́rin dàwó, wọ́n ń gba inú ihò fáwọn tó há s’ábẹ́ lomí mu

Ikọ alaabo to n ri si bi awọn ti wọn ha si abẹ ile alaja mẹrin to dawo ni Tanzania yoo ṣe yè, ti ṣalaye pe awọn n gba ibi iho kan fi omi ranṣẹ si wọn labẹ ile naa.
Nnkan bii aago mẹfa aarọ ọjọ Satide, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla ọdun 2024 ni ile naa wo ni agbegbe nla nni, Dar es Salaam, Tanzania.
Awọn eeyan to wa ninu rẹ ha sibẹ, wọn ko le jade.
Ọjọ keji lẹyin iṣẹlẹ yii ni awọn alaabo já ọgbọ́n kan ti wọn fi n fun awọn to ha sabẹ ile lomi mu.
Wọn ni awọn n gba ibi iho kan fi afẹfẹ eemi ranṣẹ si wọn pẹlu, ati iyẹfun glucose to n ro ni lagbara.
Awọn iho to wa lara ile to wo naa ni wọn n gba fi awọn nnkan naa ranṣẹ si wọn bi wọn ṣe sọ.
Eeyan mẹtala (13) ni wọn ti ku ninu iṣẹlẹ yii, wọn si ti gbe eeyan mẹrinlelọgọrin (84) jade laaye.
Onka to wa nilẹ lasiko yii to si wa lati ọdọ Aarẹ Samia Suluhu Hassan niyẹn.
Wọn ko ti i mọ ohun to fa ile wiwo naa, ṣugbọn iwadii yoo bẹrẹ lorii rẹ.
Dar es Salaam jẹ ọkan lara awọn agbegbe to gbajumọ ni Tanzania.
Awọn eeyan pọ nibẹ, ṣugbọn a gbọ pe ijọba ki i fi dandan le e fun wọn lati tẹle ilana ile kikọ to peye.
‘A gbàgbọ́ pé a ṣì máa rí àwon èèyàn gbé jáde láàyè nínú ilé náà’
Kọmiṣanna to n ri si ọrọ agbegbe ni Tanzania, Albert Chalamila, sọ fun ẹka iroyin The Citizen, pe oun gbagbọ pe ọpọ eeyan ni wọn yoo ṣi ri gbe jade laaye lati inu ile naa.
O ni awọn ko ti i le sọ iye eeyan to ha sabẹ ile ọhun.
Bakan naa ni Kassim Majaliwa, Olootu ijọba Tanzania, sọ pe awọn ko ni i sinmi, afi ti awọn ba le fọwọ sọya pe awọn ti ko gbogbo ẹni to wa labẹ ile naa jade.
Eeyan meje ni wọn yọ lọjọ Aiku, ti i ṣẹ ọjọ keji ti ile ọhun wo.














