Iṣẹ́ tíátà ni kò jẹ́ kí n gbé ilé ọkọ àmọ́ n kò kábàmọ́ọ̀ - Amina Eleha

Àkọlé fídíò, Amina Elaha
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Agba oṣerebinrin, Adebukola Mosoba, ti ọpọ eeyan mọ si Amina Eleha ti ṣalaye wi pe lara idojukọ toun ba pade lẹnu iṣẹ tiata ni ko jẹ ki oun ri ile ọkọ gbe.

O ni loootọ ni oun ko ri ile ọkọ gbe ṣugbọn Eledua bun oun ni ọmọ.

Amina Eleha sọ fun BBC Yoruba pe ''ọkunrin maa sọ fun ọ wi pe o maa mu ikan ninu iṣẹ tiata ati oun.

Amọ, mi o kabamọọ igbesẹ mi ti mo gbe nitori ere tiata.

Idi ni pe awọn ọkunrin maa ṣeleri fun ọ wi pe awọn maa fẹ ọ ti o ba le fi iṣẹ tiata silẹ.

Ṣugbọn ika ni wọn fẹ ṣe fun ọ tori wọn si maa pada fi ẹ silẹ to ba ya.''

Amina Eleha tun sọ pe ẹni to pe oun ni ologo ana sun oun de ibi ire ni.

''Ẹni to sọrọ aida si mi wi pe ologo ana ni mi, fun igbeleke Ọlọrun ni ọrọ naa jasi.

Lati igba ti ẹni naa ti bu mi pe ologo atijọ ni mi ni Ọlọrun ti ṣi iwe iranti kan mi pada.

Lẹyin to sọrọ yẹn ni Kunle Afod wa mi wa sile tawọn akẹgbẹ mi si bẹrẹ si ni lo mi ninu ere.''

Gbajumọ oṣere naa tun ṣalaye idi ti awọn osẹre ti ko tii dagba ṣe n ku iku aitọjọ.

O ṣalaye wi pe ''ko si agba oṣere to maa sọ pe oun fẹ dawọ ere duro o, abaku laṣọ ewurọ ni ere siṣe.

Ṣe ẹ ri nnkan to maa n saba pa oṣere ti o ba dagba lọ titi ni ti wọn ko ba pe wọn siṣẹ mọ, tabi ti ko ba wa laarin ọpọ awọn ẹgbẹ rẹ lati maa rẹrin in maa ṣere.

Iru oṣere bẹẹ maa ronu, lati ibẹ lo ti maa ni ẹjẹ ruru eyi to le di aisan rọpa rọsẹ.''

Amina Eleha ko ṣai sọ iṣepataki iwe kika lẹnu iṣẹ tiata, o ni iwe mẹwaa toun ka si wulo foun gan an lẹnu ere siṣe.

O wa rọ awọn ọdọ to n ṣiṣẹ tiata wi pe ki wọn ni itẹriba fagba tori ko si bi ọmọde ṣe fẹ laṣẹ bi agba to, ko le lakiṣa bi agba.