Wo àwọn aláboyún tó lè j'ànfààní iṣẹ́-abẹ ọ̀fẹ́ tí ìjọba àpapọ̀ kéde fáwọn tí kò rọ́wọ́ họrí

Oloyun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ijọba to n ri si eto ilera ni Naijiria ti kede iṣẹ abẹ ọfẹ ni awọn alaboyun to nilo iṣẹ abẹ lati bimọ ṣugbọn ti ko lowo lati ṣe e.

Eto yii ni ijọba pe orukọ rẹ ni MAMII eyi to tumọ si didena iku alaboyun lasiko ibimọ.

Minisita fun eto ilera lorilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Muhammed Ali Pate, ṣalaye pe anfaani naa wa fun awọn oloyun ti iṣẹ n ṣẹ, ti wọn si koju oṣunwọn lati jẹ anfaani iṣẹ abẹ ọfẹ.

O fi kun un pe eto naa wa fun ileewosan aladaani ati t'ijọba to ba ti forukọ silẹ labẹ eto Ma-da-n-dofo ijọba apapọ.

Nigba to n ṣalaye kikun lori eto yii, Tashikalmah Hallah, to jẹ alakooso agba fun minisita eto ilera, sọ fun BBC pe eto naa wa fun awọn alaboyun to fẹẹ bimọ ti wọn ko si le da a bi.

O ni awọn to foju han pe iṣẹ-abẹ ni ọrọ wọn gba lẹsẹkẹsẹ ti wọn ko si lowo lati fi ṣe e nikan lo wa fun, kii ṣe gbogbo oloyun.

Hallah fidi ẹ mulẹ pe awọn ọsibitu aladaani ni yoo maa tọka awọn eeyan to nilo anfaani yii, ti wọn ko si lagbara rẹ.

Obinrin 1,047 ninu 100,000 lo n ku lasiko ibimọ ni Naijiria- WHO

Oloyun ati ẹni to n yẹ ẹ wo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ eleto Ilera Agbaye, WHO, ṣe sọ, obinrin 1,047, iyẹn ẹgbẹrun kan ati mẹtadinlaadọta lo n ku ninu ẹgbẹrun lọna ọgọrun lasiko ibimọ ni Naijiria.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ajọ WHO ni akọsilẹ yii jẹ nnkan to buru jai fun orilẹede Naijiria.

Akọsilẹ naa fidi rẹ mulẹ pe Naijiria lo wa ni ipo kẹrin ninu awọn orilẹede ti alaboyun ti maa n ku julọ lasiko ibimọ lagbaaye.

Awọn dokita si sọ pe ai ki n ṣe iṣẹ abẹ fun wọn lo n fa iku naa.

Fun ọpọ obinrin to loyun, paapaa awọn ti wọn wa ni igberiko, owo ti ko si ki i jẹ ki wọn le ṣiṣẹ abẹ lasiko ti wọn ba nilo rẹ.

Ọjọgbọn Pate sọ pe pẹlu anfaani tijọba gbe kalẹ yii, iku to ṣee dena ko ni i waye fun alaboyun ni Naijiria mọ.

Ọrọ aje ti dẹnukọlẹ ni ilopo mẹta lasiko yii ni Naijiria, eyi to jẹ ki atijẹun gan-an di iṣoro fun ọpọ eeyan, lai ti sọ ti awọn oloyun.

Mabel Onwuemena, alakooṣo ajọ kan ti ki i ṣe ti ijọba, sọ pe inu oun dun si igbesẹ ijọba yii pupọ.

O ni bi obinrin ba bimọ tan ti ẹjẹ ko da, tabi to ti pẹ ju lori irọbi ati awọn iṣoro mi-in lo maa n fa iku.

O wa rọ ijọba lati ma jẹ ki anfaani yii pin si ori iṣẹ abẹ nikan.

Onwuemena ni ki ijọba pese oogun ati ayẹwo oyun ọfẹ pẹlu, lati doola ọpọ ẹmi ti ko ba tun ṣofo nitori oyun.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post