Wo ìdí márùn-ún táwọn òṣìṣẹ́ fi máa ń parọ́ ọjọ́ orí wọn

Àwòrán àwọn òṣìṣẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ní ọjọ́ méjì sẹ́yìn ni ọ̀rọ̀ báwọn òṣìṣẹ́ ṣe máa ń dín ọjọ́ orí wọn kù ń jà ràìnràìn lórí ayélujára.

Èyí kò ṣẹ̀yìn bi àjọ tó ń rí sọ́rọ̀ ẹ̀ka ètò ìdájọ́ ní Nàìjíríà, Nigerian Judicial Council, NJC ṣe bí káwọn adájọ́ méjì kan lọ fẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ fẹ́sùn pé wọ́n parọ́ ọjọ́ orí wọn.

Àtẹ̀jáde kan tí àjọ NJC fi síta lọ́jọ́ Ẹtì ní àwọn ṣàwárí rẹ̀ pé adájọ́ àgbà ní ìpínlẹ̀ Imo, Adájọ́ Chukwuemeka Chikeka àti ààrẹ adájọ́ àgbà ní ilé ẹjọ́ Yobe State Islamic Courts, Babagana Mahdi ti ṣẹ̀ sófin.

Àjọ náà tún ṣèkìlọ̀ fáwọn adájọ́ kan, tí wọn kò sì tún sanwó oṣù fáwọn mìíràn fẹ́sùn wí pé wọ́n ṣe àwọn aṣẹmáṣe kan.

Píparọ́ ọjọ́ orí kìí ṣe ohun tuntun láàárín àwọn òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà èyí ló sì mú wa ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn nǹkan márun-ún tó máaa ń ìdí táwọn òṣìṣẹ́ ṣe máa ń parọ́ ọjọ́ orí wọn.

Àwọn ìdí márùn-ún náà nìyí:

Nasir Kabir tó jẹ́ ọ̀kan lára ọmọ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà ka àwọn nǹkan márùn-ún tó máa ń mú àwọn òṣìṣẹ́ parọ́ ọjọ́ orí wọn.

  • Owó oṣù àti owó ìfẹ̀yìntì tó kéré: Ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ máa ń parọ́ ọjọ́ orí wọn nítorí owó oṣù tí wọ́n ń gbà kéré débi tí wọn yóò lè máa fi pamọ́ dìgbà tí wọ́n fi máa fẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́. Bákan náà ni kò sí ètò tó múná dóko fáwọn tó ti fẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́. Ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ ni kìí rí àjẹmọ́nú wọn gbà bọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá fẹ̀yìntì.
  • Ìbẹ̀rù ìṣẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá kúrò lẹ́nu iṣẹ́: Látàrí owó oṣù tí kò tó nǹkan, àwọn òṣìṣẹ́ máa ń bẹ̀rù pé kí àwọn má tètè kúrò lẹ́nu iṣẹ́, kí ìṣẹ́ má ba à pọ̀ si fún wọn.
  • Ìnílò láti de ìpele kan lẹ́nu iṣẹ́: Ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ló máa ń dín ọjọ́ orí wọn kù ní pẹ̀lú èròǹgbà pé àwọn fẹ́ dé ìpele kan lẹ́nu iṣẹ́ kí wọ́n tó fẹ̀yìntì.
  • Láti le rí àwọn nǹkan tí iṣẹ́ ń bèèrè fún: Ní Nàìjíríà, ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ pàápàá àwọn tí kìí ṣe ti ìjọba ló máa ń fi gbèdéke ọjọ́ orí sí àwọn tí wọ́n bá fẹ́ gbà sẹ́nu iṣẹ́. Èyí wà lára nǹkan tó máa ń mú ọ̀pọ̀ èèyàn tó bá ń wá iṣẹ́ láti dín ọjọ́ orí wọn kù, láti ní gbèdéke iye ọjọ́ orí tí iṣẹ́ náà bá ń bèèrè fún.
  • Ojúṣàájú: Àwọn òṣìṣẹ́ kan máa ń dín ọjọ́ orí wọn kù láti le máa jẹ àwọn àǹfàní kan tó wà fún àwọn òṣìṣẹ́ tó wà lábẹ́ ọjọ́ orí bẹ́ẹ̀.

Kí ni òfin Nàìjíríà sọ nípa díndín ọjọ́ orí kù?

Amòfin Haruna Zakari tó jẹ́ agbẹjọ́rò ní Nàìjíríà ṣàlàyé pé fún BBC pé òfin tó de òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà korò ojú sí kí èèyàn parọ́ ọjọ́ orí rẹ̀ yálà nípa fífikun tàbí ṣíṣe àdínkù rẹ̀.

Haruna ní òṣìṣẹ́ tó bá parọ́ ọjọ́ orí rẹ̀ ti ṣẹ̀ sófin àti pé wọ́n le fi òfin gbé onítọ̀hún, tí wọn yóò sì fi ìyà tó tọ́ jẹ ẹ́.

Abala 477 ìwé òfin Criminal Code of Nigeria ní ẹ̀wọ̀n ọdún méje tàbí owó ìtanràn ni òṣìṣẹ́ tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ yóò san.