Olùdíje sípò Ààrẹ Ghana yìí ti jáde láyé àmọ́ orúkọ rẹ̀ yóò sì wà nínú ìwé ìdìbò, ìdí rèé

Aworan oludije sipo aarẹ lorilẹede Ghana

Oríṣun àwòrán, DLFM/FACEBOOK

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọkan lara awọn to n dije du ipo Aarẹ ninu eto idibo Aarẹ ti yoo waye ni Ghana ti jẹ Ọlọrun nipe amọ orukọ rẹ yoo si farahan lara apoti ibo.

Oṣu to kọja ni oludije naa ninu ẹgbẹ oṣelu Ghana Freedom Party (GFP), Akua Donko, jade laye lẹyin aisan ranpẹ.

Lẹyin iku rẹ ni ajọ eleto idibo Ghana sọ fun ẹgbẹ oṣelu rẹ ki wọn fi ẹlomiran rọpo rẹ.

Ẹgbẹ GFP si fesi pe ẹni to n dije gẹgẹ bii igbakeji rẹ ni yoo rọpo oloogbe ọhun ninu eto idibo naa.

Amọ lẹyin ọjọ diẹ ti oludijẹ igbakeji naa, Philip Appiah Kubi ti ọpọ mọ si Roman Father, fi orukọ silẹ ni wọn sọ pe ko kun oju oṣuwọn.

Adari ajọ eleto dibo ilẹ naa sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin pe wọn yọ oludije ọhun latari pe awọn iwe ẹri to fi ṣọwọ si awọn ni awọn kudiẹ-kudiẹ kan ninu.

O ni “A sọ fun wọn ki wọn ṣe atunṣe si awọn iwe naa, a tun ri pe awọn kan lara awọn iwe ẹri rẹ ko ba ofin mu.”

O fin kun ẹgbẹ naa fi orukọ oludije silẹ lati ẹkun kan amọ ti kii ṣe ẹkun naa ni oludije naa ti wa.

Adari ajọ eleto idibo ọhun ṣalaye pe eredi ree ti awọn fi ja oludije to ṣoju eyii to jade laye kulẹ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, orukọ ẹni to jade laye gan ni yoo ṣi wa ninu iwe awọn gẹgẹ bii ẹni to n dije.

Idi ti ajọ eleto idibo ko fi yọ orukọ oludije to ti ku

Jean Mensa, to jẹ adari ajọ eleto idibo Ghana, EC, sọ pe “A ti tẹ ida 90% iwe ti a maa lo fun eto idibo naa.

“A ko ni paarọ orukọ ati aworan Akua Donkor ninu iwe eto idibo naa….”

Obinrin naa ṣalaye siwaju si pe awọn yoo ṣeto idanilẹkọọ fun araalu ṣaaju eto idibo naa ki wọn ma ba dibo fun oludije to ti jade laye.

O ni gbogbo ibo ti awọn eeyan ba di fun oludije naa lọjọ idibo lawọn yoo yọ kuro.

Wayi o, ofin orilẹede Ghana sọ pe ajọ EC gbọdọ fun ẹgbẹ oṣelu ni ọjọ mẹwaa lati pese oludibo mii ti oludije ẹgbẹ oṣelu kankan ba jade laye ṣaaju eto idibo.

Ọjọ keje, oṣu to n bọ ni eto idibo ọhun yoo waye.