Àwọn afurasí ọlọ́pàá lu akẹ́kọ̀ọ́ pa ní Kwara, òbí gbarata

Ìyá Sulyman lásìkò tó sunkún lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lẹyin osu mẹta gbako ti awọn ọlọpaa mẹta kan ṣokunfa iku akẹkọọ ile-ẹkọ gbogbonise Kwara kan, Abdulqoyum Ishola, akẹkọọ mii tun ti ṣagbako irufẹ iṣẹlẹ ọhun.

Lọtẹ yii, Sulyman Ayeyemi ni orukọ akẹkọọ naa, ẹni ọdun mẹtadinlogun, to jẹ akẹkọọ ile-ẹkọ gbogbonise ipinlẹ Kwara ni Ilorin.

Iwadii BBC News Yoruba fihan pe, lọjọ Kẹfa oṣu Kẹsan-an ni iya oloogbe naa, Alhaja Fausat Ayeyemi ati awọn abanikẹdun yabo olu Ileeṣẹ ọlọpaa ni Ilorin ti wọn si n gbara yilẹ pẹlu omije loju.

Ẹkun ti arabinrin naa n sun ni wi pe awọn ọlọpaa pa ohun lọmọ, wọn o jẹ ki ohun jere ọmọ toun tọ, o ni wọn pa a lasiko to ti yege to si n gbaradi lati lọ sin orilẹ-ede baba rẹ gẹgẹ bi agunbanirọ.

Bi obinrin naa se n kebosi, lo n bọ aṣọ kuro lọrun ara rẹ, ṣugbọn awọn abanikẹdun n sare da aṣọ bo o pada.

Ìyá Sulyman lásìkò tó sunkún lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá

Ki ni ohun to ṣẹlẹ?

AWORAN OBI OLOOGBE

BBC News Yoruba lanfani lati ba agbẹjọro arabinrin naa ti oun naa wa nibẹ ni gbolohun, o si ṣalaye bi ọrọ naa ṣe waye.

Agbẹjọro Bakare ṣalaye pe, Sulyman jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ọmọ bibi ilu Ajasẹ-Ipo ni ipinlẹ Kwara.

O ni ọmọ naa jẹ akẹkọọ ile ẹkọ gbogbonise Kwara, pe o si ti yege, o si n gbaradi láti sin orilẹ-ede baba rẹ ni osu Kiini ọdun 2025.

Agbẹjọro naa ni ọrọ owo lo pa Sulyman ati ọrẹ rẹ pọ, o sọ pe agbegbe Tankẹ ni wọn jọ n gbe ṣugbọn ọrẹ rẹ mẹjọ lọ si Ileesẹ ọlọpaa ni agbegbe Ganmo pe Sulyman jẹ ohun lowo nitori pe o mọ ọlọpaa nibẹ.

O ni "awọn ọlọpaa Ganmo naa, gbera wa si Tankẹ pẹlu kẹkẹ Marwa, wọn si mu oloogbe naa labẹ afara nibẹ.

"O sẹlẹ wi pe ariyanjiyan sẹlẹ laarin wọn nítorí pe o n beere bi wọn ṣe jẹ, ṣugbọn awọn tọrọ naa soju wọn sọ pe, wọn bẹrẹ si n lu u bi ejo aijẹ, titi ko fi le rin mọ, lẹyin naa ni wọn wọ ọ sinu kẹkẹ Marwa.

"Ohun ti a gbọ lẹyin eyi ni pe, o ti ku, nigba ti o daku mọ wọn lọwọ ni wọn gbe lọ sile iwosan gbogbo ni ilu Ilorin nibi ti wọn ti fìdí ẹ mulẹ pe o ti ku.

O ni gbogbo ẹri ni awọn ni lọwọ to fi mọ fọnran bi wọn ṣe lu u. O fi kun-un pe ohun ti o sẹlẹ jẹ ipaniyan ti awọn o si fẹ ki wọn fi ọwọ bo o mọlẹ.

Ohun tí ọlọ́pàá sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Ni alẹ ọjọ Kẹjọ, osu Kẹsan-an ni agbẹnusọ ọlọpaa fun ipinlẹ Kwara, DSP Ejirẹ Adetoun Adeyemi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade to buwọlu to si fi lede.

O ni Ileesẹ ọlọpaa Kwara gbọ nipa iṣẹlẹ to jasi iku arakunrin Suleiman Olayinka, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn.

Adetoun sọ pe ẹsun irẹnijẹ ati yiyẹ adehun ni wọn fi kan-an oloogbe naa.

O ni lọgan si ni wọn ran awọn ọlọpaa jade fun iwadii lori ẹsun naa.

O ṣalaye pe gbogbo ọlọpaa ti ọrọ naa kan ni wọn ti wa lati mọle bayii fun iwadii to peye lori iku arakunrin naa.

Agbẹnusọ naa sọ pe bi iwadii ṣe n lọ naa ni Ileesẹ ọlọpaa yoo maa fi to araalu leti.