‘Ọmọ kan ṣoṣo tí Ọlọ́run yọ̀ǹda fún mi làwọn ọlọ́pàá lù pa’

Àkọlé fídíò, ‘Ọmọ kan ṣoṣo tí Ọlọ́run yọ̀ǹda fún mi làwọn ọlọ́pàá lù pa’
‘Ọmọ kan ṣoṣo tí Ọlọ́run yọ̀ǹda fún mi làwọn ọlọ́pàá lù pa’

Lẹyin osu mẹta gbako ti awọn ọlọpaa mẹta kan ṣokunfa iku akẹkọọ ile-ẹkọ gbogbonise Kwara kan, Abdulqoyum Ishola, akẹkọọ mii tun ti ṣagbako irufẹ iṣẹlẹ ọhun.

Lọtẹ yii, Sulyman Ayeyemi ni orukọ akẹkọọ naa, ẹni ọdun mẹtadinlogun, to jẹ akẹkọọ ile-ẹkọ gbogbonise ipinlẹ Kwara ni Ilorin.

Iwadii BBC News Yoruba fihan pe, lọjọ Kẹfa oṣu Kẹsan-an ni iya oloogbe naa, Alhaja Fausat Ayeyemi ati awọn abanikẹdun yabo olu Ileeṣẹ ọlọpaa ni Ilorin ti wọn si n gbara yilẹ pẹlu omije loju.

Ẹkun ti arabinrin naa n sun ni wi pe awọn ọlọpaa pa ohun lọmọ, wọn o jẹ ki ohun jere ọmọ toun tọ, o ni wọn pa a lasiko to ti yege to si n gbaradi lati lọ sin orilẹ-ede baba rẹ gẹgẹ bi agunbanirọ.

Bi obinrin naa se n kebosi, lo n bọ aṣọ kuro lọrun ara rẹ, ṣugbọn awọn abanikẹdun n sare da aṣọ bo o pada.

Alhaja Fausat Ayeyẹmi, Mama Sulyman ti wọn ni awọn ọlọpaa kan lu pa.

BBC pada wa Alhaja Fausat Ayeyẹmi lọ si ile lati beere hulẹhulẹ ohun gan to ṣẹlẹ. Alhaja Fausat ko alaye kalẹ lori iku ọmọ rẹ.

O ni oun ko fẹ ẹbẹ tabi ẹbun owo kankan lori ọrọ yii ju pe ki awọn agbofinro ṣe afihan awọn ọlọpaa to lu ọmọ rẹ pa, ki wọn si jẹ ki idajọ ododo fi ẹsẹ mulẹ lori rẹ.

Lootọ lawọn ọlọpaa lo ipa lati fi mu Sulyman ki o to di pe o ku – Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Kwara

DSPAdetoun, alukoror ileeṣẹ ọlọpàá ni ipinlẹ Kwara.

Nigba to n fesi lori ọrọ naa, alukoror fun ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara, DSP Adetoun Ejirẹ Adeyẹmi ṣalaye pe ọrọ owo kan to to ẹgbẹrun lọna irinwo Naira lo da oloogbe Sulymain ati eeyan kan pọ ti onitọun si lọ fi ẹjọ rẹ sun ni agọ ọlọpaa.

Kikọ ti wọn ni oloogbe naa kọ lati yọju si agọ ọlọpaa lo mu ki awọn ọlọpaa waa lọ lati mu u wa si agọ naa

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara ṣalaye pe, “oloogbe naa kọ lati tẹle awọn ọlọpaa lo mu ki wọn lo ipa pẹlu rẹ. Ori fifi ipa mu u yii ni wọn wa to fi daku. Nigba ti yoo si fi de ile iwosan, dokita sọ pe oku ni wọn gbe e de.”