Àwọn èèwọ̀ tó rọ̀ mọ́ ìdìbò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ondo lọ́jọ́ Sátidé

Àkọlé fídíò, Kí ọlọ́mọ kìlọ̀ fún ọmọ rẹ̀ o, Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lórílẹ̀èdè Naijiria balẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Ondo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹẹdẹ Naijiria ti ṣalaye awọn ohun ti yoo ja si ẹṣẹ fun araalu lasiko eto idibo sipo gomina ti yoo waye ni ipinlẹ Ondo ni Ọjọ Abamẹta.

Lara awon iwa tabi ohun ti awọn agbofinro yoo mojuto gẹgẹ bi ẹṣẹ lasiko idibo naa ni ṣiṣe ipolongo fun oludije yoowu lasiko idibo tabi lọjọ idibo.

Oga ọlọpaa to n ṣe kokari eto abo fun eto idibo sipo gomina ni ipinleOndo, DIG Alexander Alabi to ṣalaye awọn iwa naa lẹkunrẹrẹ lasiko to fi n ba awọn akọriyin sọrọ nilu Akurẹ ni awọn agbofinro ti ṣetan lati rii pe idibo naa lọ ni irọwọ rọsẹ.

Aworan kọmisana ipinlẹ Ondo

Awọn iwa miran ti wọn yoo ka kun irufin lasiko idibo naa niwonyii:

Didunkoko mọ awọn oludibo lati dibo tabi lati maṣe dibo fun oludije kan lasiko idibo

Nini ohun ija kankan ni ikawọ lasiko idibo

Wiwọ aṣọ tabi iboju to le ko awọn oludibo laya jẹ.

Wiwọ awọn aṣọ tabi gbe ohun idanimọ to n ṣe afihan ẹgbẹ oṣelu tabi oludije to nkopa ninu eto idibo naa.

Gbigbe ọkọ to ni aworan idanimọ oludije tabi ẹgbẹ oṣelu.

Rinrin gberegbere lẹyin ti oludibo ba dibo ti idibo ṣi n lọ.

Lilo ọkọ to ni fere yafun un lasiko idibo naa

Pipe ipade, lilọ si ipade ti ko lẹtọ labẹ ofin lasiko idibo naa.

Lilo ẹrọ gbohungbohun tabi ẹrọ agbagbe kankan lasiko ti idibo ba n lọ lọwọ yatọ si eyi ti awọn oṣiṣẹ idibo fi n ṣe awọn ikede pataki gbogbo to yẹ.

O tun salaye siwaju sii pe, agbofinro marun- marun un ni yoo maa ṣọ ibudo idibo kọọkan lasiko idibo naa.

Wo bí ìgbáradì ṣe ń lọ fún ètò ìdìbò gómìnà Ondo tí yóò wáyé lọ́la ọjọ́ Àbámẹ́ta

Aworan awọn oṣiṣẹ INEC

Oríṣun àwòrán, INEC/X

Ajọ eleto idibo INEC ti bẹrẹ si ni pin ohun elo idibo kaakiri gbogbo ijọba ipinlẹ to wa nipinlẹ Ondo ṣaaju eto idibo gomina ti yoo waye lọla ọjọ Abamẹta nipinlẹ naa.

Ni ẹka ileeṣẹ ifowopamọ apapọ Naijiria, CBN, to wa lagbegbe Alagbaka niluu Akure ni ajọ INEC ti ko awọn nnkan elo idibo lọ kaakiri gbogbo ijọba ibilẹ nipinlẹ Ondo.

Ìjọba Ondo kéde òní gẹ́gẹ́ bíi ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ ní ìmúrasílẹ̀ ìbò Gómìnà

Awọn ohun elo idibo

Oríṣun àwòrán, INEC/X

Ẹwẹ, ijọba ìpínlẹ̀ Ondo ti kede òní, ọjọ karundinlogun, oṣù Kọkànlá, ọdún 2024, gẹgẹ bíi ọjọ ìsinmi lẹnu iṣẹ fún àwọn oṣiṣẹ ipinlẹ náà ṣaaju ìdìbò gomina ti yóò waye nibẹ.

Nínú atẹjade kan lati ọọfisi olórí oṣiṣẹ, O. F. Ayodele, sọ pé igbesẹ naa ko sẹyìn ki awọn oṣiṣẹ ọhun le rí aye rìnrìn àjò lọ ilu wọn láti dibo.

Ọla, ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹrindinlogun, oṣù Kọkànlá, ọdún 2024 ni eto ìdìbò náà yoo wáyé.

Káàkiri ìjọba ìbílẹ̀ mejidinlogun to wa ni ipinlẹ Ondo ni ìdìbò ọhun yoo ti wti wáyé.

Ẹgbẹ òṣèlú merindinlogun lo yẹ kí wọn kopa nínú ìdìbò náà ṣaaju asiko yii.

Ṣugbọn, nigba ti ìdìbò náà kù ọjọ meji pere ní ẹgbẹ oṣelu mẹta ju ọwọ silẹ fún Lucky Aiyedatiwa,to n dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC.