Kí ni èrè tí Naijiria lè jẹ lára àpérò 'G20 Summit' tí Tinubu lọ fún ní Brazil?

Oríṣun àwòrán, @Nigerian Presidency
Yoruba ni ori irin ni oore wa, yoo si ṣoro ki eeyan to o le sun siwaju bi ko ba kuro loju kan.
Fun idi eyi, Aarẹ Bola Tinubu ti balẹ si orilẹede Brazil bayii, nibi ti wọn n pe ni Rio de Janeiro, ti yoo ti ṣepade pẹlu awọn aarẹ lati orilẹede ogun (G20).
Aago mẹta kọja iṣeju mẹta oru ọjọ Aje, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla ọdun 2024 ni Aarẹ Tinubu balẹ si Brazil.
Eyi jẹ aago mọkanla alẹ kọja iṣẹju mẹta lọdọ tiwọn.
Breno Costa, aṣoju lẹka ọrọ ilẹ okeere fun Brazil lo gba Aarẹ Tinubu lalejo bo ti de.
Igba kọkandinlogun ti ipade naa yoo waye ree.
Nibi ipade G20 ọdun yii ti akori rẹ jẹ “Building a Just World and a Sustainable Planet,” ni wọn yoo ti jiroro lorii ọrọ aje, igbayegbadun awọn eeyan, ayika ati atunto iṣejọba kaakiri agbaye.
Ipade awọn olori orilẹede naa yoo tun da lori ayipada oju ọjọ kaakiri agbaye, lilo imọ ẹrọ fun idagbasoke ọrọ aje ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bakan naa ni wọn yoo sọrọ lori ogun Israel–Hamas, pẹlu ija agba to n waye laaarin America ati China.
Ọjọ meji ni ipade naa yoo fi waye, ọjọ kejidinlogun ati ikọkandinlogun oṣu Kọkanla ọdun 2024 yii ni.
Aarẹ Brazil, Luiz Inácio Lula da Silva; pin ohun ti wọn yoo jiroro le lori si ọna mẹta ti i ṣe: gbigbe ogun ti ebi, ìṣẹ́ ati òṣì ati ojuṣaaju.
Ìdí tí Ààrẹ Tinubu fi lọ sí ìpàdé náà
Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu, lọ si ipade G20 nitori Aarẹ Brazil; Da Silva to fiwe pe awọn aṣoju ajọ Iṣọkan Africa (African Union) ati ajọ European Union lati wa.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okeere ṣe ṣalaye, bi Tinubu ṣe fẹẹ kopa ninu ipade naa yoo ro Naijiria lagbara lati le dI ojulowo ọmọ ẹgbẹ G20.
Bakan naa ni yoo tun jẹ ki Naijiria le maa ba awọn ọmọ ẹgbẹ naa ṣe pẹlu.
Nibi ipade G20 yii, Aarẹ Tinubu yoo gba ẹnu Naijiria ṣalaye nipa bi a ṣe le gbogun ti ebi, ìṣẹ́ ati òṣì.
Ati bi wọn ṣe le ṣe atunto ọrọ aje kaakiri agbaye.
Gẹgẹ bi ẹka to n ri si ọrọ ilẹ okeere ṣe wi.
Kí ni G20?
G20 ni ẹgbẹ kan ti eeyan ogún wa ninu rẹ.
Wọn jẹ orilẹede ogún ti wọn maa n pade, ti wọn maa n jiroro lorii ọrọ aje agbaye.
Awọn ọmọ ẹgbẹ G20 ni: Argentina, Australia, Brazil, Canada, China, France, Germany, India, Indonesia, Italy, Japan, Mexico, Russia, Saudi Arabia.
Awọn yooku ni South Africa, South Korea, Turkey, UK ati US, African Union ati European Union.
Wọn maa N pe Spain naa wa bi alejo.
Lọdun yii, Aarẹ Bola Tinubu lọ si ipade naa pẹlu ipe ẹni pataki lati ọhun, iyẹn Aarẹ Luiz Inácio Lula da Silva,to ri gba lati wa.
Awọn orilẹede kan naa wa ti wọn kora wọn jọ ni kẹjẹbu lati ara G20 yii, ti wọn pe ara wọn ni G7.
Awọn kan lara G20 yii naa tun kora wọn jọ, wọn pe ara wọn ni Brics.
Awọn wọnyi ni- Brazil, Russia, India, China ati South Africa.














